Tobi Makinde
Tóbi Mákindé (wọ́n bi lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù karùn-ún ọdún 1988) jẹ́ òṣèré àti olóòtú sinimá ọmọ Nigeria.[2] Ó di ìlúmọ̀ọ́nká nípa ipa tó kó nínú eré àgbéléwò tẹlifíṣọ̀n, Jenifa's Diary gẹ́gẹ́ bí 'Timini'. Òun àti Funke Akindele ni wọ́n dìjọ darí eré sinimá Nollywood tí wọ́n wò gan-an lórí ìtàkùn ayélujára tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ 'Battle on Buka Street, lọ́dún 2024, ó túnbọ̀ gbajúmọ̀ nínú ipa tí ó kó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn 'Shina Judah' tí ó jẹ́ jàǹdùkú nínú sinimá kan tó gbajúmọ̀ tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ A Tribe Called Judah.[3]
Tóbi Mákindé | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 16 Oṣù Kàrún 1988[1] Ìpínlẹ̀ Èkó, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Lagos |
Iṣẹ́ | Oṣèré |
Ìgbà iṣẹ́ | 1998–present |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ìkẹ́kọ̀ọ́
àtúnṣeWọ́n bí Tóbi lọ́jọ́ kẹrìndínlógún oṣù karùn-ún ọdún 1991 ní Ìpínlẹ̀ Èkó l'órílẹ̀-èdè Nigeria, ṣùgbọ́n ọmọ bíbí Iléṣà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun. Wọ́n bí i sí ẹbí Tọkọtaya Akinjìmí Olúfisáyọ̀ Mákindé. Ìlú Age-Mowo ní agbègbè Badagry, ní Ìpínlẹ̀ Èkó ló ti lo ìgbésí-ayé rẹ̀ ní kékeré. Ó kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ni Odofa Children Home, ní Àgbárá ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, bẹ́ẹ̀ ló lọ sí ilé-ìwé gíga Supreme Pillars College, ní Age-Mowo, Badagry, ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Lọ́dún 2012,ó kàwé gboyè Bachelor's degree nínú ìmọ̀ eré ìtàgé ni University of Lagos. Lọ́dún 2016, ó kàwé gboyè Master's Degree ní University of Lagos bákan náà.[4]
Àwọn ìtọkásí
àtúnṣe- ↑ https://dnbstories.com/2021/08/nollywood-actor-tobi-makinde-timini-full-biography.html
- ↑ Emmanuel, Solution (2023-01-23). "Tope Adebayo, Tijani Adebayo, Loukman Ali, Tobi Makinde are highest-earning Nollywood directors of 2022-FilmOne". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-10.
- ↑ Ajose, Kehinde (2024-02-03). "I had to behave like thug for A Tribe Called Judah role — Tobi Makinde". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-10.
- ↑ Idowu, Hannah (2021-08-17). "Full biography of Nollywood actor Tobi Makinde (Timini) and other facts about him". DNB Stories Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-02-10.