Titanic
RMS Titanic jẹ́ ọkọ ojú omi ńlá kan tí ó rì sí òkun North Atlantic ní ọjọ́ keedogun oṣù kẹrin(15 April) ọdún 1912 lẹ́yìn ìgbà tí ó kọlu òkúta omi dídì kan nígbà tí ó rìn ìrìn àjò láti Southampton, England sí New York City, Orílẹ̀ èdè America. Lára àwọn arin ìrìn àjò 2,224 tí ó wà nínú ọkọ̀ náà, ó lé ní 1,500 sọ ẹ̀mí wọn nù.