Ugali ní Ghana
Sagtulga (Dagbani: saɣituliga, Hausa:tuo zaafi), tàbí diehuo, jẹ́ oúnjẹ tí ó gbajúgbajà láàrin àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè Ghana. Sagtulga jẹ́ oúnjẹ tí ó ṣe gbòógì tí wọ́n máa ń jẹ pẹ̀lú onírúurú ọbẹ̀ bíi ilá. Ó jẹ́ oúnje tí ó gbajúmọ̀ jù ní apá àríwá orílẹ̀-èdè náà: Northern, Upper East, àti Upper West. Wọ́n sáábà máa ń jẹ oúnjẹ yìí gẹ́gẹ́ bíi oúnjẹ alẹ́, síbẹ̀ (àwọn ènìyàn bíi àgbẹ̀ àti oníṣẹ́ ọwọ́) máa ń jẹ ẹ́ gẹ́gẹ́ bíi oúnjẹ òwúrọ̀ tàbí ti ọ̀sán. Wọ́n sáábà máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú ewédú (Dagbani: salinvogu, Hausa: ayoyo, molokai)[1] àti ilá (Abelmoschus esculentus) Àdàkọ:CN pẹ̀lú ọbẹ̀ ata ní ẹ̀gbẹ́ kan.
Oúnjẹ yìí kún fún àgbàdo sísè àti ẹ̀gẹ́ gbígbẹ díẹ̀ pẹ̀lú omi láì sí iyọ̀ nínú rẹ̀. [2] Ní ti ìbílẹ̀, a máa ń se é pẹ̀lú jéró,[3] èyí tí ó jẹ́ ìbílẹ̀ sí àwọn apá àríwá orílẹ̀-èdè Ghana.[4]
Wọ́n sáábà máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú ọbẹ̀ ẹ̀fọ́ èyí tí a ṣe láti ara ẹ̀fọ́ ewúro, tàbí nígbà mìíràn pẹ̀lú ewé ẹ̀gẹ́ tútù tí a gún. A le jẹ ẹ́ pẹ̀lú onírúurú ọbẹ̀, bíi ilá àti ọbẹ̀ ẹ̀pà.
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Corchorus olitorius Jew's Mallow, Nalta jute PFAF Plant Database".
- ↑ "Ayoyo soup and tuo zaafi". infoboxdaily.com. Archived from the original on 2015-05-27. Retrieved 2015-05-27. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Webb, L.S. (2000). Multicultural Cookbook of Life-Cycle Celebrations. Cookbooks for Students Series. Oryx Press. p. 64. ISBN 978-1-57356-290-4. https://archive.org/details/multiculturalcoo00lois. Retrieved October 2, 2018.
- ↑ "An Introduction to Northern Ghana's Super Foods Shea, Millet & Fonio | Circumspecte" (in en-US). Circumspecte. 2016-07-25. https://circumspecte.com/2016/07/an-introduction-to-northern-ghanas-super-foods-shea-millet-fonio/.