Sugar Ray Robinson (orúkọ àbísọ Walker Smith Jr.; May 3, 1921 – April 12, 1989) jẹ́ oníṣẹ́ ìjàẹ̀sẹ́ ará Amẹ́ríkà to jìjàdù láti ọdún 1940 di 1965. Idú tí Robinson ta nínú àwọn ẹ̀ka welterweight àti middleweight mú kí àwọn oniròyìn eréìdárayá ó dá ìtòsípò tó ún jẹ́ "pound for pound" (ẹ̀sẹ́ sí ẹ̀sẹ́), níbi tí wọ́n ti ṣe ìwéra àwọn ajaẹ̀sẹ́ sí ara wọn láìkàsí ẹ̀ka agbára wọn. Wọ́n fi ọrúkọ rẹ̀ sí inú Ilé Olọ́kìkí Ìjaẹ̀ṣẹ́ Àgbáyé ní 1990.[1] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ní wọ́n gba Robinson gẹ́gẹ́bí ajaẹ̀sẹ́ ẹnínlá tó lókìkí jùlọ ní gbogbo ìgba ayé, bẹ́ ẹ̀ sì ni ní ọdún 2002, iwé-ìroyìn The Ring fi Robinson sí ipò kínní nínú àtòjọ tí wọ́n ṣe fún "80 Best Fighters of the Last 80 Years" (Àwọn Ajaẹ̀sẹ́ Adárajùlọ 80 ti ọdún 80 Tókọjá).[2]

Sugar Ray Robinson
Afẹ̀ṣẹ́jà ará ìlú Amẹ́ríkà Sugar Ray Robinson (ọdún 1921 sí ọdún 1989) tí ó wáyé ní òkè nípasẹ̀ àwọn afẹ̀ṣẹ́jà mìíràn.
Statistics
Real nameWalker Smith Jr
Rated at
Height5 ft 11 in
Reach72+1/2 in
Birth date(1921-05-03)3 Oṣù Kàrún 1921
Birth placeAiley, Georgia, U.S.
Death dateApril 12, 1989(1989-04-12) (ọmọ ọdún 67)
Death placeLos Angeles, California, U.S.
StanceOrthodox
Boxing record
Total fights200
Wins172
Wins by KO109
Losses19
Draws6
No contests2