Tanimowo Ogunlesi (1908-2002[1]) jẹ́ ajàfẹ́ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ilẹ̀ Nàìjíríà ó tún jẹ́ adarí Women's Improvement League[2][3]. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adarí tó ń já à fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin àti ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ National Council of Women Societies, tí ń ṣe aṣáájú iléeṣẹ́ ajàfẹ́ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ti Nàìjíríà.

Tanimowo Ogunlesi
Fáìlì:Photo of Tanimowo Ogunlesi (cropped).png
Ọjọ́ìbí1908
Aláìsí2002
Orílẹ̀-èdèNigeria
Ẹ̀kọ́London University
Iléẹ̀kọ́ gígaKudeti Girls School Ibadan
United Missionary College (UMC)
Iṣẹ́Women's rights activist
Gbajúmọ̀ fúnLeader of the Women's Improvement League

Ìgbésí ayé rẹ̀

àtúnṣe

Tanimowo Ogunlesi lọ iléèkọ́ Kudeti Girls School Ibandan. Ó tún kàwé ní iléèkọ́ United Missionary College (UMC) fún ìkàwágboyè ìkẹ́ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́ bí i olùkọ́. Ó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti ṣe ìdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ oníléégbèé ní ìlú Ìbádàn (Children Home School).

Ó jẹ́ ààrẹ àkọ́kọ́ ti National Council of Women Societies ní ọdún1959[4]. Ó ṣiṣẹ́ ribiribi lórí ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin láti ma dìbò àti láti ní àǹfààní sí àwọn ohun-èlò ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí i ọ̀pọ̀ àwọn adarí obìnrin ìgbà ayé rẹ̀, Kò ní ẹjọ́ tó tako sí àwọn ọkùnrin gẹ́gẹ́ olórí àwọn ìdílé oríléèdè ilẹ̀ Nàìjíríà.[5][6]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "OGUNLESI Gladys Tanimowo Titilola (Née Okunsanya)". 3 September 2020. 
  2. "Foreign Data". Jet : 2004 (Jet Magazine (Johnson Publishing Company)): 40. December 16, 1961. ISSN 0021-5996. https://books.google.com/books?id=MrMDAAAAMBAJ&pg=PA40. 
  3. Banji Oyeniran Adediji (2013). DEEPER INSIGHT INTO NIGERIA'S PUBLIC ADMINISTRATION. AuthorHouse. ISBN 978-1-491-8347-25. https://books.google.com/books?id=5qFkAgAAQBAJ&q=Tanimowo+Ogunlesi&pg=PA476. 
  4. http://news.biafranigeriaworld.com/archive/ngguardian/2003/feb/19/article18.html Archived 2007-09-27 at the Wayback Machine. - 16k
  5. Karen Tranberg Hansen; African Encounters with Domesticity. Rutgers University Press, 1992. p. 131–133.
  6. Hajo Sani (2001). Women and national development: the way forward. Spectrum Books. p. 32. ISBN 978-9-780-2928-29. https://books.google.com/books?id=wFW1AAAAIAAJ&q=Tanimowo+Ogunlesi.