Umqombothi

Ohun mímu tí wọ́n fi àgbàdo àti ọkà bàbà ṣe

Umqombothi jẹ́ ọtí ìbílẹ̀ ilẹ̀ South Africa tí a ṣe láti ara àgbàdo, malt, sorghum, yeast àti omi. Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ vitamin B. Ọtí náà kò ní ọtí púpọ̀ nínú (sábàá máa ń kéré sí ìdá 3%) ó sì jẹ́ mímọ̀ pé ó ní òórùn kíkan tí ó le tí ó sì dá yàtọ̀. Ní ìrísí, ọtí náà fúyẹ́. Ó ní ìrísí líle àti yíyọ̀ láti ara àgbàdo náà.[1]

Umqombothi kò wọ́n tó àwọn ọtí tí wọ́n ṣe láti ara barley àti adùn pẹ̀lú òdòdó hop.

Umqombothi served in an ukhamba, Zulu beer vessel at Cape Town, South Africa.

Ọ̀nà ṣíṣè ti ìbílẹ̀

àtúnṣe

Umqombothi máa ń di ṣíṣe nípa títẹ̀lé ìṣe ìbílẹ̀, èyí sì yàtọ̀ díẹ̀ díẹ̀ láàárín àwọn agbègbè. Ohun èlò máa ń di fífi sílẹ̀ láti ọwọ́ ìran kan sí òmíràn. Ọtí náà máa ń di ṣíṣe ní ìbílẹ̀ lórí iná ní ìta ilé. Lẹ́yìn náà ni yóò wá tutù láti lè jẹ́ kí gbígbóná rẹ̀ tutù ní ìta ilé.[2]

Àwọn èròjà tí a lò ni: ìwọ̀n déédéé àgbàdo, ọkà bàbà gígún, àti jéró gígún. Àgbàdo náà máa ń pèsè ọtí díẹ̀ pẹ̀lú adùn. Jéró máa ń pèsè ọtí dúdú.

Àwọn èròjà náà máa ń di pípò papọ̀ nínú ìkòkò, tí a mọ̀ sí potjie ní South Africa. Òdiwọ̀n omi tó lọ́wọ́rọ́ mẹ́rin máa di fífi kún un. Àpòpọ̀ yìí máa di fífi sílẹ̀ mọ́jú. Àpòpọ̀ yìí máa bẹ̀rẹ̀ sí ní wú, bọ́bù á sì jáde. Òórùn kíkan lè di mímọ̀.

Díẹ̀ nínú rẹ̀ máa di yíyọ yóò sì di fífi sí ẹ̀gbẹ́ kan. Ìyókù máa di ṣíṣè títí yóò fi jinná. Ọjà yìí ni a mọ̀ sí isidudu ó sì lè di jíjẹ gẹ́gẹ́ bí àsáró. Nígbà tí a bá ń ṣe ọtí, isidudu máa ń di fífi sílẹ̀ fún ọjọ́ kan láti tutù.[3]

Lẹ́yìn tí pípò papọ̀ náà bá ti tutù, yóò di dídà sínú ike ńlá kan. Èyí tí ó jẹ́ yíyọ kúrò yóò di fífi kún ti inú ike náà. Jéró àti àgbàdo yóò di fífi kún ti inú ike náà. Yóò sì di rírò pẹ̀lú síbí ìbílẹ̀ tí à ń pè ní iphini. Ike náà yóò di bíbò pẹ̀lú ìdérí láti lè jẹ́ kí ooru mú un. Ike náà yóò di gbígbé síbi tí ó lọ́wọ́rọ́ mọ́jú láti lè jẹ́ kí ó toró.

Láti mọ̀ bóyá ọtí náà ti setán, ọ̀nà ìdánwò ti ìbílẹ̀ ni láti sá iná nítòsí ike náà. Tí iná náà bá tètè kú, ọtí náà ti setán. Tí iná náà bá sì wà ní títàn, ọtí náà kò tíì ṣetán. Èyí jẹ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé títoró náà ṣe àgbéjáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ carbon dioxide, èyí tí kò fi ààyè gba kíkú iná náà.

