Sophie Rammal Alákijà (bíi ni ọjọ́ keje oṣù kejì ọdún 1994) jẹ́ òṣèré ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó gbajúmọ̀ fún ipa tí ó kó nínú eré Halita àti Assistant Madam

Sophie Alakija
Ọjọ́ìbíSophie Rammal
7 Oṣù Kejì 1985 (1985-02-07) (ọmọ ọdún 39)
Lagos, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Nollywood Actress
Ìgbà iṣẹ́2010–present
Olólùfẹ́Wale Alakija (2010–2019)
Àwọn ọmọ2
Àwọn olùbátanJay Rammal (brother)

Ìgbésí ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Alákijà ní ọjọ́ keje oṣù kejì ọdún 1994 sí ìdílé Mùsùlùmí.[1] Ó jẹ́ olólùfẹ́ fún gbajúmọ̀ olórin, Wizkid láti ọdún 2010 di ọdún 2016.[2] Ní ọdún 2016, ó fẹ́ Wale Alákijà tí ó jẹ́ ọmọ fún obìnrin tí ó lọ́wọ́ jù ní ilé Áfríkà: Folorunsho Alákijà.[3] Wọ́n ṣe ìgbéyàwó wọn ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta ọdún 2016 ní ìlú Surulere ní ìpínlẹ̀ Èkó. Ó sì bí ọmọ méjì.[4]

Iṣẹ́

àtúnṣe

Ní ìgbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ó kópa gẹ́gẹ́ bí oníjó nínú eré orin Holla At Your Boy èyí tí Wizkidgbé jáde. Ó tí kópa nínú orísìírísìí eré bíi Drawing Strands, Getting over him, àti Small Chops.[5] Ní ọdún, 2017, ó kópa nínú eré Scandals[6]. Ní ọdún 2019, ó kópa nínú eré tẹlẹfíṣọ̀nù tí àkòrí rẹ jẹ Halita.[7]

Àwọn Ìtọ́kàsi

àtúnṣe