Streptococcal pharyngitis

Ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni èyítí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà (Strep throat) jẹ́ àìsàn tí àwọn kòkòrò tó ń fa àrùn tí à ń pè ní “ẹgbẹ́ bakitéríà. sitẹrẹpitókókálì" tí ó ń fà.[1] Ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà máa ń yọ ọ̀nà-ọ̀fun, àwọn bèlúbèlú (àwọn gíláńdì rìbìtì méjì tí ó wà ní ọ̀nà-ọ̀fun, ní ẹ̀yìn ẹnu), àti bí ó bá ṣe é ṣe àpótí ohùn (larynx) lẹ́nu. Àwọn àmì àìsàn tí ó wọ́pọ̀ ní nínú ibà, ọ̀nà-ọ̀fun tí ó ń dun ni (tí a tún ń pè ní ọ̀fun tó ń dun ni, àti àwọn nódù ẹ̀jẹ̀ funfun tí ó wú (lymph nodes) ní ọrùn. Ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà máa ń fa ìdá mẹ́tàdínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún (37%) ọ̀nà-ọ̀fun tí ó ń dun ni láàrín àwọn ọmọdé.[2]

Streptococcal pharyngitis
Streptococcal pharyngitisA culture positive case of streptococcal pharyngitis with typical tonsillar exudate in a 16 year old.
Streptococcal pharyngitisA culture positive case of streptococcal pharyngitis with typical tonsillar exudate in a 16 year old.
A culture positive case of streptococcal pharyngitis with typical tonsillar exudate in a 16 year old.
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10J02.0 J02.0
ICD/CIM-9034.0 034.0
DiseasesDB12507
MedlinePlus000639

Ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà máa ń tàn nípasẹ̀ ìfarakora pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú aláìsàn kan. Láti ríi dájú wí pé ènìyàn kan ní ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a a kò le fojú lásán rí ń fà èyí tí ó ń dun ni, àyẹ̀wò kan tí à ń pè ní mímú àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí dàgbà lórí nǹkan amú-nǹkan ẹlẹ́mìí dàgbà l’óde ara láti inú ọ̀nà-ọ̀fun (throat culture) fún ìwádìí ṣe pàtàkì. Láì ṣe àyẹ̀wò yìí pàápàá, a le mọ̀ nípa ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà nípasẹ̀ àwọn ààmì àìsàn. Ní èyí ti ó jọ bẹ́ẹ̀ tàbí tí a mọ̀ dájú, àwọn apa-kòkòrò (antibiotics) (àwọn oògùn tí ó ń pa bakitéríà) le dẹ́kun àìsàn náà láti má léwu gan-an àti láti mú ara padà bọ́ sípò ní kíákíá.[3]

Àwọn ààmì àìsàn

àtúnṣe

Ààmì àìsàn tí ó wọ́pọ̀ fún ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà ní ọ̀nà-ọ̀fun tí ó ń dun ni, ibà tí ó ju 38°C (100.4°F) lọ, ọyún (olómi yẹ́lò tàbí aláwọ̀-ewé) tórí bélúbélú, àti àwọn gíláńdì tí ó wú nínú ọrùn.[3]

Àwọn ààmì àìsàn mìíràn tún le wà:

  • Orí tí ó ń dun ni (ẹ̀fọ́rí)[4]
  • Èébì bíbì tàbí èébì tí ó ń gbé ní [4]
  • Inú tí ó ń dun ni (Inú ríro)[4]
  • Iṣan tí ó ń dun ni [5]
  • Èélá (tí ó wú díẹ̀ tí ó pọ́n) ní ara tàbí nínú ẹnu tàbí ní ọ̀nà-ọ̀fun (èyí tí kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n àmì àìsàn tí ó dájú ní pàtó) [3]

Ẹni tí ó bá ní ọ̀nà-ọ̀fun dídùn tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà yóò fi àwọn àmì àìsàn hàn láàrin ọjọ́ kìn-ín-ní sí ìkẹta lẹ́yìn tí ó ní ìfarakora pẹ̀lú aláìsàn kan.[3] Àdàkọ:Gallery

