Wendy Okolo
Wendy A. Okolo jé onímọ̀ àti oní-ìwàdìí ọkọ̀-òfurufú ní ara àwọn ẹ̀ka NASA Ames Research Center. [1] Ó jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Òun ni obìnrin aláwọ̀ dúdú àkọ́kọ́ tí yóò gba àmì ẹ́yẹ Ph.D nínú Aerospace engineering ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Texas. [2]
Ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeOkolo kẹ́kọ̀ọ́ àlákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rè ní St. Mary primary School ní Lagos Highland, ó sì tẹ̀síwájú ní Queen's college ti ìpínlè Èkó, ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fún ẹ̀kọ́ girama rè. [3] Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Bachelor degree rẹ̀ nínú Aerospace Engineering ní Yunifásítì ìlú Texas (UTA) ní ọdún 2010. Okolo jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ láti gba àmì ẹ̀yẹ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ (Ph.D) nínú ẹ̀kọ́ Aerospace engineering ní yunifásítì náà ní ọdún 2015. Ó jé omo ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ̀n (26) nígbà náà, [4] nígbà tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ ní UTA láti gba àmì ẹyẹ àkọ́kọ́ (Bachelor degree), òun ni ó jẹ Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ engineer ní yunifásítì náà.
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeOkolo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ilé iṣẹ́ Lockhead Martin, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí Orion Spacecraft ti NASA. Lẹ́yìn ìgbà tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka Control Design and Analysis ti Air Force Research Laboratory (AFRL). Wendy so pé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ méjì tí wọ́n jẹ́ obìnrin; Jennifer Okolo àti Phyllis Okolo ni wọ́n jẹ́ akọni rẹ̀, àwon sì ni wọ́n kọ́ ọ ní Biology àti àwọn iṣẹ́ sáyẹ́ǹsì mìíràn. [5]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Dr. Wendy Okolo: The Most Promising Engineer in Government". US Black Engineer – The STEM Community's Magazine. Retrieved 2022-05-26.
- ↑ "African woman reaching lofty heights as aerospace engineer". The Philadelphia Tribune. 2019-03-15. Retrieved 2022-05-26.
- ↑ Ajumobi, Kemi (2021-03-05). "With a PhD at 26, her eyes on the mark, WENDY A. OKOLO steadily soars". Businessday NG. Retrieved 2022-05-26.
- ↑ "Nigeria’s Wendy Okolo Becomes First Black Woman To Earn PhD In Aerospace Engineering At NASA". My Engineers. 2019-02-21. Retrieved 2022-05-26.
- ↑ Tijani, Mayowa (2019-02-19). "Meet Wendy, Nigeria's NASA whizz who is the 'most promising engineer in US government'". TheCable. Retrieved 2022-05-26.