Soumaya Akaaboune
Soumaya Akaaboune (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ 16 Oṣù kejì, Ọdún 1974) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Mòrókò.
Soumaya Akaaboune | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 16 Oṣù Kejì 1974 Tangier |
Orílẹ̀-èdè | Moroccan |
Iṣẹ́ | Actress, comedian |
Ìgbà iṣẹ́ | 1987-present |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeAkaaboune lẹni tí wọ́n bí tó sì dàgbà ní ìlúTangier, orílẹ̀-èdè Mòrókò. Ìyá rẹ̀ jẹ́ aṣàpẹẹrẹ ẹ̀ṣọ́ aṣọ. Ní ìgbá tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá, òṣe~ré ijó kan tí wọ́n pè ní Maurice Bejart ṣe àkíyẹ̀sí wípé Akaaboune ní ẹ̀bùn ijó tó sì pèé láti wá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ oníjó rẹ̀. Ó gbà láti darapọ̀, ó sì bẹ̀rè sí ní kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ Maurice Bejart.[1] Akaaboune káàkiri gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù láti ṣeré ijó ní àwọn ìlú bíi Párìs, Spéìn àti Lọ́ndọ̀nù. Ní àkókò tí ó wà ní ìlú Lọ́ndọ̀nù, ó kọjúmọ́ eré orí-ìtàgé ṣíṣe tó sì kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré olórin.[2] Òpin dé bá iṣẹ́ ijó jíjó rẹ̀ nígbà tí ó ní ìfarapa níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 1989.[3] Ní ìlú Lọ́ndọ̀nù, Akaaboune pàdé Sandra Bernhard, ẹnití ó pèé láti kópa nínu ètò ìfihàn rẹ̀ tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Up All Night" àti lẹ́hìnwá nínu ètò "I am Still Here Damn It".[4]
Akaaboune kọ́ ẹ̀kọ́ eré ṣíṣe ní ilé-ìṣeré Loft Studio. Ní ọdún 2010, ó kópa pẹ̀lú Matt Damon nínu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Green Zone.[4] Akaaboune ní àwọn ipa nínu eré aláwàdà afìfẹ́hàn kan ti ọdún 2012 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Playing for Keeps àti eré Lovelace ní ọdún 2013.[5] Ó tún wà nínu ètò ìfihàn ti ọdún 2013 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les Vraies Housewives.[6] Láàrin ọdún 2015 sí 2016, Akaaboune kópa gẹ́gẹ́ bi Fettouma nínu eré tẹlifíṣọ̀nù kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Wadii, tí olùdarí rẹ̀ n ṣe Yassine Ferhanne. Ipa rẹ̀ dá lóri ọmọbìnrin kan tí ó kọ ìwà ìbàjẹ́ àti àìṣedéédé tọkàntọkàn. Ní ọdún 2019, ó kó ipa Marcelle nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Spy.[7]
Akaaboune pàdé Peter Rodger ní ọdún 1999. Àwọn méjéèjì fẹ́rawọn tí wọ́n sì bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Jazz. Peter Rodger ti bí ọmọ kan ríí tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Elliot Rodger, ẹni tí ó ṣe ẹ̀mí àwọn ènìyàn lófò ní ọdún 2014.[5] Elliot Rodger ti gbàá lérò rìí láti ṣekú pa Akaaboune náà.[8] Akaaboune padà sí orílẹ̀-èdè Mòrókò ní ìgbẹ̀yìn ọdún 2014. [9] Akaaboune maá n sọ èdè Faransé, Lárúbáwá, Gẹ̀ẹ́sì àti Spánìṣì.[4]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣe- Àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀
- 1987 : Dernier été à Tanger
- 1999 : Esther
- 2010 : When the Voices Fade (short film) : Leila
- 2010 : Green Zone : Sanaa
- 2012 : Playing for Keeps : Aracelli
- 2013 : Lovelace
- 2013 : Djinn
- 2017 : Catch the Wind : Madame Saïni
- 2017 : Looking for Oum Kulthum
- Àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù rẹ̀
- 2013 : Les Vraies Housewives
- 2015-2016 : Waadi : Fettouma
- 2017-2018 : Rdat L'walida : Faty Kenani
- 2019 : EZZAIMA
- 2019 : The Spy : Marcelle
- 2020 : Bab Al Bahar : Zineb
Àwọn ìtọ́kasì
àtúnṣe- ↑ "Soumaya Akaaboune". Visage du Maroc (in French). Archived from the original on 24 January 2018. Retrieved 14 November 2020.
- ↑ "Un thé avec Soumaya Akaaboune" (in French). Les Eco. 8 July 2016. Archived from the original on 17 November 2020. https://web.archive.org/web/20201117235606/https://leseco.ma/un-the-avec-soumaya-akaaboune/. Retrieved 14 November 2020.
- ↑ "Soumaya Akaaboune Actress" (PDF). Harcourt Paris. Retrieved 14 November 2020.
- ↑ 4.0 4.1 4.2 "Un thé avec Soumaya Akaaboune" (in French). Les Eco. 8 July 2016. Archived from the original on 17 November 2020. https://web.archive.org/web/20201117235606/https://leseco.ma/un-the-avec-soumaya-akaaboune/. Retrieved 14 November 2020.
- ↑ 5.0 5.1 "Alleged gunman Elliot Rodger, 22, lived a life of privilege". https://www.smh.com.au/world/alleged-gunman-elliot-rodger-22-lived-a-life-of-privilege-20140525-zrndx.html. Retrieved 14 November 2020.
- ↑ "Claude's Corner: Meet The Ladies Of Les Vraies Housewives!". iReal Housewives. Retrieved 14 November 2020.
- ↑ "The Spy on Netflix ending explained: What happened at the end?". https://www.express.co.uk/showbiz/tv-radio/1175166/The-Spy-ending-explained-Netflix-Eli-Cohen-Sacha-Baron-Cohen-series. Retrieved 14 November 2020.
- ↑ Allen, Nick (27 May 2014). "'Virgin killer’ Elliot Rodger planned to murder his family". https://www.telegraph.co.uk/news/worldnews/northamerica/usa/10858971/Virgin-killer-Elliot-Rodger-planned-to-murder-his-family.html. Retrieved 14 November 2020.
- ↑ Guisser, Salima (9 August 2015). "Soumaya Akaaboune : Un prochain personnage dans un autre style". https://aujourdhui.ma/culture/soumaya-akaaboune-un-prochain-personnage-dans-un-autre-style-120028. Retrieved 14 November 2020.