Somkele Iyamah
Somkele Iyamah Idhalama jẹ́ òṣèré àti mọ́dẹ́lì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1] Ó gbajúmọ̀ fún ipá tí ó kó nínú àwọn eré bíi 93 Days, The Wedding Party, The Arbitration, àti Gidi Up.[2]
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Somkele sí ìlú Ika ní ìpínlẹ̀ Delta[3]. Àwọn òbí rẹ̀ ni Andrew àti Onyi Iyamah tí wọn sì jẹ́ ọmọ ìlú Ika (Agbor). Òun ni ọmọ kẹta nínú àwọn ọmọ mẹ́rin tí àwọn òbí rẹ bí. Olùkọ́ rẹ̀, Mrs Abe ní o kókó kọ bí wọ́n ń ṣé jó àti bí wọ́n ṣé ń ṣe eré.[4] Ó gboyè jáde láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí McMaster University nínú ìmò Biochemistry.
Iṣẹ́
àtúnṣeÓ kópa nínú eré 93 Days gẹ́gẹ́ bí dókítà kan tí ó kó àrùn Ẹ̀bólà. Ipa tí ó kó nínú eré yìí ló fà tí ó fi gba àmì ẹ̀yẹ òṣèré to dára jù lọ láti ọ̀dọ̀ ELOY Award. Ó jẹ́ àmbásẹ́dọ̀ fún ilé iṣẹ́ Multichoice Nigeria. Òun ní o ṣe aṣojú fún ilé iṣẹ́ Andrea Iyamah tí àbúrò rẹ̀ gbé kalẹ̀. Ó jẹ́ ìyàwó fún Aaron Idhalama[5]
Àṣàyàn àwọn eré tí ó tí ṣe
àtúnṣeỌdún | Àkọ́lé | Ipa tí ó kó |
---|---|---|
2020 | A Soldier's Story: Return From The Dead | Zaya |
2018 | Lara and the Beat | Dara Giwa |
2017 | The Wedding Party 2 | Yemisi Disu |
2016 | The Wedding Party | Yemisi Disu |
2016 | 93 Days | Dr. Ada Igonoh |
2016 | The Arbitration | Omawumi Horsefall |
2015 | The Department | Ireti |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "I pursued my acting career while maintaining a day job - Somkele Iyama-Idhalama". March 24, 2017.
- ↑ Husseini, Shaibu (10 September 2016). "Somkele Iyamah-Idhalama: New Nollywood rising star goes to Toronto". guardian.ng. Archived from the original on 2020-01-20. Retrieved 2020-10-02. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "somkelei". somkelei. Retrieved 2017-03-04.
- ↑ "I’m a private person — Somkele Iyamah-Idhalama" (in en-US). Punch Newspapers. http://punchng.com/im-a-private-person-somkele-iyamah-idhalama/.
- ↑ "Aaron Idhalama". Cognovi Ventures (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-10-06. Retrieved 2020-10-05.