Tomi Adeyemi
Tomi Adeyemi (tí wọ́n bí ní August 1, 1993) jẹ́ ònkọ̀wé àti olùkọ́ àkọsílẹ̀ àtinúdá ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tan mọ́ ilẹ̀ America. Ó gbajúmọ̀ fún ìwé ìtàn-àròsọ rẹ̀ Children of Blood and Bone, èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ìtàn Legacy of Orïsha trilogy, tí Henry Holt Books for Young Readers ṣá̀tẹ̀jáde rẹ̀.[1] Ìwé yìí gba àmì-ẹ̀yẹ ti Andre Norton ní ọdún 2018 fún Young Adult Science Fiction and Fantasy,[2] bákan náà ni ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti Waterstones Book Prize ọdún 2019, àti àmì-ẹ̀yẹ ti Hugo Lodestar Award for Best Young Adult Book, ní ọdún 2019.[3] Ní ọdún 2019, ìwé-ìròyìn Forbes kọ orúkọ rẹ̀ sínú àkójọ 30 Under 30. Ní ọdún 2020, ìwé-ìròyìn TIME náà to orúkọ rẹ̀ pọ̀ mọ́ 100 Most Influential People of 2020.[4]
Tomi Adeyemi | |
---|---|
Adeyemi in 2022 | |
Ọjọ́ ìbí | 1 Oṣù Kẹjọ 1993 |
Iṣẹ́ | Writer, Creative Director |
Alma mater | Harvard University |
Genre | |
Notable works | |
Notable awards |
|
Website | |
tomiadeyemi.com |
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Tomi Adeyemi ní August 1, 1993[5][6] ní United States sí àwọn òbí tó kó kúrò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bàmí rẹ̀ jẹ́ dọ́kítà ní Nàìjíríà, ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i awakọ̀ kí ó tó ríṣẹ́ lókè òkun. Ìyá rẹ̀ sì jẹ́ afọlẹ̀. Ìlú Chicago ni Tomi dàgbà sí, wọn ò sí mu mọ àṣà Yorùbá; àwọn òbí rè sì pinnu láti má kọ́ òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ ní èdè abínibí wọn. Àmọ́ ìgbà tó ṣẹ̀ dàgbà ló kọ́ èdè Yorùbá. Ó sì ṣàpèjúwe ọ̀kan lára àwọn ìwé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i lẹ́tà sí èdè rẹ̀[6]
Àwọn iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeLegacy of Orïsha trilogy
àtúnṣe- Children of Blood and Bone (March 6, 2018)
- Children of Virtue and Vengeance (December 3, 2019)
- Children of Anguish and Anarchy (June 25, 2024)
Companion books
- Awaken the Magic (journal) (April 7, 2020)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Nsubuga, Jimmy (April 15, 2017). "Writer lands seven figure deal for Black Lives Matter-inspired fantasy novel". Metro. http://metro.co.uk/2017/04/15/writer-lands-seven-figure-deal-for-black-lives-matter-inspired-fantasy-novel-6576793/.
- ↑ "2018 Nebula Awards". The Nebula Awards (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved May 19, 2019.
- ↑ "2019 Hugo Award & 1944 Retro Hugo Award Finalists". The Hugo Awards (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). April 2, 2019. Retrieved May 19, 2019.
- ↑ "Tomi Adeyemi: The 100 Most Influential People of 2020" (in en). Time. September 23, 2020. https://time.com/collection/100-most-influential-people-2020/5888211/tomi-adeyemi/. Retrieved June 25, 2021.
- ↑ Adeyemi, Tomi (August 1, 2018). "thank you all for making this the best birthday yet..." (in en). Twitter. https://twitter.com/tomi_adeyemi/status/1024699215690260480.
- ↑ 6.0 6.1 Kembrey, Melanie (March 9, 2018). "Interview: Tomi Adeyemi and her fantasy novel inspired by Black Lives Matter", The Sydney Morning Herald.