Stephanie Busari (tí a bí ní ọdún 1977) jẹ́ akọ̀ròyìn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tí ó gbajúmọ̀ fún gbígbá “proof of life” ní ìyasọ́tọ̀ [1][2] fún àwọn ọmọbìnrin ilé-ìwé Chibok tí ó pàdánù ní àtẹ̀lé agbawi Bring Back Our Girls èyí tí ó yọrí sí ìdúnadúrà pẹ̀lú Boko Haram pé yọrísí ìtúsílẹ̀ tí ó ju ọgọ́run àwọn ọmọbìnrin ilé-ìwé tí a jí gbé. [3]

Stephanie Busari
Ọjọ́ìbíStephanie Kemi Busari
12 Oṣù Kẹjọ 1977 (1977-08-12) (ọmọ ọdún 46)
Lagos, Nigeria
Ẹ̀kọ́Leeds Trinity University
Iṣẹ́Journalist

Ẹ̀kọ́ àtúnṣe

Busari kọ́ ẹ̀kọ́ Faransé àti "Media" gbogbogbò ní Trinity and All Saints College ní Leeds àti lẹ́hìn náà lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Rennes fún Ètò ìwé-ẹ̀kọ́ gíga, Diploma. [4]

Iṣẹ́ Rẹ̀ àtúnṣe

 
Busari interviews US Secretary of State Antony Blinken in 2021

Busari bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní "New Nation" tí ó ti parẹ́ báyìí, ìwé ìròyìn tí ó dá lórí Ìlú Lọ́ńdọ́nù, àti lẹ́hìn náà ó kó lọ sí Daily Mirror. Arábìnrin náà ní àkókò kúkurú bí oníròyìn onítumọ̀ ní BBC News ṣáájú kí ó tó lọ sí CNN ní ọdún 2008 àti tún gbé lọ sí Èkó, Nàìjíríà ní ọdún 2016 láti ṣe ìtọsọ́nà ilé-iṣẹ́ oní nọ́mbà àkọ́kọ́ ti CNN àti ọ̀pọ̀lọpọ̀-ẹ̀rọ. [5][6][7] Ní ọdún 2015, Busari jẹ́ àpákan ti ẹgbẹ́ tí ó gba Ààmì Ẹ̀yẹ Peabody fún ìròyìn CNN ti àwọn ọmọbìnrin ilé-ìwé Nàìjíríà tí ó pàdánù àti ní ọdún 2017, ó gba Ààmì Ẹ̀yẹ Hollywood Gracie àti Outstanding Woman ní Media Awards fún ìròyìn jinlẹ̀ ti àwọn ọmọbìnrin ilé-ìwé Nàìjíríà tí ó pàdánù. [8][9] Ọ̀rọ̀ Busari ọdún 2017 tí à ń pè ní TED talk ní Gèésì lórí “Báwo ni àwọn ìròyìn irọ́ ṣe ìpalárá gidi” ni a ti wò ju àwọn àkókò mílíọ̀nù kan lọ àti pé a túmọ̀ ìwé-kíkọ rẹ̀ sí àwọn èdè mẹ́ta-dín-ogójì jùlọ. [10]

Àwọn Ìtọ́ka Sí àtúnṣe

  1. Proof of life for some kidnapped Chibok schoolgirls (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), retrieved 2019-11-29 
  2. Knoops, CNN EXCLUSIVE REPORTING by Stephanie Busari, Nima Elbagir and Sebastiaan (13 April 2016). "Nigeria's missing girls: 'Proof of life?'". CNN. Retrieved 2019-11-29. 
  3. Stephanie Busari; Kelly McCleary (6 May 2017). "82 Chibok schoolgirls released in Nigeria". CNN. Retrieved 2019-11-29. 
  4. "Stephanie Busari". LinkedIn. Retrieved November 29, 2019. 
  5. "Stephanie Busari". AWiM19 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-05-27. Archived from the original on 2019-06-03. Retrieved 2019-11-29. 
  6. "I want to change negative reports about Africa – Stephanie BuSari". The Sun Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-07-29. Retrieved 2019-11-29. 
  7. "CNN Goes Multi-platform in Nigeria". WarnerMedia (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-11-29. 
  8. "Stephanie Busari: What Happens When Real News Is Dismissed As Fake?". NPR.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-11-29. 
  9. "Stephanie Busari". UNESCO (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-04-24. Retrieved 2019-11-29. 
  10. Busari, Stephanie (24 April 2017). "How fake news does real harm" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). TED. Retrieved 2019-12-14 – via YouTube.