Òkunfà

àtúnṣe

Àwọn kòkòrò tó ń fa àrùn (tàbí bakitéríà) tí à ń pè ní ẹgbẹ́ sitẹrẹputokokúsì tí bítà (A beta-hemolytic streptococcus) (GAS) ló ń se okùnfà ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà.[6] Àwọn kòkòrò mìíràn tó ń fa àrùn tún le fa ọ̀nà-ọ̀fun tí ó ń dun ni.[3][5] Ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà máa ń tàn nípasẹ̀ ìfarakora pẹ́kípẹ́kí ní tààrà pẹ̀lú aláìsàn kan. Ọ̀pọ̀ ènìyàn, bíi àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ-ogun tàbí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ máa ń mú kí àìsàn náà tàn káàkiri láti pọ̀ si.[5][7] Àwọn kòkòrò tó ń fa àrùn tí a kò le fojú rí tí wọ́n ti gbẹ tán tí a sì rí nínú erùpẹ̀ tí ó le sọ ènìyàn di aláàárẹ̀. Àwọn kòkòrò tó ń fa àrùn tí kò tíì gbẹ, bíi èyí tí a rí lórí pákó-òyìnbó (búrọ̀ṣì), lè jẹ́ kí ènìyàn ṣe àárẹ̀ fún bí ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún (15 days).[5] Kò wọ́pọ̀ kí àwọn kòkòrò tó ń fa àrùn tí a kò fojú rí yìí láti wà nínú oúnjẹ kí wọ́n sì mú àwọn tí wọ́n jẹ oúnjẹ náà ṣe àárẹ̀.[5] ìdá méjìlá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé tí kò ní àwọn ààmì àìsàn kan fún ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà ń gbé afẹ́fẹ́ (GAS) àwọn kòkòrò tí ó ń fa àrùn káàkiri nínú ọ̀fun wọn.[2]

Fífi ìdí ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò ti a kò le fojú lásán rí ń fà múlẹ̀

àtúnṣe
Modified Centor score
Points Ṣíṣe é ṣe kòkòrò tó ń fa ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni Àbójútó
1 tàbí èyí ti ó kéré sí èyí <10% Kò nílò òògùn apakòkòrò tàbí àyẹ̀wò kòkòrò tó ń fà á rárá
2 11–17% Òògùn apakòkòrò tí ó dá lé orí mímu nǹkan ẹlẹmii tí a mu dàgbà lórí nǹkan amu ẹlẹmi dagba l’óde ara láti ọ̀nà-ọ̀fun tàbí RADT
3 28–35%
4 tàbí 5 52% Òògùn apakòkòrò tí ó dájú nípa ìrírí

Àkójọ àwọn àbùdá tí à ń pè ní iye Sẹ́ńtọ̀ tí ó jẹ́ àtúnṣe (modified Centor score) ni à ń lò láti mọ bí a ti ń ṣe àbójútó àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ọ̀nà-ọ̀fun tí ó ń dun ni. Èyí dá lórí àbùdá ọ̀nà àyẹ̀wò tí ìwádìí nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti òyìnbó márùn-ún, iye Sẹ́ńtọ̀ náà ń ṣe Ìtọ́kasí bí ọ̀nà-ọ̀fun tí ó ń dun ni ṣe le wáyé sí.[3]

Ààmì kan ni a fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àbùdá wọ̀nyí: [3]

  • Kò sí ikọ́ kankan
  • Àwọn gíláǹdì tí ó wú tí ó sì rọ̀ ninu ọrùn
  • Ìwọ̀n gbígbóná tí ó ju 38°C (100.4°F) lọ
  • Ọyún tàbí wíwú àwọn gíláǹdì nínú ọrùn (bèlúbèlú)
  • Ọjọ́ orí tí ó kéré sí mẹ́ẹ̀dógún (15) (àmì kan ni a yọ kúrò fún ọjọ́ orí tí ó ju mẹ́rìnléógójì (44) lọ)

Àyẹ̀wò Iṣẹ́ ìwádìí nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀

àtúnṣe

Àyẹ̀wò kan tí à ń pè ní mímú nǹkan ẹlẹ́mìí tí a mú dàgbà lórí nǹkan a mú ẹlẹ́mìí dàgbà l’óde ara láti ọ̀nà-ọfun (throat culture) ni ọ̀nà tí ó ṣe kókó jù lọ. [8] láti mọ̀ bóyá ènìyàn kan ní ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú rí. Àyẹ̀wò yìí máa ń mọ ní ọ̀nà tí ó dánilójú ìdá 90 si 95 nínú àwọn tí ó ṣe àìsàn tí a yẹ̀wò. [3] Àyẹ̀wò kan tí à ń pè ní àyẹ̀wò kòkòrò tó ń fà á ní kánkán (èyí tí a tún ń pè ní àyẹ̀wò mímọ antigini ní kánkán (rapid antigen detection testing), tàbí RADT) tún ṣe é lò. Àyẹ̀wó kòkòrò tó ń fà á ní kánkán yára ju mímu nǹkan ẹlẹ́mìí tí a mu dàgbà lórí nǹkan a mú ẹlẹ́mìí dàgbà l’óde ara láti ọ̀nà-ọ̀fun lò ṣùgbọ́n ó máa ń mọ àìsàn dájú nínú ìdà ààdọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún (70 percent) àwọn ènìyàn tí a yẹ̀wò. Àwọn àyẹ̀wò mejeeji le mọ ní ọgbọọgba nígbà ti ènìyàn kò bá ní ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú rí ń fà (ní ìdá méjìdínlọ́gọ̀rún àwọn ènìyàn tí a yẹ̀wò (98 percent)).[3]

