Taha Karaan (2 June 1969 – 11 June 2021) jẹ́ onímọ̀ Mùsùlùmí ti orílẹ̀-èdè South Africa àti amòfin. Òun ni olórí Muslim Judicial Council, ti ilẹ̀ South Africa nígbà náà. Òun ni olùdásílè Mahajjah Research Institute àti Dar al-Uloom al-Arabiyyah al-Islamiyyah ní Strand, Western Cape.

Ìtàn ìgbésíayé rẹ̀

àtúnṣe

Ọjọ́ kejì, oṣù kẹfà, ọdún 1969 ni a bí Taha Karaan, ní Cape Town.[1][2] Òun ni ọmọ Yusuf Karaan.[3]Ó ṣe àkàsórí ìwé Kùráànì ní Waterfall Islamic Institute, ó sì lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní Darul Uloom Deoband, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 1991 pẹ̀lú èsì ìdánwò tó dára jù lọ. Ó padà lọ kàwé ní Cairo University fún ọdún méjì.[1][4] Díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ rẹ̀ ni: Saeed Ahmad Palanpuri.[1]

Wọ́n rí Taha gẹ́gẹ́ bíi onímọ̀ gbajúgbajà ní ilẹ̀ South Africa.[5] Wọ́n fi oyè "ash-Shāfi‘ī as–Sagīr" dá a lọ́lá (Al-Shafi'i kékeré) láti ọwọ́ Khalil Ibrahim Mula Khatir.[1] Ní ọdún 1996, Taha ṣe ìdásílẹ̀ Dar al-Uloom al-Arabiyyah al-Islamiyyah (DUAI) ní Strand, Western Cape.[2][6] Lábé ìṣàkóso rẹ̀,wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ DUAI ti àwọn obìnrin ní ọdún 2016, ibẹ̀ sì ni Taha ti ṣe onímọ̀ràn fún àyàn iṣẹ́.[7] Taha rọ́pọ̀ bàbá rẹ̀, Yusuf Karaan gẹ́gẹ́ bíi olórí-mufti ti Muslim Judicial Council ní ọdún 2015.[3] Òun ni olùdásílè àti olùdarí Mahajjah Research Institute tí ó bẹ̀rẹ̀ láti gbèjà "Companions of the Prophet".[1] Ó kọ Fleeing from Fate to Fate: 40 Ahadith on Contagion and Pandemics.[1]

Ó kú ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹfà, ọdún 2021, látàri ìnira àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19.[3] Àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti àwọn onímọ̀ òye ti Islam Abdur Rahman ibn Yusuf Mangera, Faraz Rabbani, Ismail ibn Musa Menk, Omar Suleiman àti Yasir Qadhi fi ìbanújẹ́ hàn lórí ikú rẹ̀ .[1]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe

Ìjápọ̀ gbangba

àtúnṣe