Volta Regional Museum jẹ́ musíọ́mù kan tí ó wà ní Ho, orílẹ̀ èdè Ghana. Musíọ́mù náà wà fún ìgbé lárugẹ ìtàn àti àsà agbègbè Volta.[1] Musíọ́mù náà wà lábẹ́ ìdarí Ghana Museums and Monuments Board.

Volta Regional Museum
Fáìlì:File:Drums in the volta region musueum.jpg
Lua error in Module:Location_map at line 382: No value was provided for longitude.
Building
Location43 Glala Road, P. O. Box 43, Ho, Ghana
Coordinates6°36′31″N 0°28′08″E / 6.608611°N 0.468889°E / 6.608611; 0.468889Coordinates: 6°36′31″N 0°28′08″E / 6.608611°N 0.468889°E / 6.608611; 0.468889

Kí wọ́n tó lò ó fún musíọ́mù, wọ́n ń lò fún ọ́fícì àwọn olóyè agbègbè ibẹ̀.[2] Wọ́n ta ilé náà fún ìjọba ní ọdún 1967 wọ́n sì ṣí musíọ́mù náà ní ọdún 1973. Ní oṣù kẹrin ọdún 2014, musíọ́mù náà so wọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé ìwé Evangelical Presbyterian University College ṣe ayẹyẹ àwọn tí ó kọ́ nípa èdè Ewe.[3] Ní ọdún 2018, aṣojú orílẹ̀ èdè Germany sí Ghana, Christoph Retzlaff, ṣe àbẹ̀wò sí musíọ́mù náà, ó sì sọ nípa ète rẹ̀ láti tún agbègbè Volta ṣe.[4] Ní ọdún 2021, wọ́n parí àtúnṣe tí wọ́n ń ṣe síbẹ̀, ìjọba Germany àti Ghana ni ó parapọ̀ pèsè owó tí wọ́n fi tún ṣe. Ìjọba Germany gbé 25000 euros kalẹ̀, àjọ Ghana Museums and Monuments Board sì gbé 200000 Ghanaian cedi kalẹ̀.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Lamptey, P. S. N. O. (2022-04-01). "Museums and Skeletons: prospects and challenges of cataloguing, storing and preserving human remains in the Museum of Archaeology, Ghana" (in en). Ethics, Medicine and Public Health 21: 100753. doi:10.1016/j.jemep.2022.100753. ISSN 2352-5525. https://www.sciencedirect.com/science/article/pii/S2352552522000020. 
  2. "Letsa commits to completing stalled projects". Modern Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-23. 
  3. "EP university honours contributors to Ewe language". Graphic Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-23. 
  4. "Volta Regional Museum To See Facelift". Modern Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-05-23. 
  5. Simpson, Tony. "Refurbished Volta Regional Museum re-opens". Ghana News Agency (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-05-31. Retrieved 2022-03-08.