Àyẹ̀wò nǹkan ẹlẹmi tí a mu dàgbà lórí nǹkan a mú ẹlẹmi dàgbà lóde ara láti ọ̀nà-ọ̀fun tí ó rí bẹ́ẹ̀ (ni ọ̀rọ̀ mìíràn, èyí tí o mọ̀ wí pé ènìyàn ṣe àìsàn) tàbí àyẹ̀wò kòkòrò tó ń fà á ní kánkán, pẹ̀lú àwọn ààmì àìsàn ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú rí ń fà, n fìdí wíwá àìsàn náà múlẹ̀.[9] A kò gbọdọ̀ máa ṣe àyẹ̀wò nǹkan ẹlẹmi tí á mú dàgbà lórí nǹkan a mu ẹlẹmi dàgbà l’óde ara láti ọ̀nà-ọ̀fun tàbí àyẹ̀wò kòkòrò tó ń fà á ní kánkán lóòrèkóòrè fún àwọn ènìyàn tí kò ní ààmì àìsàn. Ìdá àwọn ènìyàn kan láwùjọ ni kòkòrò àìfojú lásán rí streptokokal bakitéríà náà nínú ọ̀fun wọn láì sí àbájáde ewu kankan.[9]

Àwọn àìsàn mìíràn tí a tún le sì mú fún ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a ko le fojú lásán rí ń fà

àtúnṣe

Àdàkọ:Tun wo Àwọn ààmì àìsàn ọ̀nà-ọ́fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà fi ara jọ àwọn ààmì àìsàn mìíràn. Fún ìdí èyí , mímọ ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí mọ̀ láì lo nǹkan ẹlẹ́mìí tí a mú dàgbà lórí nǹkan a mú ẹlẹ́mìí dàgbà l’óde ara láti ọ̀nà-ọ̀fun tàbí àyẹ̀wò kòkòrò tó ń fa ni kankan láti le sọ̀rọ̀. [3] Ikọ́ wíwú, fi fún ikun-imú, ìgbẹ́-ọ̀rin àti ojú pípọ́n tí ó ń ta ni ní àfikún pẹ̀lú ibà àti ọ̀nà ọ̀fun tó ń dun ni lè fẹ̀ ẹ́ jẹ́ ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí tí fáírọ̀sì (virus) fà jù kí ó jẹ́ ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà lọ.[3] Wíwá àwọn gíláńdì ti ó wú (lymph nodes) nínú ọrùn pẹ̀lú ọ̀nà-ọ̀fun tí ó ń dun ni, ibà ati àwọn gíláńdì tí ó tóbi (àwọn bèlúbèlú) nínú ọrùn le tún wáyé nínú àwọn àìsàn mìíràn tí à ń pè ní infectious mononucleosis.[10]

Dídẹ́kun

àtúnṣe

Yíyọ àwọn bèlúbèlú kúrò le jẹ́ ọ̀nà tí ó lóye láti dẹ́kun ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà nínú àwọn ènìyàn tó máa ń sáábà ní àìsàn náà.[11][12] Ṣíṣe àìsàn pẹ̀lú ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí fún ìgbà mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ọdún kan ni a rí bíi ìdí láti yọ àwọn bèlúbèlú kúrò, ní títí di ọdún 2003.[13] Kíkíyèsára nígbà tí ènìyàn ń dúró náà tún tọ̀nà.[11]

