Stefania Turkewich

Atorinjọ àti Onímọ́-orin ọmọ Yukréìn

Stefania Turkewich-Lukianovych (tí a bí ní ọjọ́ karún-úndínlọ́gbọ̀n, oṣụ̀ kẹrin, ọdún 1898 tí ó sì di olóògbé ní ọjọ́ kejọ, oṣù kẹrin, ọdún 1977) jẹ́ atorinjọ, atẹdùru, àti onímọ̀-orin ọmọ orílè-èdè Ukraine, tí wọ́n dámọ̀ gẹ́gẹ́ bíi obìnrin atorinjọ àkọ́kọ́ ní Ukraine.[1] Àwọn SovietUkraine gbẹ́sẹ̀lé iṣẹ́ rè.

Stefania Turkewich-Lukianovych
Ọjọ́ìbíStefania Turkewich
April 25, 1898
Lviv, Yukréìn
AláìsíApril 8, 1977
Cambridge, Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì
Ẹ̀kọ́University of Lviv, Lviv Conservatory, Berlin Conservatory
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́1920's–1970's

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

A bí Stefania sí ìlú Lviv, ní orílẹ̀-èdè Austria-Hungary. Bàba-bàbá rẹ̀ (Lev Turkevich), àti bábà rẹ̀ (Ivan Turkevich) jẹ́ àlùfáà. Ìyá rẹ̀ Kormoshiv (Кормошів) máa ń tẹ dùrù, ó sì kàwé pẹ̀lú Karol Mikuli àti Vilém Kurz, ó sì tẹ dùrù pọ̀ pẹ̀lú Solomiya Krushelnytska.[2] Gbogbo wọn nínú ebí rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí orin, wọ́n sì ní ohun èlò orin kan tí wọ́n ń lù. Stefania máa ń tẹ pianó, dùrù, àti hàmóníọ̀mù.

Ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe
 
Middle Row (left to right): sister Irena, brother Lev (with racket), Stefania, circa 1915

Stefania bẹ̀rẹ̀ sí ní kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin kíkọ pẹ̀lú Vasyl Barvinsky. Láti ọdún 1914 wọ ọdún 1916, ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Vienna pẹ̀lú Vilém Kurz. Lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní, ó kékọ̀ọ́ pèlú Adolf Chybiński ní University of Lviv, ó sì darapọ̀ mọ́ èkọ́ rè ní Lviv Conservatory.[2]

Ní ọdún 1919 ó kọ orin àkọ́kọ́ rẹ̀,– the Liturgy (Літургію), èyí tí ó ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní St. George's Cathedral ní ìlú Lviv.[3]

Ní ọdún 1921, ó kékọ̀ọ́ pẹ̀lú Guido Adler ní University of Vienna àti Joseph Marx ní University of Music and Performing Arts Vienna, tí ó sì kékọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 1923.[3]

Ní ọdún 1925 ó fẹ́ Robert Lisovskyi, ó sì rin ìrìn àjò pèlú rẹ̀ lọ sí Berlin, wọ́n jọ gbé pọ̀ láti ọdún 1927 wọ 1930, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ pèlú Arnold Schoenberg àti Franz Schreker.[2] Lásìkò yìí, ní ọdún 1927 ni ó bí ọmọbìnrin rẹ̀, tí ń ṣe Zoya (Зоя) was born.[4]

Ní ọdún 1930, ó lọ sí ìlú PragueCzechoslovakia, láti lọ kékọ̀ọ́ pèlú Zdeněk Nejedlý ní Charles University, àti Otakar Šín ní Prague Conservatory. Ó tún kọ́ bí wọ́n ṣe ń kọ orin sílẹ̀ pẹ̀lú Vítězslav Novák ní ilé-ìwé orin náà. Ní ọdún 1933, ó kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe ń tẹ dùrù Ó gboyè gíga nínú ẹ̀kọ́ orin ní ọdún 1934 ní Ukrainian Free University, ó sì di obìnrin àkọ́kọ́ tó ti ìlú Galicia wá tó gboyè gíga ọ̀hún.[2]