Nígbà tí ọtí náà bá ti delẹ̀, èyí tí ó ti toró náà yóò di ṣíṣẹ́ nípa lílo asẹ́ onírin ńlá láti yọ hóró kúrò. Èérún tí ó wà ní ìdí ike náà ni a mọ̀ sí intshela. Intshela náà máa di fífi kún ọtí náà láti fi kún adùn rẹ̀.

Èrúnrún náà máa di fífún kúrò, ó sì sábàá máa ń di dídà sílẹ̀ fún àwọn adìẹ. Olùṣe ọtí náà yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn bàbáńlá nígbà tí ó bá ń tan èrúnrún náà ká.

Lẹ́yìn tí ọtí náà bá ti di ṣíṣe tán, yóò di dídà sínú àmù ńlá kan tí a mọ̀ sí gogogo. Ó ti lè di pínpín pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí. Nígbà tí àwọn àlejò bá dé sí ilé olùṣe ọtí láti tọ́ ọtí náà wò àti láti darapọ̀ mọ́ ayẹyẹ, wọn yóò gbé ìgò burandí brandy kan lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì ìdúpẹ́.

Ìlò ìbílẹ̀ == Umqombothi máa ń di lílò láti ṣe ayẹyẹ ìpadawálé ọ̀dọ́mọkùnrin, tí a mọ̀ sí abakwetha ní àṣà Xhosa, lẹ́yìnulwaluko - ìgbàwọlé àti religious male circumcision.

Ọtí yìí kó ipa pàtàkì nígbà tí ènìyàn bá ń pe bàbáńlá wọn, amadlozi, ó sì máa ń kó ipa ribiribi ní àwùjọ, ó sì sábàá máa ń di lílò níbi ìgbéyàwó, òkú ṣíṣe àti imbizos (ìpàdé ìbílẹ̀).[4]

Àkíyèsí ìlera

àtúnṣe

Ìwádìí kan[5] ṣàwárí pé jéró àti àgbàdo tí a lò gẹ́gẹ́ bí èròjà ní umqombothi sábàá máa ń ní ààrùn mycotoxin- tí ó ń ṣe àgbéjáde ewú Aspergillus spp., Penicillium spp., Rhizopus spp. àti Mucor spp.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí tí wọ́n ti parí náà kò ní ààrùn fungi, ìdá 33% ti ọtí tí wọ́n fi jéró ṣe ni ó ní aflatoxins àti ìdá 45% ọtí tí wọ́n ṣe nílé ni ó ní zearalenone tàbí ochratoxin A (tàbí méjèèjì) nínú ọjà ìkẹyìn.

Ẹkùn Eastern Cape ti South Africa ní ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ga ti esophageal cancer.[6] Ìwádìí láti ọ̀dọ̀ South African Medical Research Council dábàá mycotoxins ní àgbàdo gbíngbìn máa ń di síso pọ̀ mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ààrùn jẹjẹrẹ tí ó wọ́pọ̀.

Nínú àṣà tó gbajúgbajà

àtúnṣe

Wọ́n ń pè é ní song of the same nameYvonne Chaka Chaka kọ. Kíkọ orin náà pè é ní "idán African beer." Orin náà di gbígbọ́ níbi ayẹyẹ ṣíṣí ilé ìtura ti Hotel Rwanda.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Murray, Slater. "Umqombothi: Africas original beer". Beerhouse. Beerhouse. Archived from the original on 2 June 2016. Retrieved 7 April 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. Odhav, B.; Naicker, V. (2002). "Mycotoxins in South African traditionally brewed beers". Food Additives and Contaminants 19 (1): 55–61. doi:10.1080/02652030110053426. PMID 11811766. 
  3. "@Livewire - Throat Cancer". Archived from the original on 2015-12-22. Retrieved 2007-10-31.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Murray, Slater. "Umqombothi: Africas original beer". Beerhouse. Beerhouse. Archived from the original on 2 June 2016. Retrieved 7 April 2016.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. Odhav, B.; Naicker, V. (2002). "Mycotoxins in South African traditionally brewed beers". Food Additives and Contaminants 19 (1): 55–61. doi:10.1080/02652030110053426. PMID 11811766. 
  6. "@Livewire - Throat Cancer". Archived from the original on 2015-12-22. Retrieved 2007-10-31.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)