Tick-borne encephalitis vaccine
Àjẹsára Igbọ́n amú ọpọlọ wújẹ́àjẹsára tí a ńlò láti dẹ́kun igbọ́n amú ọpọlọ wú(TBE), [1] Àrùn yíì wọ́pọ̀ ní Àarín àti Ìlà-Oorùn Úròpù, àti Àriwá Éṣíà. Ju ìdá 87% àwọn ènìyàn tí ó gba àjẹsára ni kòní ààrùn. [2] Ó wúlò nígbà tí igbọ́n tí ó ní ààrùn bágé ènìyàn jẹ. A máa ń fún ènìyàn nípa fífún ènìyàn ní abẹ́rẹ́ nínu iṣan. [1]
Àjọ Ìlera Àgbayé (AIA) gbaniníyànjú ìgba-abẹ́ẹ́rẹ́ fún gbogbo ènìyàn ní àwọn àgbègbè tí ààrùn yíì ti wọ́pọ̀. Láìjẹ́bẹ̀ àjẹsára yíì ni a gbaniyáǹjú fún àwọn tí ó wà léwu rẹ̀ gan an. Abẹ́ẹ́rẹ́ ìgbà mẹ́ta ni a gbaniyáǹjú ní èyí tí abẹ́ẹ́rẹ́ òmíìràn yóò tẹ̀le ní ọdún mẹ́ta-mẹ́ta sí márùn-márùn. Alèlo àjẹsára náà fún àwọn ènìyàn tí ó ju ọmọ ọdún kan sí mẹ́ta lọ ní èyí tí o ní fiṣe pẹ̀lú irúfẹ́.[1]
Ìlòdìsí rẹ̀ tí ó le kò wọ́pò. Ìlòdìsí rẹ̀ tí ó kéré ni a lèrí ìbà àti pípọ́n ohun ìrora níbi ojú abẹ́ré. Àwọn irúfẹ́ tí o tipẹ́ ni o somọ́ ìlòdìsí rẹ̀. Àjẹsára yíì kò léwu rárá lákókò oyún. [1]
Àjẹsára tí a ńlò lòdìsí TBE ni a ṣe jáde ní ọdún 1937.[1] O wà ní orí Ààtò Àwọn Òògùn tí ó Wúlò ti Àjọ Ìlera Àgbayé, ogùn tí a gbaniníyànjú jùlọ fún ètò ìléra tí ó wọ́pọ̀. Ní ẹyọ hóró iye rẹ̀ wà láàrin Pọ́ùn Òyìnbó 50 sí 70.[4] Kòsí àjẹsára yíì ní United States.[5]
Àwon ìlo oogùn
àtúnṣeIpá àjẹsára ni a ti sàkọsílẹ̀ rẹ̀ dáradára.[1] Àti ṣàwarí wí pé o máa ń dábòbò èkutelé lọ́wọ ìdojúkọ ìpànìyàn pẹ̀lú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìyàsọ́tọ̀ kòkòrò àkóràn TBE tí a ṣàkójọ rẹ̀ láàrin ọdún tí o lé ní ọgbọ̀n ní gbogbo Úròpù àti apákan Éṣíà tí Ìgbimò Sófíétì. Láfikún, ati ṣàfihàn rẹ̀ pé ìdábòbò-ara ti abẹ́rẹ́ àjẹsára ń ṣòkunfà lọ́dọ̀ àwọn olùfarajìn ènìyàn ni o ní ìyàsọ́tọ̀ ìporó tí a dánwò.
Ètò
àtúnṣeMéjì sí mẹ́ta ìlo oogùn ni a gbàníyánjù léyi tí ó dá lórí irúfẹ́. Lọ́nàkan, oṣù kan sí mẹ́ta gbọ́dọ̀ wáyé láàrín oogùn lílò àkọkọ́ ti oṣù máàrún sí méjìlá yóò tẹ̀le kí o tó lo oogùn tí ó kẹ́hìn. Oogùn lílò àfikún ni a gbàníyànjú ní oṣù mẹ́ta-mẹ́ta sí ọdún márùn ùn.[1]
Ìtàn
àtúnṣeÀjẹsára àkọ́kọ́ tí a ńlò lòdì sí TBE ni a ṣe jáde ní ọdún 1937 nínu ọpọlọ èkutélé. Ní ogún ọdún lẹ́hìn náà ni àjẹsára TBE tí a rí nínu àṣà sẹ́lì (ọ̀lẹ̀ inú sẹ́lì òròmọdìẹ) ni a gbékalẹ̀ tí a sì lò fún abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ó jáfáfá nínu ènìyàn ni Ìgbimò Sófíetì tẹ́lẹ̀. Lẹ́hìn náà, ìmọ́gaara, oogùn àjẹsára tí a koṣí ni a gbé jáde èyí tí ó ní agbára àti dára ju àjẹsára TBE tẹ́lẹ̀.