Ta ni Olùwúre?

Ní àkókó iwúre, ẹni tó bá dàgbà jùlọ nínú ẹbí tabí ninú àpèjo ni àwọn Yorubá máa n fi í sí lẹ́nu láti wúre. Ṣé irírí ni ki í jẹ́ ki a pe àgbà ní wèrè. Yàto sí èyí, àwọn tí wọ́n bá ń ṣe ayeye le yan ẹnìkan ki wọ́n mú ti ọjọ́ orí kúrò tí wọ́n rò pé ó ní irírí nípa à ń wúre nítorí pé ó jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ àgbà. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni yóó wúre.

Níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, bàbá tàbí ìyá ọmọ tí à ń sìn lọ sí ilé ọkọ le wúre fún ọmọ. Nígbà miíràn ẹ̀wẹ̀, ìyá àti bàbá ọmọ a máa wúre fún ọmọ wọn. Àwọn àgbààgbà nínú mọ̀lẹ́bí máa ń lọ́wọ́ nínú iwúre báyií. Ṣé ọ̀pọ̀ irú ni àdúà, kì í ba ọbẹ̀ jẹ́. Ọ̀gá níbi iṣẹ́ ní sáábà wúre fún ọmọ abẹ́ rẹ̀ tí ó bá kọ́ṣẹ́ parí níbi ayẹyẹ iwúre. Nígbà miíràn ẹ̀wẹ̀, eni ọ̀rá kàn le fi orí ara rẹ̀ wúre fún ara rẹ̀. Àwọn òbí, ará, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ tó fẹ́ràn irú ọmọ bẹ́ẹ̀ le wúre fún un.