Stephanie Okereke Linus

Stephanie Linus (Stephanie Onyekachi Okereke;[1] 2 Oṣù Kẹẹ̀wá 1982)[2][3] jẹ́ òṣèré, olùdarí eré àti afẹwàṣiṣẹ́. Ó ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àmì-ẹ̀yẹ àti àwọn yíyàn fún iṣẹ́ rẹ̀ bí òṣèré, tó fi mọ́ àmì-ẹ̀yẹ ti Reel ti ọdún 2003 fún òṣèré tí ó dára jùlọ, àmì-ẹ̀yẹ Afro Hollywood ti ọdún 2006 fún òṣèré tí ó dára jùlọ, àti àwọn yíyàn mẹ́ta míràn fún òṣèré tí ó dára jùlọ ní ipa asíwájú níbi ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards ní ọdún 2005, 2009 ati 2010.[4][5][6][7]Ó tún jẹ́ olùdíje níbi ìdíje ẹwà ti Nàìjíríà ní ọdún 2002.[8] Ní ọdún 2011, ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà da lọ́lá pẹ̀lú fífun ní oyè Memeber of the Order of the Federal Republic (MFR).[9]

Stephanie Okereke Linus
Ọjọ́ìbíStephanie Onyekachi Okereke
2 Oṣù Kẹ̀wá 1982 (1982-10-02) (ọmọ ọdún 41)
Ngor Okpala, Imo, Naijiria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Calabar,
New York Film Academy
Iṣẹ́Oṣere, Oludari, Afẹwaṣiṣẹ
Olólùfẹ́Linus Idahosa (m. 2012)
Àwọn ọmọMaxwell Enosata Linus (b. 2015)
Websitestephaniedaily.com

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀ àtúnṣe

Stephanie Okereke ni a bí ní Ngor Okpala, ní Ìpínlẹ̀ Ímò . Òun ni ọmọ ẹ̀kẹfà ti ọmọ mẹ́jọ àwọn òbí rẹ̀. Ó parí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ní Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà. Ó kẹ́ẹ̀kọ́ gíga ní Yunifásitì ìlú Calabar, ní Ìpínlẹ̀ Cross River, níbi tí ó ti gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ èdè gẹ̀ẹ́sì.[10]

Iṣẹ́ ìṣe àtúnṣe

Ní àkókò ìgbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́ ní ọdún 1997, ó hàn nínu àwọn fíìmù Nollywood méjì kan; Compromise 2 àti Waterloo.[11] Níbi ìdíje ẹwà Nàìjíríà ti ọdún 2002 tí ó ti kópa, Okereke ṣe ipò kejì.[12] Ní ọdún 2003, Okereke gba àwọn àmì-ẹ̀yẹ méjì, nínu mẹ́jọ tí wọ́n yàán fún, níbi ayẹyẹ Reel Awards ti ọdún 2003 fún òṣèré tí ó dára jùlọ. Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́ láti Ilé-ẹ̀kọ́ gíga New York Film Academy ní ọdún 2007, Okereke ṣe àgbéjáde fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Through the Glass[13][14] èyítì ó ṣe pé òun ni ó ṣètò kíkọ àti dídarí eré náà, tí ó sì tún kópa nínu rẹ̀.[15][16] Fíìmù náà rí yíyàn Africa Movie Academy fún àmì-ẹ̀yẹ ní ọdún 2009.[17] Ní ọdún 2014, ó ṣe àgbéjáde fíìmù míràn tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Dry. Òun yìí kan náà lótún ṣètò kíkọ àti dídarí, bẹ́ẹ̀ ló sì tún kópa nínu eré náà, èyí tí ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àmì-ẹ̀yẹ tó fi mọ́ ti Africa Movie Awards ẹlẹ́kejìlá àti ti Africa Magic Viewers Choice Awards ti ọdún 2016 fún fíìmù tí ó dára jùlọ pẹ̀lú ẹ̀bùn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun kan. Okereke ti kópa nínu fíìmù tó lé ní àádọ́rùn-ún.[18]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Stephanie Okereke's full name". Archived from the original on 28 March 2009. Retrieved 6 October 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Stephanie Okereke clocks 30 and it’s going to be…". http://www.vanguardngr.com/2012/10/stephanie-okereke-clocks-30-and-its-going-to-be/. 
  3. "My Wedding Plans in Top Gear, Says Stephanie Okereke". P.M. News (Lagos, Nigeria). 1 February 2011. http://pmnewsnigeria.com/2011/02/01/my-wedding-plans-in-top-gear-says-stephanie-okereke/. Retrieved 3 October 2012. 
  4. "And the 2010 AMAA nominees are". Jemati.com. Archived from the original on 6 April 2010. Retrieved 14 April 2010. 
  5. "The African Movie Academy Awards (AMAA) 2010 Nominations". thefuturenigeria.com. Archived from the original on 17 July 2011. Retrieved 14 April 2010.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "Stephanie Okereke: Awards & Nominations". Retrieved 2009-10-06. 
  7. "AMAA 2009: List of Nominees and Winners". Africa Movie Academy Awards. Archived from the original on 5 April 2011. Retrieved 17 October 2010.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  8. "Official bio". Archived from the original on 6 September 2009. Retrieved 6 October 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. "Official bio". Archived from the original on 6 September 2009. Retrieved 6 October 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  10. "Okereke at NigeriaMovies.com". Archived from the original on 2008-12-28. Retrieved 2009-10-06. 
  11. "Stephanie Okereke: Nigerian screen queen". Archived from the original on 26 March 2009. Retrieved 6 October 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  12. "Official bio". Archived from the original on 6 September 2009. Retrieved 6 October 2009. 
  13. "Through the Glass: Review". Retrieved 2009-10-06. 
  14. "Through the Glass: Official Site". Archived from the original on 14 April 2009. Retrieved 6 October 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  15. "Official bio". Archived from the original on 6 September 2009. Retrieved 6 October 2009.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  16. "New York Film Academy Film School: Film School Student Stephanie Okereke in The News". Archived from the original on 2014-07-16. Retrieved 2009-10-06. 
  17. "AMAA 2009: List of Nominees and Winners". Africa Movie Academy Awards. Archived from the original on 5 April 2011. Retrieved 17 October 2010.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  18. "Filmography". Retrieved 2009-10-06.