Táyọ̀ Awótúsìn

(Àtúnjúwe láti Tayo Awotusin)

Tayo Awotusin

àtúnṣe

Táyọ̀ Awótúsìn àti Chris Odiiibe: Níbi ogun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní Leberia, wọ́n pa Táyọ̀ Awótúsìn ti ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn Champion àti Chris Odiiibe ti ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn Guardian ní ọdún 1991 níbi tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ òòjọ́ wọn.

Gbigbesele Iwe Iroyin

àtúnṣe

Ní oṣù kéje ọdún 1993, ìjọba àpapọ̀ gbẹ́sẹ̀ lé títẹ̀ jáde awon ìwé-ìròyìn bi: The Concord, Press, the Punch Press, the Sketch Press, the ObserverPress and Abuja Newsday Press. Wọ́n ní wọn kò gbọ́dọ̀ tẹ ìwé-ìròyìn jade fún ọdún kan. Ní osu kẹ́fà ọdún 1994, ìjọba àpapọ̀ tún sọ pé kí the Concord Press, The Punch Press àti the Guardian Press má tẹ́ ìwé-ìròyìn wọn jade niọdún mìíràn.

Thirty Minutes of Corruption in Nigeria

àtúnṣe

Thirty Minutes of Corruption in Nigeria: Ní ọdún 1994, ilẹ́-iṣẹ́ tẹlífísàn kan ní ilẹ̀ Àmẹ́ríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ the American Colombia Broadcasting Service (CBS), ní oṣù kéjìlá ọdún gbé ètò kan jáde lórí ìwá ìbajẹ́ tí ó pè ní ‘thirty minutes of corruption in Nigeria. Lẹ́yìn ètò yìí, ìjọbá àpapọ́ ní kí gbogbo àwọn ẹni tí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ náà kan kí wọn sì pè wọ́n lẹ́jọ́.

Iwe iroyin gbowo lori

àtúnṣe

Owó ìwé ìròyìn: Ní ọjọ́ kìíní oṣù kéjìlá ọdún 1963, owó ìwé ìròyìn kúrò ní kọ́bọ̀ mẹ́rin ó di kọ́bọ̀ márùn-ún.