Toyin Lawani
Toyin Ajoke Muyinat Lawani-Adebayo, tí orúkọ gbajúgbajà rẹ̀ ń jẹ́ Toyin Lawani, jẹ́ gbajúgbajà ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sì jẹ́ aránṣọ, òǹkọ̀wé, onínúure, àti oníṣòwo rẹpẹtẹ. Òun ni olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Tiannahs Place Empire, èyí tó ní ìdókòwò mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) ìmíì lábẹ́ rẹ̀.[1] Yàtọ̀ sí èyí, òun ni oníṣẹ́ tó rí sí òkan-ò-jọ̀kan àwọn aṣọ tí wọ́n lò nínú fíimù àgbéléwò King of Boys: The Return of the King àti Shanty Town.
Tiannah's Empire, èyí tó jẹ́ ètò orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, jẹ́ èyí tó dá lórí ayé rẹ̀. EbonyLife Studio ló ṣagbátẹrù ètò yìí, òun ló sì rí sí ìtànkálẹ̀ rẹ̀.[2] Ó ṣàfihàn nínú ètò orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, The Real Housewives of Lagos tí wọ́n ṣàfihàn lórí Showmax ní ọdún 2022.[3][4]
Ìgbésí ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Toyin Lawani ní 1 March 1982.
Ó kọ́ ara rẹ̀ bí a ti ń ran aṣọ, ó sì gbajúmọ̀ fún àwọn sítàì àràmàǹdà tó máa ń gbé jáde. Lawani bọ̀ sí gbàgede lẹ́yìn tó ṣàfihàn àwọn aṣọ rẹ̀ ní Africa Fashion Week London in 2013.
Lẹ́yìn náà, ó tún ṣàfihàn àwọn aṣọ rè ní Africa Fashion Week Nigeria, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adájọ́ fún ètò orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Nigeria’s Next Top Designer. Òun náà ni ọ̀dọ́bìnrin tó jẹ́ aṣojú fún Fashion Designers Association of Nigeria (FADAN).
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ní pẹ̀lú Chude Jideonwo, Lawani sọ ọ́ di mímọ̀ pé ọ̀kan lára mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fi ipá bá a lò pọ̀ nígbà tí òun sì jẹ́ ọmọdún márùndínlógún (15).[5] Ní ọdún 2022, ó kéde rẹ̀ pé oyún kẹ́rin tí òun ní ti wálẹ̀.[6]
Àtòjọ àwon fíìmù rẹ̀
àtúnṣeÀwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
àtúnṣeỌdún | Amì-ẹ̀yẹ | Ìsọ̀rí | Èsì | Ìtọ́ka. |
---|---|---|---|---|
2020 | Nigerian Achievers Awards | Top 20 'Under 40' Entrepreneur/Game changer | Gbàá | [7] |
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Toyin Lawani: “My passion fuels me and my Kids inspire everything I do.”". Her Network (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 1 March 2022. Retrieved 29 June 2023.
- ↑ Izuzu, Chibumga (8 May 2017). "Toyin Lawani's reality series is surprisingly not the worst thing on TV". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 14 December 2022.
- ↑ 3.0 3.1 Augoye, Jayne (17 March 2022). "Real Housewives of Lagos cast unveiled". Premium Times (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 12 December 2022.
- ↑ 4.0 4.1 "Iyabo Ojo, Toyin Lawani, others debut as Real Housewives of Lagos". The Punch (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 19 March 2022. Retrieved 12 December 2022.
- ↑ Onikoyi, Ayo (12 August 2022). "I was raped by my uncle at 15 — Toyin Lawani". Vanguard. Retrieved 14 December 2022.
- ↑ "Celebrity stylist, Toyin Lawani, announces miscarriage". The Punch (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 9 August 2022. Retrieved 12 December 2022.
- ↑ "Achievers Awards for Fani Kayode, Toyin Lawani, others". The Sun. Retrieved 12 December 2022.