Tèmítọ́pẹ́ Ṣólàjà
Tsèmítọ́pẹ́ Ṣólàjà tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí '"Star Girl" jẹ́ òṣèrébìnrin, olùgbéré-jáde, ònkọ̀tàn ,oníṣòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .[1]
Ìgbà èwe rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Tọ́pẹ́ ní ìlú Ṣàgámù ní Ìpínlẹ̀ Ògun. Òun ni àkọ́bí àwọn òbí rẹ̀, amọ́ ìyá rẹ̀ ni ó tọ dàgbà látàrí ìpínyà tí ó dé bá ìgbéyàwó àwọn òbí rẹ̀.
Ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeTọ́pẹ́ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ "Obani" tí ó wà ní ìlú Ṣàgámù ní Ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti Ìkẹ́nẹ́ Rẹ́mọ ní ìpínlẹ̀ Ògùn, níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí ìwé mẹ́wàá. Ní ọdún 20017, ó wọlé sí ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì Tai Ṣólàrí láti kọ́ nípa ìmọ̀ Mass Communication.[2]
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré
àtúnṣeTọ́pẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣiṣẹ́ ní ọdún 2007, nígba tí ó kópa nínú eré Bámitálẹ́, eré tí Afeez Ẹniọlá gbé jáde. Afeez ń ya apá kan eré yí ní inú ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì Tai Ṣólárín tí ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn olùwòran bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ́ sí láti kópa gẹ́gẹ́ bí Arugbá kejì. Ẹniọlá ati ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ọ̀gbẹ́ni Ẹjalónibú pẹ̀lú gbajú-gbajà òṣèré Adébáyọ̀ Tìjání ni wọ́n ṣe àyẹ̀wò fun tí ó sì yege. Lẹ́yìn tí Tọ́pẹ́ bá wọn kópa níní eré yí gblẹ́gẹ́ bí Arugbá tán, ó padà lọ bá Afeez Ẹniọlá láti daraọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré rẹ̀ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì. Ó tẹ̀ siwájú láti máa ṣeré orí-ìtàgé Yorùbá títí ó fi jáde ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀, àmọ́ èyí ṣe àkóbá fún ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó sì jẹ́ kí ọdún jan ó tún orí ọdún tí ó yẹ kí ó jáde ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ó ti kópa nínú eré tí ó ti tó Inú eré Yorùbá nìkan ni ó ti ma ń kópa, amọ́ o kópa nínú eré gẹ̀ẹ́sì lẹ́ẹ̀kan, eré tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ The Antuque. Eré tí D.J Tee kọ tí Darasen Richards sì gbé jáde. Tọ́pẹ́ náà kọ eré tìrẹ tí ó pè ní Arugbá tí gbajúmọ̀ òṣèré Antar Láníyan darí rẹ̀ ní ọdún 2015. Ó tún gbé eré Ashabi Akata jáde ní ọdún 2017, eré tí Ibrahim Yẹ̀kínì darí rẹ̀. Eré yí ni Azeezat Ṣórónmú kọ, tí àwọn òṣèré bí Bímbọ́ Ọ̀ṣìn Níyì Jhonson ati Jumoke George ti kópa Ṣólàjà gẹ́hẹ́ bí oníṣòwò ni ó ni ilé-ìtajà aṣọ Star Girl Luxury Store.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Temitope Solaja: Biography, Age, Movies, Family & Career". Nigerian Finder. 2019-01-11. Retrieved 2020-11-22.
- ↑ "Temitope Solaja (Aruga) (Producer, Writer, Actress, Location Management) - Biography, Photo, and Movies". INSIDENOLLY. 1954-01-12. Archived from the original on 2020-10-24. Retrieved 2020-11-22.
- ↑ Theayoadams. "Award-winning Nollywood Actress Temitope Solaja unveils her Perfume Brand". Opera News. Archived from the original on 2020-11-30. Retrieved 2020-11-22.