Títọ́jú

àtúnṣe

Ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú rí ń fà èyí tí a kò tọ́jú máa ń sáábà yanjú ara rẹ̀ láàrin ọjọ́ mélòó kan.[3] Ìtọ́jú pẹ̀lú òògùn (àwọn apakòkòrò) máa ń dín pípẹ́ àwọn ààmì àìsàn kù fún bíi wákàtí mẹ́rìndínlógún (16 hours).[3] Ìdí àkọ́kọ́ fún títọ́jú pẹ̀lú àwọn apakòkòrò ni láti dín ewu níní àìsàn tí ó léwu gan-an, bíi ibà tí ó léwu (tí a mọ̀ ní ibà rọ́ọgun-rọ́ọgun)tàbí àkójọ ọyún nínú ọ̀fun (tí a mọ̀ sí retropharyngeal abscesses) ku[3]. Àwọn òògùn wọ̀nyí múnádóko bí a bá lò ó láàrin ọjọ́ mẹ́sàn-án (9 days) tí àwọn àmì àìsàn bẹ̀rẹ̀.[6]

Àbójútó ìrora

àtúnṣe

Òògùn láti dín ìrora kù, bíi òògùn tí ó ń dín wíwú kù (non-steroidal anti-inflammatory drugs, tàbí NSAIDs) tàbí òògùn tí ó ń dín ibà kú (parasitamọ,tabi asẹtaminofeni), lè ranni lọ́wọ́ láti ṣàkóso ìrora tí ó ní àsopọ̀mọ́ ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà.[14] Àwọn sítẹ́ríọ́dù náà tún wúlò [6][15], gẹ́gẹ́ bíi kírìmù tàbí olómi tí à ń pè ní lidokáínì.[16] A le lo asipirínì fún àwọn àgbàlagbà ṣùgbọ́n a kò gbani nímọ̀ràn láti lò ó fún àwọn ọmọdé nítorí ó máa ń mu ewu níní àìsàn tí ó mú ewu bá ẹ̀mí ẹni tí à ń pè ní àkójọ àìsàn Reye (Reye's syndrome)gberu.[6]

Òògùn apakòkòrò (Antibiotics)

àtúnṣe

Òògùn apakòkòrò jẹ́ ààyò ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fún títọ́jú ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni èyí tí kòkòrò ti a kò le fojú lásán rí ń fà ni pẹnisilini V. Òògùn yìí gbayì nítorí àìléwu rẹ̀, owó rẹ̀ tí kò wọ́n àti mímúnádóko rẹ̀. [3] Òògùn tí à ń pè ní amosilini ni wọ́n yàn ní Europe.[17] Ní India, ní ibi tí ewu níní ibà rọ́ọgun-rọ́ọgun ti ga gan-an, òògùn alábẹ́rẹ́ tí à ń pè ní bẹnsatini pẹnisilini G ni ààyò àkọ́kọ́ fun abojuto.[6] Òògùn apakòkòrò tí ó tọ̀nà máa ń dín iye ìgbà ààmì àìsàn kù (èyí tí ó jẹ́ ọjọ́ mẹ́ta sí márùn-ún) fún bí ọjọ́ kan. Àwọn òògùn wọ̀nyí tún máa ń dín títàn káàkiri àìsàn náà kù.[9] A máa ń kọ àwọn òògùn náà fún lílò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti gbìyànjú láti dín àwọn ewu tí kò wọ́pọ̀ bíi ibà tí ó le gan-an,ara tó ń janijẹ, tàbí àwọn àrùn kù. [18] Àwọn ànfàní ṣíṣe àbójútó ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le f’ojú lásán rí pẹ̀lú òògùn apakòkòrò ni a gbọ́dọ̀ mú dọ́gba pẹ̀lú àwọn ewu tí ó le wáyé pẹ̀lú lílò wọn [5]. A kò nílò láti fún àwọn àgbàlagbà tí ara wọn dá sáká tí wọ́n ní ìhùwàsí ara sí àwọn òògùn èyí tí kò dára ni òògùn apakòkòrò fún ìtọ́jú. [18] Àwọn òògùn apakòkòrò ni a kọ fún lílò fún ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà ní ipò tí ó ga gan-an ju èyí tí a lérò lọ nítorí bí ó ti ṣe léwu sí àti bí ó ṣe ń tàn káàkiri. [19] Òògùn eritiromaisini (àti àwọn òògùn mìíràn tí à ń pè ní mákírólídì) ni a gbà àwọn ènìyàn tí ara wọn ní ìkórira tí ó le sí pẹnisilini níyànjú láti lo.[3] Àkọ́kọ́, oríṣi òògùn tí à ń pè ní sẹfalosiporini ṣe é lò fún àwọn tí ara wọn ní ìkórira tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu. [3] Àwọn àrùn tí kòkòrò streptokokal tí a kò le fojú lásán rí ń fà (Streptococcal infections) tún le fa wíwú àwọn kídìrín. Àwọn òògùn apakòkòrò kò le dín níní èyí kù. [6]

