Stephen Oluwole Awokoya (1913–1985) jẹ́ mínísìtà ẹ̀kọ́ ti Western Region of Nigeria nígbà kan rí. Ó wà lára àwọn olùṣètò pọ́lísì tó rí sí ètó ẹ̀kọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1950 síwájú.[1] Ó gba oríyìn fún ìdásílẹ̀ universal primary education ní apá Ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà.

Stephen Oluwole Awokoya
Ọjọ́ìbíJuly 1913
Oyo
Aláìsí1985
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Ẹ̀kọ́University of London
Iléẹ̀kọ́ gígaYaba College
Iṣẹ́Teacher

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Awokoya kẹ́kọ̀ọ́ ní Yaba College of Higher Education, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn tó kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé-ẹ̀kọ́ ọ̀hún. Lẹ́yìn tí ó parí ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Yaba, ó yan iṣẹ́ olùkọ́ni láàyò. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ní St Andrews College, Oyo àti ní Abeokuta Grammar School. Lẹ́yìn ogun agbáyé kejì, ó di ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ Molusi College, ní Ijebu Igbo. Lẹ́yìn èyí Awokoya kúrò ní western Assembly, ó sì di ọ̀gá́ ilé-ẹ̀kọ́ Tai Solarin, nígbà tí wọ́n yàn án láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùdarí ilé-ẹ̀kọ́ náà.[2] Láàárín àsìkò náà, ó lọ sí Great Britain, níbi tí ó ti gboyè ẹ̀kọ́ BSc University of London. Nígbà tí ó wà ní London, ó di gbajúmọ̀ láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Milton Krieger, 'Education and Development in Western Nigeria: The Legacy of S. O. Awokoya, 1952-1955', The International Journal of African Historical Studies > Vol. 20, No. 4 (1987)
  2. A. Ade. Adeyinka, Local Community Efforts in the Development of Secondary Grammar School Education in the Western State of Nigeria, 1925-1955, The Journal of Negro Education. Vol. 45, No. 3 (Summer, 1976)