Uche Azikiwe
Uche Ewah Azikiwe tí a bí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kejì ọdún 1947 jẹ́ Ọ̀mọ̀wé ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, olùkọ́ àti òǹkòwé. Òun ni opó Nnamdi Azikiwe Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí. [1][2] Ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ti Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ tí ìmọ̀ Ìpìlẹ̀-ẹ̀kọ́ (the department of Educational Foundation, Faculty of Education), ní University of Nigeria, Nsukka. Lọ́dún 1999, wọ́n yàn án mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ adarí ilé ìfowópamọ́-àgbà (member, board of directors of Central Bank of Nigeria )
Uche Azikiwe | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Uche Ewah 4 Oṣù Kejì 1947 Afikpo, Ebonyi State |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Nigeria |
Olólùfẹ́ | Nnamdi Azikiwe (1973–1996, his death) |
Àwọn ọmọ | 2 |
Ìgbésí ayé àti ètò-èkó rẹ̀
àtúnṣeA bí i ní ọjọ́ kẹrin oṣù kejì ọdún 1947 ni ìlú Afikpo ní ìpínlẹ̀ Ebonyi. A bí i sínú ìdílé Sergeant Major Lawrence A. àti Florence Ewah.
Ó gboyè Bachelor of Arts nínú English ní University of Nigeria, Nsukka (UNN) kí ó tó tẹ̀ síwájú láti gba ìwé-ẹ̀rí Masters nínú Curriculum Studies and Sociology of Education. Ní ọdún 1992, ó gboyè Ph.D. ninu Sociology of Education/Gender Studies ní Fásitì kan náà.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ My Concern: Reflections of a Sensitive Mind. Dorrance Publishing. p. 10. ISBN 1434926133. https://books.google.com/books?id=nklElrKYz2MC. Retrieved 17 September 2015.
- ↑ Christopher Isiguzo (17 May 2015). "Azikiwe's Widow Laments Breakdown of Security in Enugu". Thisday (Enugu). Archived from the original on 23 July 2015. https://web.archive.org/web/20150723100344/http://www.thisdaylive.com/articles/azikiwes-widow-laments-breakdown-of-security-in-enugu/209564/. Retrieved 17 September 2015.
- ↑ Ozor, Chineye (4 October 2011). "Zik’s dream yet to be achieved, 51 years after- Mrs Azikiwe". Vanguard. http://www.vanguardngr.com/2011/10/zik%E2%80%99s-dream-yet-to-be-achieved-51-years-after-mrs-azikiwe/. Retrieved 17 September 2015.