Àwọn ààmì àìsàn ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà máa ń san nípa ṣíṣe àbójútó rẹ̀ tàbí àìṣe àbójútó rẹ̀, láàrin ọjọ́ mẹ́ta sí márùn-ún. [9] Ṣíṣe àbójútó pẹ̀lú òògùn apakòkòrò máa ń dín ewu àwọn àìsàn tí ó léwu kù àti títàn káàkiri àìsàn náà. Àwọn ọmọdé le padà sí ilé-ẹ̀kọ́ lẹ́yìn wákàtí mẹ́rìnlélógún (24 hours) tí wọ́n bá ti lo òògùn apakòkòrò.[3]

Àwọn ìṣòro tí ó léwu gan-an wọ̀nyí le wáyé nítorí ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà:

  • Àwọn ibà tí ó le gan-an, bíi ibà rọ́ọgun-rọ́ọgun [4] tabi ibà Àlàárì (Scarlet fever)[20]
  • Àìsàn tí ó ń kó ewu bá ẹ̀mí ẹni tí à ń pè ní àkójọ àìsàn tí ó wáyé nípasẹ̀ idiji màjèlé (toxic shock syndrome)[20][21]
  • Wíwú àwọn Kídìrín [22]
  • Àìsàn kan tí à ń pè ní àkójọ àìsàn PANDAS (PANDAS syndrome)[22], ìṣòro pẹ̀lú àjẹsára tí ó máa ń fà á nígbà mìíràn àwọn ààmì àìsàn tí ó l’éwu gan-an nípa ìhùwàsí, lójijì.

