Adebayor Zakari Adje (ti a bi ni ọjọ kejila Oṣu kọkanla ọdun 1996) jẹ agbabọọlu ọmọ orilẹ-ede Niger ti o gba fun ẹgbẹ agbabọọlu Niger Premier League USGN, ti o wa la'win lati ọdọ Danish 1st Division club HB Køge .

Ni ọdun 2016, Adebayor ni awọn idanwo pẹlu awọn ẹgbẹ kan ni Ligue 1 FC Lorient ati AS Monaco ṣugbọn won ko funni ni adehun ni ẹgbẹ mejeeji. [1] [2]

Ni ọjọ kakandinlogbon Oṣu Kẹjọ 2018, Vejle Boldklub ni Denmark kede iforukọsilẹ ti Adebayor lati Inter Allies lori adehun awin titi di ọjọ ogbon ni osu Okudu 2019. [3] Sibẹsibẹ, lẹhin oṣu kan, ẹgbẹ naa kede pe wọn fẹ lati fopin si adehun awin naa nitori Adebayor ko wa ibi igbaboolu lehin ti wọn ti ṣe adehun ati wipe ẹgbẹ naa ko ni anfani lati kan si agbabọọlu naa. [4]

Sibẹsibẹ, o pada si orilẹ-ede Denmark ni Oṣu Kẹwa Ọdun 2020, nigbati o fowo si iwe adehun pẹlu Danish 1st Division club HB Køge, eyiti o jẹ egbẹ bọọlu afẹsẹgba Danish ti o wa ni ilu Herfølge, ati eekeji ni ilu Køge, mejeeji ni Agbegbe Køge . [5] Bibẹẹkọ, ni ọjọ 4 Oṣu Kẹta ni odun 2021, ẹgbẹ naa jẹrisi, pe Adebayor ti lo lawin si Legon Cities, nitori o fẹ lati sunmọ idile rẹ nitori awọn idi ti ara ẹni. [6] Ni ọjọ 10 Oṣu Kẹsan ọdun 2021, Adebayor gba si adehun alawin ọdun kan pẹlu ENPPI SC ti orilẹ-ede Egypt.

Ise okeere àtúnṣe

O jẹ agbaboolu giga julọ ni Niger pẹlu ami ayo mejidinlogun ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtalelogoji. [7]

Awọn iṣiro iṣẹ àtúnṣe

International àtúnṣe

Rara. Ọjọ Ibi isere Alatako O wole Abajade Idije
1. Oṣu Kẹta ọjọ 18, Ọdun 2016 Stade Régional Nyamirambo, Kigali, Rwanda </img> Nigeria 1–2 1–4 2016 African Nations asiwaju
2. Oṣu Kẹta Ọjọ 29, Ọdun 2016 Stade Général-Seyni-Kountché, Niamey, Niger </img> Senegal 1–2 1–2 2017 Africa Cup of Nations afijẹẹri
3. 5 Kẹsán 2017 Stade Adrar, Agadir, Morocco </img> Mauritania 2-0 2–0 Ore
4. 27 Oṣu Karun ọdun 2018 Stade Général Seyni Kountché, Niamey, Niger </img> Central African Republic 3–2 3–3 Ore
5. Oṣu Kẹfa Ọjọ 2, Ọdun 2018 Stade Général-Seyni-Kountché, Niamey, Niger </img> Uganda 1-0 2–1 Ore
6. 2-0
7. Oṣu kọkanla ọjọ 18, ọdun 2018 Mavuso Sports Center, Manzini, Eswatini </img> Eswatini 1–1 2–1 2019 Africa Cup of Nations afijẹẹri
8. 2-0
9. Oṣu Kẹta Ọjọ 20, Ọdun 2020 Stade Général-Seyni-Kountché, Niamey, Niger </img> Chad 1-0 2–0 Ore
10. Oṣu Kẹfa Ọjọ 11, Ọdun 2021 Arslan Zeki Demirci Sports Complex, Manavgat, Turkey </img> Guinea 1-0 2–0 Ore
11. Oṣu Kẹsan 6, ọdun 2021 Prince Moulay Abdellah Stadium, Rabat, Morocco </img> Djibouti 1–1 4–2 2022 FIFA World Cup jùlọ
12. 2 –1
13. Oṣu kọkanla ọjọ 15, ọdun 2021 Stade Général Seyni Kountché, Niamey, Niger </img> Djibouti 1-0 7–2 2022 FIFA World Cup jùlọ
14. 2 –1
15. 5-1
16. Oṣu Kẹta Ọjọ 23, Ọdun 2022 Stade Cheikha Ould Boïdiya, Nouakchott, Mauritania </img> Mozambique 1-0 1–1 Ore
17. Oṣu Kẹta Ọjọ 26, Ọdun 2022 Stade Cheikha Ould Boïdiya, Nouakchott, Mauritania </img> Libya 1–2 1–2 Ore

Ita ìjápọ àtúnṣe

Awọn itọkasi àtúnṣe

  1. "Monaco: Victorien Adebayor, une pépite nigérienne à l'essai" (in fr-FR). Africa Top Sports. 2016-05-13. http://www.africatopsports.com/2016/05/13/victorien-adebayor-petite-perle-nigerienne-a-lessai-a-monaco/. 
  2. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2016-08-15. Retrieved 2022-06-14. 
  3. 21-årig afrikansk angriber på plads i VB Archived 2021-06-07 at the Wayback Machine., vejle-boldklub.dk, 28 August 2018
  4. Vejle vil ophæve kontrakt med forsvundet spiller, tipsbladet.dk, 26 September 2018
  5. Rekordkøb: HB Køge henter Adebayor, hbkoge.dk, 4 October 2020
  6. HB Køge udlejer Adebayor til Legon Cities FC, hbkoge.dk, 4 March 2021
  7. "AFCON Qualification: Ethiopia 3-3 Algeria" (in en). Al Bawaba. 2016-03-30. http://www.albawaba.com/sport/afcon-qualification-ethiopia-3-3-algeria-823230.