Ó padà sí ìlú Lviv, láti ọdún 1934 títí wọ ìbẹ̀rẹ̀ ogun àgbáyé kejì. Ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ orin ní Lviv Conservatory, ó sì di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbé Union of Ukrainian Professional Musicians.[3]

Àwọn àtòjọ orin rẹ̀

àtúnṣe

Iṣẹ́ Síḿfónì rẹ̀

àtúnṣe
  • Symphony No.. 1, 1937
  • Symphony No.. 2a, 1952
  • Nọmba Symphony 2b, ẹya keji
  • Sinfonietta, ọdun 1956
  • Meta Symphonic Sketches, Oṣu Keje 3, Ọdun 1975
  • Oriki Symphonic "La Vita"
  • Symphony Space, 1972
  • Suite fun meji okun orchestras
  • Irokuro fun Double Okun Orchestra

Ijó bàléè

àtúnṣe
  • Ọmọbirin naa pẹlu Awọn Ọwọ Rẹ, Bristol, 1957
  • Egba Ọgba
  • Vesna (orisun omi; Ballet ọmọ), 1934-1935
  • Mavka (Igbo Nymph; Ballet Awọn ọmọde), 1964-1967, Belfast
  • Strachopud (The Scarecrow), 1976

Ijó ọ́púrà

àtúnṣe
  • Mavka - da lori Orin igbo Lesia Ukrainka (ko pe)

Ijó Ijó ọ́púrà

àtúnṣe
  • Tsar Okh tabi Ọkàn Oksana, 1960
  • Bìlísì Ọ̀dọ́
  • A Ewebe Idite, 1969

Awọn iṣẹ Kórà

àtúnṣe
  • Liturgy, ọdun 1919
  • Orin Dafidi fun Scheptitsky
  • Ṣaaju Ogun
  • Triptych
  • Lullaby (Ah, ko si ologbo), 1946

Iyẹwu - Awọn irinṣẹ́

àtúnṣe
  • Sonata fun violin ati piano, 1935
  • Quartet okun, 1960 - 1970
  • Mẹta fun violin, viola ati cello, 1960 - 1970
  • Piano Quintet, 1960 - 1970
  • Afẹfẹ Mẹta, ọdun 1972

Àwọn isẹ́ dùrù

àtúnṣe
  • Awọn iyatọ lori akori Ti Ukarain, 1932
  • Irokuro. Piano Suite pẹlu Awọn akori Ti Ukarain, 1940
  • Impromptu, ọdun 1962
  • Grotesque, ọdun 1964
  • Mountain Suite, 1966-1968
  • Ayika ti Awọn nkan fun Awọn ọmọde, 1936–1946
  • Ukrainian Keresimesi carols ati Shtjedrivka
  • Irohin ti o dara
  • Keresimesi pẹlu Harlequin, 1971

Oriṣiriṣi

àtúnṣe
  • Okan, fun ohun ati onilu
  • Lorelei, itan ti harmonium ati piano, 1919. Ọrọ nipasẹ Lesia Ukrainka
  • Oṣu Karun ọdun 1912
  • Awọn akori ti awọn orin eniyan
  • Ominira Square, fun duru
  • Orin Lemky fun ohun ati awọn gbolohun ọrọ

Ita ìjápọ

àtúnṣe

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ukrainian Art Song Project – Stefania Turkewich". Archived from the original on 2016-03-22. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 Павлишин, Степанія Стефанівна. Перша українська композиторка: Стефанія Туркевич-Лісовська-Лукіянович, БаК, Lviv 2004.
  3. 3.0 3.1 3.2 Роман Кравець. "Українці в Сполученому Королівстві". Інтернет-енциклопедія. Archived from the original on 2017-04-27. Retrieved 2018-08-28. 
  4. "Зоя Робертівна Лісовська-Нижанківська, the Encyclopedia of Modern Ukraine" (in ukrainian). Retrieved 2018-12-17.