Àwọn àwòṣe àti títàn káàkiri àìsàn náà

àtúnṣe

Ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni (tàbí faringitísì), ìsọ̀rí tí ó gbòòrò nínú èyí tí ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí wà, ni a ṣe àwárí rẹ̀ nínú àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mọ́kànlá (11 million) l’ọ́dọọdún ní orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà.[3] Fáírọ́ọ̀sì ni ó máa ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀nà-ọ̀fun tó ń dun ni tí kòkòrò tí a kò le fojú lásán rí ń fà. Ṣùgbọ́n, ẹgbẹ́ bakitéríà tí kòkòrò tí a kò le fojú rí ti bítà (group A beta-hemolytic streptococcus) máa ń fà nínú ọgọ́rùn-ún ìdá 15 sí 30 ọ̀fun tí ó ń dun ni láàrín àwọn ọmọdé àti sí 20 láàrin àwọn àgbàlagbà.[3] Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ máa ń sábà wáyé nígbà tí jíjábọ̀ yínyìn bá ń kâsẹ̀ ń lẹ̀ tí ọ̀rini (Spring) sí ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀.[3]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "streptococcal pharyngitis" at Dorland's Medical Dictionary
  2. 2.0 2.1 Shaikh N, Leonard E, Martin JM (September 2010). "Prevalence of streptococcal pharyngitis and streptococcal carriage in children: a meta-analysis". Pediatrics 126 (3): e557–64. doi:10.1542/peds.2009-2648. PMID 20696723. 
  3. 3.00 3.01 3.02 3.03 3.04 3.05 3.06 3.07 3.08 3.09 3.10 3.11 3.12 3.13 3.14 3.15 3.16 3.17 3.18 3.19 3.20 Choby BA (March 2009). "Diagnosis and treatment of streptococcal pharyngitis". Am Fam Physician 79 (5): 383–90. PMID 19275067. http://www.aafp.org/afp/2009/0301/p383.html. 
  4. 4.0 4.1 4.2 4.3 Brook I, Dohar JE (December 2006). "Management of group A beta-hemolytic streptococcal pharyngotonsillitis in children". J Fam Pract 55 (12): S1–11; quiz S12. PMID 17137534. 
  5. 5.0 5.1 5.2 5.3 5.4 5.5 Hayes CS, Williamson H (April 2001). "Management of Group A beta-hemolytic streptococcal pharyngitis". Am Fam Physician 63 (8): 1557–64. PMID 11327431. Archived from the original on 2008-05-16. https://web.archive.org/web/20080516091711/http://www.aafp.org/afp/20010415/1557.html. Retrieved 2014-01-03. 
  6. 6.0 6.1 6.2 6.3 6.4 6.5 Baltimore RS (February 2010). "Re-evaluation of antibiotic treatment of streptococcal pharyngitis". Curr. Opin. Pediatr. 22 (1): 77–82. doi:10.1097/MOP.0b013e32833502e7. PMID 19996970. 
  7. Lindbaek M, Høiby EA, Lermark G, Steinsholt IM, Hjortdahl P (2004). "Predictors for spread of clinical group A streptococcal tonsillitis within the household". Scand J Prim Health Care 22 (4): 239–43. doi:10.1080/02813430410006729. PMID 15765640. 
  8. Smith, Ellen Reid; Kahan, Scott; Miller, Redonda G. (2008). In A Page Signs & Symptoms. In a Page Series. Hagerstown, Maryland: Lippincott Williams & Wilkins. pp. 312. ISBN 0-7817-7043-2. 
  9. 9.0 9.1 9.2 9.3 Bisno AL, Gerber MA, Gwaltney JM, Kaplan EL, Schwartz RH (July 2002). "Practice guidelines for the diagnosis and management of group A streptococcal pharyngitis. Infectious Diseases Society of America". Clin. Infect. Dis. 35 (2): 113–25. doi:10.1086/340949. PMID 12087516. 
  10. Ebell MH (2004). "Epstein-Barr virus infectious mononucleosis". Am Fam Physician 70 (7): 1279–87. PMID 15508538. Archived from the original on 2008-07-24. https://web.archive.org/web/20080724055725/http://www.aafp.org/afp/20041001/1279.html. Retrieved 2014-01-03. 
  11. 11.0 11.1 Paradise JL, Bluestone CD, Bachman RZ, et al. (March 1984). "Efficacy of tonsillectomy for recurrent throat infection in severely affected children. Results of parallel randomized and nonrandomized clinical trials". N. Engl. J. Med. 310 (11): 674–83. doi:10.1056/NEJM198403153101102. PMID 6700642. 
  12. Alho OP, Koivunen P, Penna T, Teppo H, Koskela M, Luotonen J (May 2007). "Tonsillectomy versus watchful waiting in recurrent streptococcal pharyngitis in adults: randomised controlled trial". BMJ 334 (7600): 939. doi:10.1136/bmj.39140.632604.55. PMC 1865439. PMID 17347187. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=1865439. 
  13. Johnson BC, Alvi A (2003). "Cost-effective workup for tonsillitis. Testing, treatment, and potential complications". Postgrad Med 113 (3): 115–8, 121. PMID 12647478. 
  14. Thomas M, Del Mar C, Glasziou P (October 2000). "How effective are treatments other than antibiotics for acute sore throat?". Br J Gen Pract 50 (459): 817–20. PMC 1313826. PMID 11127175. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=1313826. 
  15. "Effectiveness of Corticosteroid Treatment in Acute Pharyngitis: A Systematic Review of the Literature.". Andrew Wing. 2010; Academic Emergency Medicine. Archived from the original on 2012-12-04. 
  16. "Generic Name: Lidocaine Viscous (Xylocaine Viscous) side effects, medical uses, and drug interactions". MedicineNet.com. Retrieved 2010-05-07. 
  17. Bonsignori F, Chiappini E, De Martino M (2010). "The infections of the upper respiratory tract in children". Int J Immunopathol Pharmacol 23 (1 Suppl): 16–9. PMID 20152073. 
  18. 18.0 18.1 Snow V, Mottur-Pilson C, Cooper RJ, Hoffman JR (March 2001). "Principles of appropriate antibiotic use for acute pharyngitis in adults". Ann Intern Med 134 (6): 506–8. PMID 11255529. http://www.annals.org/cgi/reprint/134/6/506.pdf. 
  19. Linder JA, Bates DW, Lee GM, Finkelstein JA (November 2005). "Antibiotic treatment of children with sore throat". J Am Med Assoc 294 (18): 2315–22. doi:10.1001/jama.294.18.2315. PMID 16278359. http://jama.ama-assn.org/cgi/content/full/294/18/2315. 
  20. 20.0 20.1 "UpToDate Inc.". 
  21. Stevens DL, Tanner MH, Winship J, et al. (July 1989). "Severe group A streptococcal infections associated with a toxic shock-like syndrome and scarlet fever toxin A". New England Journal of Medicene 321 (1): 1–7. doi:10.1056/NEJM198907063210101. PMID 2659990. 
  22. 22.0 22.1 Hahn RG, Knox LM, Forman TA (May 2005). "Evaluation of poststreptococcal illness". Am Fam Physician 71 (10): 1949–54. PMID 15926411.