Wálé Adébáyọ̀
Wálé Adébáyọ̀ jẹ́ òṣèrékùrin, adarí eré àti olùgbéré-jáde tí wọ́n bí ní ìlú Abẹ́òkúta ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ qá láti Ìpínlẹ̀ Òndó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1]
Ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWálé lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé-ẹ̀kọ́ girama ti "Satellite Town" ní Ìpínlẹ̀ Èkó níbi tí ó dàgba sí. Ó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ òfin ní ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ .
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeWálé di ìlú-mòọ́ká látàrí ipa rẹ̀ tí ó kó nínú eré Ṣàngó gẹ́gẹ́ bí olú ẹ̀dá-ìtàn. Ó ti gbé awọn eré ọlọ́kan-ò-jòkan eré bíi Makabba ati Double Game, The Legendary African King àti Figuring . Ó sì tún ti darí eré onípele àtìgbà-dégbà bí Binta and Friends ati Papa Ajasco and Company lábẹ́ ilé-iṣẹ́ Walé Adénúgà.[2]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "PROFESSIONAL ACTORS DON'T REJECT ROLES-----WALE ADEBAYO". Modern Ghana. 2009-02-25. Retrieved 2020-11-25.
- ↑ "- Actor Director profile on Nollywood Boulevard.". Nollywood Boulevard. Retrieved 2020-11-25.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]