Tomato bredie
Tomato bredie jẹ́ ọbẹ̀ jíjẹ ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà tí a mọ̀ sí "tamatiebredie" ní èdè Afrikaans tí ó sì túmọ̀ sí, ohun tí a fi ẹran àgùntàn sè. A máa ń gbé e ka iná fún ìgbà pípẹ́ pẹ̀lu àwọn èròjà bíi cinnamon, cardamom, ginger àti clove pẹ̀lú ata. "Bredie" túmọ̀ sí "ọbẹ̀" ní èdè Afrikaans, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ṣẹ̀ láti èdè Malaysia. Ọ̀nà ìdáná yìí jẹ́ èyí tí àwọn ará Malaysia mú wá sí Cape, sí àwọn tí wọ́n kó wá síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ẹrú. Ọ̀rọ̀ "bredie" túmọ̀ sí tòròmọ́gbè. Fún síse tomato bredie yìí, tòmátì ni wón máa fí ń rọ́pò rẹ̀. Pumpkin, green beans àti waterblommetjies (Cape water lily, Aponogeton distachyos, flowers) jẹ́ ara ohun tí a máa ń lò. Oúnjẹ ìbílẹ̀ Orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà yìí jẹ́ jíjẹ fún ará ilé àti àjò bákan náà.[1]
Type | Stew |
---|---|
Place of origin | South Africa |
Main ingredients | Mutton, cinnamon, cardamom, ginger, cloves, chilli |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
Bredies lápapọ̀ jẹ́ ọbẹ̀ ẹran àgùntàn, tí a sè pẹ̀lu ẹ̀fọ́. Ní àfikún sí tòmátì wọ́n tún lè lo cauliflower, lentils, parsnips, àti quince, tí wọ́n sì fi máa ń jẹ ìrẹsì.[2][3]
Tún wo
àtúnṣeÀwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Archived at GhostarchiveÀdàkọ:Cbignore and the Wayback MachineÀdàkọ:Cbignore: "TOMATO BREDIE". YouTube.Àdàkọ:Cbignore
- ↑ Davidson, Alan (2014). The Oxford companion to food. Tom Jaine, Soun Vannithone (3rd ed.). New York, NY. pp. 758. ISBN 978-0-19-967733-7. OCLC 890807357. https://www.worldcat.org/oclc/890807357.
- ↑ Jackman, Tony (October 20, 2023). "Throwback Thursday: Tomato bredie the Leipoldt way". Retrieved January 2, 2022.