Wikipedia:Àyọkà ọ̀ṣẹ̀ 19 ọdún 2021

Ìṣekúpa ààrẹ Abraham Lincoln (Currier & Ives, 1865), lati òsì sí ọ̀tún: Major Henry Rathbone, Clara Harris, Mary Todd Lincoln, Abraham Lincoln, àti apànìyàn, John Wilkes Booth Àtẹ̀jáde yìí ṣe àfihàn wípé Rathbone rí Booth tí ó wọ ibi tí ààrẹ wà tí ó sì ti dìde bí Booth ṣe yin ìbon. Ní tòótọ/ , Rathbone ò mọ oun tí Booth fẹ́ lọ sè ṣùgbọn o dá si lẹ́yìn tí ó yìnbọn
Ìṣekúpa ààrẹ Abraham Lincoln (Currier & Ives, 1865), lati òsì sí ọ̀tún: Major Henry Rathbone, Clara Harris, Mary Todd Lincoln, Abraham Lincoln, àti apànìyàn, John Wilkes Booth Àtẹ̀jáde yìí ṣe àfihàn wípé Rathbone rí Booth tí ó wọ ibi tí ààrẹ wà tí ó sì ti dìde bí Booth ṣe yin ìbon. Ní tòótọ/ , Rathbone ò mọ oun tí Booth fẹ́ lọ sè ṣùgbọn o dá si lẹ́yìn tí ó yìnbọn


Ìṣekúpa Abraham Lincoln John Wilkes Boot ṣekú pa Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà Abraham Lincoln ní ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ kẹrìnlá Oṣù kẹrìnlá, Ọdún 1865, nígbà tí ó lọ wo eré Our American Cousin ní ilé ìṣeré orí ìtàgé Ford bí ogun abẹ́lé Amẹ́ríkà ṣe ń lọ sí òpin. Ìpànìyàn yìí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ karún tí balógun ti ológun dìmọlú ti gúúsù Virginia, ọ̀gágun  Robert E. Lee jọ̀wọ́ ara rẹ̀  àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ fún ọ̀gágun Ulysses S. Grant tí ó jẹ́ ọ̀gạ́gun pátápátá àti ti àwọn ìṣọ̀kan ológun ti Potomac. Lincoln jẹ́ ààrẹ Amẹ́ríkà àkọ́kọ́ tí àwọn agbanipa máa pa. Ìgbìyanjú àkọ́kọ́ ti ṣẹlẹ̀ lórí Andrew Jackson ní bíi ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn kí wọ́n tó pa Lincoln ní ọdún 1835, tí Lincoln fúnra rẹ̀ sí jