Ìlú Ùgbò jẹ́ ìlú ní ìjọba ìbílè Ìlàjẹ ní Ìpìnlẹ̀ Oǹdó, gúúsù-Iwọ̀-Oòrùn Nàìjíríà. Àwọn apẹja ló pọ̀ jù lára àwọn ará Ìjọba Ùgbò. [1] 

Ìṣàkóso

àtúnṣe

Ìjọba Ùgbò ní àwọn ìdámẹ́rin mẹ́rìndínlógún ó sì ní olórí nípasẹ̀ àwọn olóyè tí a yàn gẹ́gẹ́ bíi àṣà àti ìṣe wọn. Ọkàn lára àwọn olórí ilé ẹgbẹ́ náà tí wọn ń pè ní Olóyè Gbógunró ló ń gbé èwe oyé náà sórí Ọba tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn lọ́jọ́ ìjoyè.

Geography

àtúnṣe

Ilẹ̀ Ùgbò wà ní etí i òkun àti Gúúsù-Iwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Ládùúgbò àwọn ọmọ Ugbo ni awon Ikales, Itshekiris, Ijaws, Apois, Ijebus, and Edos. Ìlú Ùgbò wà ní etí òkun ti ẹkún Iwọ̀-òórùn Gúúsù ti Nàìjíríà ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó lọ́wọ́lọ́wọ́. Gbogbo agbègbè náà ni àwọn àmì-ilẹ̀ etí òkun, àwọn ṣiṣan, àwọn odò àti àwọn adágún omi. Ó wà láàárín agbègbè ìwọ-oòrùn ti Niger Delta bẹ̀rẹ̀ láti Bight of Benin ní Ìlà-oòrùn, àti gbogbo ọ̀nà láti Oghoye nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ṣiṣan ilẹ̀ Ùgbò sí Abetobo.

Ilẹ̀ Ùgbò wà lórí gíga tí ó wà láàárín àwọn mítà 1.0 ati 1.5 lókè ìpele òkun. Ó wà ní gbangba bí kò ṣe sí òkè kankan ní àyíká.

  1. Ault, Jerald S. (October 2007). Biology and Management of the World Tarpon and Bonefish Fisheries. ISBN 9781420004250. https://books.google.com/books?id=hM3ycC-vtugC&q=Ilaje+people+are+fishermen&pg=PA117.