Wunmi Mosaku

(Àtúnjúwe láti Wùnmí Mosákú)

Wunmi Mosaku (bíi ni ọdún 1986) jẹ́ òṣèré àti olórin ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [2]Ó gbajúmọ̀ fún ipa Joy tí ó kó nínú eré Moses Jones (2009) àti Holly Lawson nínú eré Vera(2011). Ó gba àmì ẹ̀yẹ Best Supporting Actress láti ọ̀dọ̀ BAFTA TV Award fún ipa Gloria Taylor tí ó kó nínú eré Damilola, Our Loved Boy ni ọdún 2016. Ní ọdún 2019, ó kópa nínú ipá karùn-ún tí fíìmù Luther.[3]

Wunmi Mosaku
Mosaku at The Old Vic, 2010
Ọjọ́ìbíOluwunmi Mosaku
1986 (ọmọ ọdún 37–38)[1]
Nigeria
Iléẹ̀kọ́ gígaRoyal Academy of Dramatic Art (2007)
Iṣẹ́
  • Actress
  • singer
Ìgbà iṣẹ́2006–present

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Mosaku sì orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àmọ́ wọ́n gbe lọ sí ìlú Manchester ni orílẹ̀ èdè England. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Trinity Church of England High school àti Xaverian Sixth Form College.

Iṣẹ́

àtúnṣe

Mosaku gboyè jáde láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Royal Academy of Dramatic Art ní ọdún 2007. Ó kọ́kọ́ farahàn lórí eré orí ìtàgé nínú eré The Great Theatre of the World èyí tí Pedro Calderón gbé kalẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ti kópa nínú eré Rough Crossing èyí èyí tí Rupert Goold ṣe adarí fún. Ní ọdún 2009, ó kópa nínú eré Isindigo Katrina. Ó farahàn nínú ìwé ìròyìn ní ojú ìwé àkọ́kọ́ tí Screen International ni oṣù kẹfà ọdún 2009 gẹ́gẹ́ bí ìkan lára àwọn gbajúmọ̀ ni orílẹ̀ èdè UK. Ní ọdún 2010, ó kó ipa Malia nínú eré I am Slave[4], èyí ló sì jẹ́ kí ó gba àmì ẹ̀yẹ òṣèré bìnrin to dára jù lọ láti ọ̀dọ̀ Birmingham Black Film Festival, Culture Diversity Awards àti Screen Nation Awards. Ní ọdún 2015, ó kó ipa Quentina nínú eré Capital èyí tí BBC gbé kalẹ̀.[5]

Àṣàyàn àwọn eré tí ó tí ṣe

àtúnṣe
Year Film Role Director
2006 The Women of Troy Helen of Troy Phil Hawkins
2010 Honeymooner Seema Col Spector
Womb Erica Benedek Fliegauf
I Am Slave Malia Gabriel Range
2011 Stolen Sonia Carney Justin Chadwick
Citadel Marie Ciaran Foy
2013 Philomena Young nun Stephen Frears
2016 Batman v Superman: Dawn of Justice Kahina Ziri Zack Snyder
Fantastic Beasts and Where to Find Them Beryl David Yates
2018 Leading Lady Parts Herself Jessica Swale
2019 Sweetness in the Belly Amina Zeresenay Berhane Mehari
2020 His House Rial Remi Weekes

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Wunmi Mosaku. (1986-), Stage and screen actress". National Portrait Gallery. Retrieved 6 January 2019. 
  2. "TEN MINUTES WITH... WUNMI MOSAKU". Arise Live. Archived from the original on 23 September 2015. Retrieved 23 November 2014. 
  3. Wise, Louis (23 December 2018). "Wunmi Mosaku interview: Idris Elba's new Luther sidekick on how she got into acting by watching Annie" (in en). The Times. https://www.thetimes.co.uk/edition/culture/wunmi-mosaku-interview-idris-elba-new-luther-sidekick-xxhm7snpd. Retrieved 6 January 2019. 
  4. Peter J. Thompson. "I AM SLAVE’S WUNMI MOSAKU ON BEING MENDE NAZER". Nigeria Films. Retrieved 24 November 2014. 
  5. "BBC One: Capital". BBC Online. Retrieved 24 November 2015.