Reanne Weruche Opia (tí a bí ní 11 Oṣù Kẹẹ̀rin, Ọdún 1987 ní Nàìjíríà) jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀-èdè Bìrìtìkó, ó sì tún jẹ́ olùṣòwò. Ó jẹ́ aláàkóso ilé ìtajà rẹ̀ tí ó dá sílẹ̀ táa pe orúkọ rẹ̀ ni Jesus Junkie Clothing.[1]

Òṣèré àti oníṣòwò Weruche Opia ní ọdún 2017.
Weruche Opia
Ọjọ́ìbíReanne Weruche Opia
11 Oṣù Kẹẹ̀rin, Ọdún 1987
Nàìjíríà
Iṣẹ́òṣèré orí-ìtàgé

Ìṣẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Weruche gbajúmọ̀ fún kíkó ipa Cleopatra Ofoedo nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Bad Education.[2] Ní Ọdún 2015, wọ́n yan Weruche fún àmì ẹ̀yẹ "Nollywood Actress of the Year" níbi ayẹyẹ 2015 Nigeria Entertainment Awards. Ní ọdún 2018, Opia dì jọ kópa pẹ̀lú Steve Pemberton àti Reece Shearsmith nínu ìpele ẹ̀kẹfà àti ìkẹhìn ti eré "Tempting Fate." Opia tún ti kópa nínu eré BBC kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ I May Destroy You, èyítí ó kọ́kọ́ jẹ́ gbígbé sáfẹ́fẹ́ ní Oṣù Kẹẹ̀fà Ọdún 2020. Opia ti ní oyè-ẹ̀kọ́ nínu eré ìtàgé àti ìmọ̀ àwùjọ.[3] Ó jẹ́ ọmọ ògbólògbó agbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti olùgbàlejò lóri ètò tẹlifíṣọ̀nù Ruth Benamaisia Opia.[4]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

àtúnṣe
Fíìmù
Ọdún Fíìmù Ipa Àwọn àkọsílẹ̀
2010 The Bill as Selina Moris TV series
2013 Top Boy as Nafisa
2014 Bad Education as Cleopatra starred in Series 3
When Love Happens as Mo
2015 Banana (TV series) as Lilia featured in 1 episode
The Bad Education Movie as Cleopatra Ofoedo
Hot Pepper as Toya featured in 1 episode
Suspects as Mae Roberts featured in 2 episodes
Prey (IV) as Ebele short film
2016 When Love Happens Again as Mo film sequel
Thereafter as June short film
2017 Just a Couple as Melissa TV series
2018 Inside No. 9 as Maz featured in 1 episode "Tempting Fate"
2019 Sliced as Naomi TV series featured in all 3 episodes
2020 I May Destroy You as Terry TV Series

Àwọn ìyẹ́sí rẹ̀

àtúnṣe
Ọdún Ayẹyẹ Àmì-ẹ̀yẹ Èsì ìtọ́kasí
2015 2015 Nigeria Entertainment Awards Actress of The Year (Nollywood) Wọ́n pèé [5]
3rd Africa Magic Viewers Choice Awards Best Actress in a Comedy Wọ́n pèé [6]


Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "YHP Interviews Young Entrepreneur and CEO of Jesus Junkie, Reanne Weruche Opia.". Your Hidden Potential. 5 October 2009. Archived from the original on 17 September 2016. Retrieved 30 May 2016. 
  2. "Bad Education's girls interview". British Comedy Guide. Retrieved 30 May 2016. 
  3. "Weruche Opia". Afrinolly. Archived from the original on 22 August 2016. https://web.archive.org/web/20160822142633/https://m.afrinolly.com/celebs/d/851. Retrieved 30 May 2016. 
  4. "Weruche Opia is the next Nigerian actress you should be stanning". YNaija. 29 June 2020. https://ynaija.com/weruche-opia-is-the-next-nigerian-actress-you-should-be-stanning/. Retrieved 13 July 2020. 
  5. Oneill, Danielle (15 July 2015). "The Nigeria Entertainment Awards Announce 2015 Nominees". OkayAfrica. Retrieved 30 May 2016. 
  6. Izuzu, Chidumga (11 December 2014). "AMVCA 2015 Nominees Rita Dominic, 'October 1', '30 Days in Atlanta', get nominations". Pulse Nigeria. Archived from the original on 17 May 2017. Retrieved 30 May 2016.