Werner Heisenberg
Werner Heisenberg (5 December 1901 – 1 February 1976) je ara Germany to je onimo fisiyiki oniro to se afikun pataki si isise ero atasere ti o si gbajumo fun titenumo opo aidaju fun iro atasere. Bakanna, o tun se afikun pataki si fisiksi inuatomu, iro papa atasere, ati fisiksi eleruku.
Heisenberg, pelu Max Born ati Pascual Jordan, se ilalele apoti nomba fun isise ero atasere ni 1925. Heisenberg gba Ebun Nobel ninu Fisiyiki ni 1932.
Leyin Ogun Agbaye Keji, o di oludari Kaiser Wilhelm Institute for Physics, to yi oruko si Max Planck Institute for Physics. Ohun ni oludari ile-ekose yi titi ti won fi gbe lo si Munich in 1958, nibi ti won ti fe po si, ti wo si tun yi oruko re si Max Planck Institute for Physics and Astrophysics.
Heisenberg je aare German Research Council, alaga Commission for Atomic Physics, alaga Nuclear Physics Working Group, ati aare Alexander von Humboldt Foundation.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |