Thérèse Sita-Bella (tí wọ́n bí ọdún 1933, tó sì kú ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2006), tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Thérèse Bella Mbida, jẹ́ olùdarí fíìmù ilẹ̀ Cameroon, tó padà di aṣagbátẹrù fíìmù ilẹ̀ Áfíríkà.

Fáìlì:Sitabella.png
Àwòrán Sita-Bella nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí awakọ̀ òfuurufú.
Thérèse Sita-Bella
Ọjọ́ìbíThérèse Bella Mbida
1933
Aláìsí27 February 2006
Yaoundé
Orílẹ̀-èdèCameroonian
Ọmọ orílẹ̀-èdèCameroonian
Iṣẹ́Film director

Ìgbésí ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí i sí ẹ̀yà Beti ní ìhà Gúúsù ilẹ̀ Cameroon, ó sì gba ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajíhìnrere ìjọ Catholic. Ní ọdún 1950 síwájú, lẹ́yìn tí ó gboyè ẹ̀kọ́ baccalaureate láti ilé-ìwé kan ní olú-ìlú Cameroon, ìyẹn Yaoundé, ó lọ sí Paris láti lè tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ìlú Faranse ni ìfẹ́ rẹ̀ sí ìròyìn kíkọ àti fíìmù ṣíṣe ti bẹ̀rẹ̀.

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ní ọdún 1955, Sita-Bella bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i akọ̀ròyìn.[1] Lẹ́yìn náà, ní 1963, Sita-Bella di obìnrin àkọ́kọ́ tí ó ṣe fíìmù ní Cameroon àti ní gbogbo ilẹ̀ Áfíríkà. [2] Láti ọdún 1964 wọ 1965, Sita-Bella ṣiṣẹ́ ní Faranse, ní ilé ìwé-ìròyìn La Vie Africane, tí òun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀. Lẹ́yìn tó padà sí orílẹ̀-èdè Cameroon ní ọdún 1967, ó dara pọ̀ mọ́ ẹ̀ka tó ń bójú tó ìròyìn, ó sì di igbákejì ọ̀gá ìròyìn. [1]

Tam Tam à Paris

àtúnṣe

Ní ọdún 1963, Sita-Bella ṣe olùdarí fíìmù Tam-Tam à Paris, tó tẹ̀lé ẹgbẹ́ kan láti Cameroon National Ensemble lásìkò ìrìn-àjò ti Paris.[2] Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn máa sọ pé Tam Tam à Paris jẹ́ fíìmù àkọ́kọ́ tí obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà ṣe.[3] Ní ọdún 1969, Tam Tam à Paris ṣàfihàn nínú ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ ti African Cinema, tó wá padà di FESPACO.[4]

Sita-Bella wà lára àwọn obìnrin tó ṣịṣẹ́ ní àwọn ilé-iṣẹ́ fíìmù tí ọkùnrin pọ̀.[5] Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ilé-iṣẹ́ fíìmù ti ọdún 1970, tó sì sọ pé:

Ikú rẹ̀

àtúnṣe

Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n ọdún 2006, Sita-Bella kú sí ilé-ìwòsàn kan ní Yaoundé látàri àìsàn jẹjẹrẹ.[6] Wọ́n sin ín sí ibi ìsìnkú Mvolye ní Yaoundé.[7]

Ìdálọ́lá

àtúnṣe

Wọ́n fi orúkọ rẹ̀ sọ gbọ̀ngàn fíìmù Sita Bella ní Cameroon Cultural Centre.[8]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Pouya, André Marie (September 1989). "Interview with Thérèse Sita-Bella". Amina 233. 
  2. 2.0 2.1 Tchouaffé, Olivier Jean (2012). "Women in Film in Cameroon: Thérèse Sita-Bella, Florence Ayisi, Oswalde Lewat and Josephine Ndagnou". Journal of African Cinemas 4 (2): 191–206. doi:10.1386/jac.4.2.191_1.  Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name "africancinemas" defined multiple times with different content
  3. "Recovering Lost African Film Classics". africa-in-motion.org.uk. Archived from the original on 17 October 2008. Retrieved 10 November 2016. 
  4. African Women and the Documentary: Storytelling, Visualizing History, from the Personal to the Political. https://muse.jhu.edu/article/634992. Retrieved 10 November 2016. 
  5. Tande, Dibussi. "Sita Bella: The Final Journey of a Renaissance Woman". dibussi.com. Retrieved 10 November 2016. 
  6. "Cameroon's first woman journalist dies". nation.com.pk. Archived from the original on 17 March 2008. Retrieved 10 November 2016. 
  7. Tande, Dibussi. "Sita Bella: The Final Journey of a Renaissance Woman". dibussi.com. Retrieved 10 November 2016. 
  8. Anchunda, Benly. "Cameroon Cultural Centre gets face lift". crtv.cm. Retrieved 24 November 2016.