Ukazi soup
Ukazi soup jẹ́ ọ̀bẹ̀ Igbo tó sì súnmọ́ sí ọ̀bẹ̀ Afang ti àwọn ẹ̀yà Efik; ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọ̀bẹ̀ méjèèjì ni pé ọ̀bẹ̀ okazi nípon ju ọ̀bẹ̀ Afang lọ yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ oúnjẹ pàtàkì sí agbo ilé kọ̀ọ̀kan.[1] Lára ewé méjì pàtàkì ni ọ̀bẹ̀ yìí ti wáyé, àwọn ni : okazi àti Gúre.[2]
Àwọn èròjà tí a fi ń se ọ̀bẹ̀ náà ni epo, egusi (mgbam), edé àti ohun èlò ìsebẹ̀. A lè fi ọ̀bẹ̀ jẹ òkèlè bíi ẹ̀bà, sẹ̀mó, àti iyán.[3]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "How To Make Okazi Soup". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-04-04. Archived from the original on 25 June 2022. Retrieved 2022-06-25.
- ↑ onnaedo (2015-10-29). "How to make okazi soup". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-06-25.
- ↑ "Okazi soup from Nigerian dishes". ResearchGate. https://www.researchgate.net/publication/355944811.