Toyin Saraki
Toyin Ojora-Saraki LLB, LLM, BL, tí a bí ní ọjọ kẹfa oṣù Kẹsán ọdun 1964 jẹ́ ajijagba eto ilera lagbaye, ẹlẹ́yinjú àánú lori ilera, oun si ni Ààrẹ ati Oludasilẹ àjọ ẹlẹ́yinjú àánú kan ni ilẹ Adúláwọ̀ tí wọ́n pè ní Wellbeing Foundation Africa. [1]
Toyin Saraki |
---|
Toyin Saraki | |
---|---|
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 6 Oṣù Kẹ̀sán 1964 Lagos, Nigeria |
Alma mater | SOAS, University of London Kings College, University of London |
Ibẹrẹ Igbe Aye ati Ẹkọ rẹ̀
àtúnṣeA bi Toyin Saraki ninu ẹbi awọn ọba Ọjọra àti Adele ni ilu Eko [Lagos], ni orilẹ-ede Naijiria, ó jẹ ọmọbinrin ọkan lara awọn ọtọkulu ọmọ Yoruba eyinni gbajumọ, Oloye Adekunle Ojora, tó jẹ́ Ọ̀túnba ti ilu Eko bakanna ló jẹ ọmọ-ọmọ fun Omoba Abdulaziz Ojora, ẹni tó jẹ Olórí Ọmọ-Ọba ilu Eko. Ni ile iya rẹ̀, oun ni ọmọbinrin Oodua, tó jẹ Iyaloye Ojuolape Ojora (ọmọ Akinfe), ati ọmọ-ọmọ Iyaloye Sabainah Akinkugbe, ẹniti oun tikararẹ je oloye lobinrin.[2] Awọn ẹbi Akinfẹ jẹ oloye pataki lati ipinle Ondo, orilẹ-ede Naijiria, olokoowo nla si ni won pẹlu.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Her Excellency Toyin Ojora Saraki appointed WHO Foundation Ambassador for Global Health". pmnch.who.int (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-03-07.
- ↑ "Toyin Ojora Saraki; A Life Devoted to Service". Konnect Africa. Retrieved 2013-09-13.