Tolu Odebiyi

Olóṣèlú

Tolulope Odebiyi (Tí a bí ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kọkànlá ọdún1963) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Naijiria tí Ó wá láti Ìpínlẹ̀ Ògùn.[1] Odebiyi ni wọn dìbò yàn sí ilé Ìgbìmọ̀ Aṣojú Àgbà láti jẹ́ aṣojú fún ìwọ oorun ti Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọdún 2019.[2] Ó ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gomina Ibikule Amosu ti Ìpínlẹ̀ Ògùn gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn òṣìṣẹ́.[3]

Tolu Odebiyi
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Tolu Odebiyi

14 Oṣù Kọkànlá 1963 (1963-11-14) (ọmọ ọdún 60)
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressives Congress
ResidenceIboro, Ìpínlẹ̀ Ògùn
EducationWenthworth Institute of Technology
(BS,) University of Massachusetts, Lowell Campus

Ọdebiyi kọ́ ẹ̀kọ́ jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìjọba ní Ibadan àti Institute of technology tí ó wà ní Boston ní Massachusetts[4]. Ní ọdún 2018, Ó kọ̀ sí ìmọ̀ràn tí gomina Amosu gba a pé kí Ó fi ẹgbẹ́ òṣèlú onigbale (([[All Progressive Congress]]) sílẹ̀ lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlú miran.[5] Ó so wípé òún gbọ́dọ̀ daabo bo ẹgbẹ́ òṣèlú òun.[6]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé, ètò-ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́

àtúnṣe

Ọdẹbiyi jẹ́ ọmọ bíbí inú kẹmi ati Jonathan Ọdẹbiyi.[7] Baba rẹ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ìgbìmọ̀ Aṣojú tẹ́lẹ̀.[8] iya rẹ si jẹ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ ti o nri si ètò ìdìbò ní orílẹ̀ èdè (Independent National Electoral Commission).[9] Ọdẹbiyi kọ́ ẹ̀kọ́ gboyè àkọ́kọ́ lórí ẹ̀kọ́ nípa ilé kíkọ́ àti nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ láti Wentworth Institute of Technology, Boston.

Ọdẹbiyi kọ́kọ́ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ ti All Saints primary school ní Ibadan kí ó tó di wípé Ó lọ gba ìwé ẹ̀rí onípele gíga ní ilé-ẹ̀kọ́ Ìjọba ní Ìbàdàn. Ó fi orílẹ̀ èdè Naijiria sílẹ̀ lọ sí ìlú Amerika láti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ rẹ̀.[10]

Lẹhinna, Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ajé rẹ lórí ojúlówó ohun ìní (Real Estate) kí ó to dí wípé Ó wá darapọ̀ mọ́ òṣèlú.[11]

Iṣẹ́ nípa ojúlówó ohun ìní

àtúnṣe

Lẹ́hìn ikẹkọ gba oyè rẹ, Ọdẹbiyi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nípa ojúlówó ohun ìní rékọjá lọ òkè òkun ní ìlú Amerika àti ní ilẹ̀ Naijiria.[12] kí ó tó di wípé wọ́n yan an si ipò òṣèlú, Ó ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùdarí ìṣàkóso ti Agbara Estate Limited.[13] Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ti Real Estate, Stururacasa Nigeria Limited, Travfirst Nigeria limited àti àwọn òmíràn.[14]

Iṣẹ́ olóṣèlú

àtúnṣe

Ọdẹbiyi jẹ́ ẹni tí ó dàgbà sínú òṣèlú. Baba rẹ, Jonathan Ọdẹbiyi ni olórí ọmọ ẹgbẹ́ tí ó kéré jùlọ ní ilé Ìgbìmọ̀ Aṣojú Àgbà nígbà ìjọba olómìnira kejì lórí pẹpẹ ẹgbẹ́ oníṣọ̀kan (Unity Party of Nigeria).[15] Ó ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi akọ̀we àgbà ní ọfiisi olórí àwọn òṣìṣẹ́ tí ó wà ní ọfiisi gomina ti Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọdún 2006 kí ó tó di wípé Ìjọba gomina Ibikunle Amosu wa yan an gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn òṣìṣẹ́.[16] Ní ọdún 2015, ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ kọ láti gbárùkù ti ìpinnu rẹ láti díje lọ sí ilé Ìgbìmọ̀ Aṣojú. Ó ti kọ́kọ́ pinnu láti díje gẹ́gẹ́ bi gómìnà fún Ìpínlẹ̀ Ògùn nínú ìdìbò ti ọdún 2019, ṣùgbọ́n Ó jáwọ́ ninu ìpinnu rẹ.[17] Ní ọdún 2018, Ọdẹbiyi kọ̀wé fi ipò rẹ sílẹ̀ bí olórí àwọn òṣìṣẹ́ láti díje lọ sí ilé Ìgb̀imọ̀ Aṣojú gẹ́gẹ́ bí aṣojú fún ìwọ oorun ti Ìpínlẹ̀ Ògùn.[18]

