Uzoamaka Aniunoh
Uzoamaka Doris Aniunoh jẹ́ ònkọ̀wé àti òṣèré ará ìlu Nàìjíríà. Ó ti di òdú tí kìń ṣe àìmọ̀ fólóko nínu eré MTV Shuga léyìn tí ó ti hàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà eré tẹlifíṣọ́nù náà tó fi mọ́ àkọ́kọ́ àti ẹ̀kẹfà.
Uzoamaka Aniunoh | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Onitsha |
Orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Ẹ̀kọ́ | Yunifasiti Naijiria, Yunifasiti Birmingham |
Iṣẹ́ | osere |
Ìgbé ayé rẹ̀
àtúnṣeAniunoh ni a bí ní Onitsha. Ó kẹ́ẹ̀kọ́ Yunifásitì ti Nàìjíríà, ní ílu Nsukka. Ní ọdún 2015, ó lọ sí UK níbití ó ti kẹ́ẹ̀kọ́ Ìwé kíkọ nì Yunifásitì Birmingham tí ó sì gba oyè gíga.[1]
Eré ṣíṣe rẹ̀
àtúnṣeÓ padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 2017, ó sì lọ sí àwọn àyẹ̀wò tí ó ṣí sílẹ̀ fún ti eré alátìgbà-dègbà tuntun tí a pè ní MTV Shuga. Ó ṣe kòńgé láti wà lára àwọn tí wọ́n yàn, ó sì kópa Cynthia. Ó ti gba ìmọ̀ràn tẹ́lẹ̀ rí láti ẹnu Níyì Akinmolayan ní im̀uŕasílẹ̀ fún àyẹ̀wò naa. Irú ìmọ̀ràn yí kan náa ̀ni ó ṣé ní ànfàní láti rí ipa nínu Rumor Has It tí NdaniTV.
Ó ti jẹ́ olùkópa àṣíwájú nínu fiimu “Stuck” pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Ṣeun Àjàyí àti Lala Akindoju.[2]
Ẹ̀yà kẹfà tí MTV Shuga padà wá sí Nàìjíríà lẹ́ẹ̀kansi, wọ́n sì tún pe Aniunoh láti kópa gẹ́gẹ́ bi Cynthia lẹ́ẹ̀kansi níbi ẹ̀yà ti ọdún náà tí a pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Choices".[3] Àwọn olùjọkópa rẹ̀ ni Timini Egbuson, Rahama Sadau, Yakubu Mohammed, Bukola Oladipupo, Helena Nelson àti Ruby Akabueze.[4]
Ìwé kíkọ
àtúnṣeAniunoh tún jẹ́ ònkọ̀wé ó sì ti ní iṣẹ́ tó ti jẹ́ títẹ̀jáde. Ònkọ̀wé ará ìlu Nàìjíríà kan, Chimamanda Ngozi Adichie, sì tún ti ṣe àtúnkọ àti àtẹ̀jáde ìyọ nínu iṣẹ́ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ n jẹ́ "Balcony".[1]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "UZOAMAKA ANIUNOH CHATS WITH GLANCE NG.". Glance Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-05-30. Archived from the original on 2020-10-28. Retrieved 2020-05-13.
- ↑ Tv, Bn (2019-01-23). "Ozioma Ogbaji’s Short Film "Stuck" starring Seun Ajayi, Lala Akindoju & Uzoamaka Aniunoh is a Must Watch | BN TV". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-13.
- ↑ Chikwendu, Margaret (2019-10-23). "Award Winning TV Drama, MTV Shuga Naija Returns To TV Screens Today!". BHM (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-13.
- ↑ Kehinde, Opeyemi; Lagos (2019-10-19). "MTV Shuga Naija returns with ‘Choices’ this October". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-05-03. Retrieved 2020-05-13.