[1]SỌRỌSOKE ('TALKAM) jẹ́ ìpilẹ̀sẹ̀ Devatop Centre For Africa Development, ibùdó tó ń jà fún ètọ́ ọmọ ènìyàn tí ó gúnwá sí orí ìtàkùn ayélujára tí ó ń pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàyé àti dátà lórí kíkó àwọn ènìyàn ní ọ̀nà àìtọ́ àti jíjà fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹgbẹ́ láwùjọ, ilé -iṣẹ́, àwọn amòyè fún ìdàgbàsókè, àwọn ajìjàgbara fún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn, àwọn agbófinró àti àwọn àjọ tó ń sojú ìjọba. TALKAM jẹ́ èdè pidgin tí ó túmọ̀ sí sọ̀rọ̀sókè, ó kún fún àwọn wọ̀nyìí: ohun èlò ìròyìn ayélujára, ètò ajàfẹ́ẹ̀tọ́ lórí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì ní ọ̀sẹ̀ẹ̀sẹ̀, ìsàkóso ọ̀ràn tí óbá sẹlẹ̀, nọ́m̀bà tí a le yára pè, whatsapp, ìpolongo lágbègbè àti ìdánilẹ́ẹ̀kọ. Pèlu ohun èlò ìròyìn ayélujára, ó rọrùn fún àwọn ènìyàn káàkiri orílẹ̀ èdè Nàíjírìà láti kàn sìwa lórí ọ̀ràn tí ó bá sẹlẹ̀ níbì kan lẹ́yìí tí à ń se ìsàkóso àti àmójútó fún ẹni tí ó ń jìyá ìpalára. Ohun èlò ìròyìn ayélujára àti ètò lórí asọ̀rọ̀mágbèsì ti di gbajúgbajà láwùjọ láti lè máa lọgun ìlòkulò àwọn ènìyàn.

[2]Ní ọdún 2018, ibùdó yìí ṣe ìsirò àwọn ènìyàn tó ń gbé ní oko ẹrú ìgbàlódé jẹ́ mílíọ̀nù kan lé ní ẹ́ẹ̀rin dín láádọ́rúùn lé ní ọ̀ọ̀dúnrún (1, 386,000), ìwòtun rẹ j́ẹ́ méje lé pẹ́sẹ́pẹ́sẹ́ ní́nú́ ẹgbẹ̀rún kan (7.65 in 1000) nígbàtí ìwòtún àwọn tó le è ńi ìpalára wíwà lóko ẹrú ìgbàlódé jẹ́ ẹ́ẹ̀rìn lé láàdọ́rin lé pẹ́sẹ́pẹ́sẹ́ (74.07/100). Ọ́f́iìsì wọn wà ní Zone 2, Municipal Council, 22 Koforidua St, Wuse 90028, Àbújá.

  • SỌRỌSOKE (TALKAM) ṣe àkọsílẹ̀ ọ̀ràn tó tó ààdọ́rin níye(70 cases) láti ọdún 2020.
  • [3]Fèsí sí ó lé ní ọgbọ̀n níye.
  • Ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ fún igba alágbàwí fún ẹ̀tọ ọmọ ènìyàn ní ọgbọ̀n ìpínlẹ̀ àti dídé ẹ́ẹ́fàléláàdọ́ta agbègbè.
  • Ìfòyeyé ènìyàn tó ju mílíọ̀nù kan ààbò lọ lórí ètò ìjàfún ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn lọ́sẹ̀̀ẹ̀sẹ̀ ló́ asọ̀rọ̀mágbèsì(Cool FM, Wazobia FM ati Ku FM).
  • Àt̀ilẹyìn láti ọ̀dọ̀ U.S Embassy, International Centre for Investigative Reporting,Seed For Change, National Agency For Prohibition of Trafficking in Persons and Human Rights Commission láar̀in ọdún méjì sẹyìn.
  • Ìmúṣẹ ìfarahàn iṣẹ́ àkànṣe ẹlẹ́ẹ̀kẹta TALKAM, níbi tí a tiṣe ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ fún àwọn áàrún lélọgóta alágbàwí ajàfún ẹ̀tó ọmo ènìyàn ní ọgbọ̀n ìpínlẹ̀ lórílè èdè Nà̀íjíríà
  • Ìdánilẹ́ẹ̀kọ lóŕi kíkó káàkiri àwọn ènìyàn lọ́nà àìtọ́, ìwà-ipá lórí ìmọ̀ akọ àti abo,ìwà-ipá lòdì sí ọmọkùnrin tàbí àwọn ọkùnrin,ìfipábánilòpọ̀ àti ìlòkulò ọmọ.
  • Áàrún lélọ́gbòn nínú àwọn tí a dá lẹ́ẹ̀kọ láti ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún gbé ìgbésè ìpolongo ní agbègbè ọgbọn níye~ àti lórí ẹ̀rọ ayélujára.
  • Ẹ̀kọ́ fún àwọn tó lé ní irinwó lélẹ́gbẹ̀rún méjì (2,400).
  • Lara àwọn alágbàwí tí ó gba ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ ń ṣe iṣẹ́ alámójútó àti ìròyìn lórí ìlòkulò ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn lílo ohun èlò ìròyìn ayélujára.
  • Ìdánilẹ́ẹ̀kọ́ fún ééjì lé láádọ́rin ẹgbẹ́ alágbàwí fún ìdojú kọ ìwà- ipá lórí ìmọ̀ akọ tàbí abo.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe

[4]

  1. https://soundcloud.com/user-144829469/talkam-human-rights-program-on-11th-dec-2021
  2. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2022-03-30. Retrieved 2022-03-30. 
  3. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2022-02-28. Retrieved 2022-03-30. 
  4. https://www.devatop.org/talkam-human-rights-project/