Ìgbésí ayé rẹ

àtúnṣe

Ọdẹbiyi jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Ibooro ní Ipinlẹ Ogun.[19]

Ìtàn ìdìbò

àtúnṣe

Nínú ìdìbò gbogboogbo tí o wáyé ní orílẹ̀ èdè Naijiria ní ọdún 2019, Ọdẹbiyi díje lọ sí ilé Ìgbìmọ̀ Aṣojú láti lọ ṣé aṣojú fún ìwọ oorun ti Ìpínlẹ̀ Ògùn lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú onigbalẹ ([[All Progressive Congress]]), ó sì borí ìbó yí.[20] Òhun ló ní ìbò tí ó pọ̀ julọ tí ó jẹ 58,452 ní àkàwé sí èsì ìbò àwọn oludije ti o sunmọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Allied People's Movement tí ó ní ìbò 48,611 àti ọmọ ẹgbẹ́ Alaburada (People's Democratic Party) tí ó ní ìbò 43,454.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Published (2015-12-15). "APC wins Ogun-West Senatorial District election". Punch Newspapers. Retrieved 2020-03-11. 
  2. "#NigeriaDecides2019 - APC's Odebiyi wins Ogun-West Senatorial District election". Tribune Online. 2019-02-26. Retrieved 2020-03-11. 
  3. "Breaking: Ogun Chief of Staff resigns". Vanguard News. 2018-11-30. Retrieved 2020-03-11. 
  4. sitedesigner (2018-09-05). "Chief Tolu Odebiyi Biography and Detailed Profile". Politicians Data. Retrieved 2020-03-12. 
  5. "Gov. Amosun, Tolu Odebiyi’s friction worsens". The Sun Nigeria. 2019-01-25. Retrieved 2020-03-12. 
  6. Nwachukwu, John Owen (2018-12-24). "2019 election: Why I ignored Gov. Amosun's instruction to dump APC for APM -Ex-Chief of Staff, Odebiyi". Daily Post Nigeria. Retrieved 2020-03-12. 
  7. sitedesigner (2018-09-05). "Chief Tolu Odebiyi Biography and Detailed Profile". Politicians Data. Retrieved 2020-03-12. 
  8. "Remembering Jonathan Odebiyi, great democrat and leader » Opinions » Tribune Online". Tribune Online. 2017-03-09. Retrieved 2020-03-12. 
  9. "Gov. AMOSUN's Chief Of Staff Set To Run". City People Magazine. 2017-09-17. Retrieved 2020-03-12. 
  10. sitedesigner (2018-09-05). "Chief Tolu Odebiyi Biography and Detailed Profile". Politicians Data. 
  11. "Odebiyi and the battle to succeed Amosun". Vanguard News. 2018-02-11. Retrieved 2020-03-12. 
  12. "Tolu Odebiyi Coasts To Senate". Startrend International Magazine. 2020-03-12. Retrieved 2020-03-12. 
  13. "Ogun 2019: Odebiyi, emergence of  son of the soil for governor’s seat". Nigerian News Direct. 2017-05-22. Archived from the original on 2019-03-19. Retrieved 2020-03-12. 
  14. "Odebiyi and the battle to succeed Amosun". Vanguard News. 2018-02-11. Retrieved 2020-03-12. 
  15. "Odebiyi and the battle to succeed Amosun". Vanguard News. 2018-02-11. Retrieved 2020-03-12. 
  16. "Amosun names new head of service, chief of staff – Punch Newspapers". Punch Newspapers – The most widely read newspaper in Nigeria. 2015-12-15. Retrieved 2020-03-12. 
  17. "TOLU ODEBIYI IS HEIR-APPARENT TO SUCCEED SENATOR IBIKUNLE AMOSUN AS GOVERNOR OF OGUN STATE IN 2019 – NEWSFLAGSHIP -". NEWSFLAGSHIP |. 2018-05-22. Archived from the original on 2020-05-19. Retrieved 2020-03-12. 
  18. Reporters, Tropic (2018-11-30). "Tolu Odebiyi resigns, appreciates Amosun for giving him privilege to serve". TROPIC REPORTERS. Retrieved 2020-03-12. 
  19. "Ogun 2019: Odebiyi, emergence of  son of the soil for governor’s seat". Nigerian News Direct. 2017-05-22. Archived from the original on 2019-03-19. Retrieved 2020-03-12. 
  20. Published (2015-12-15). "APC wins Ogun-West Senatorial District election". Punch Newspapers. Retrieved 2020-03-12.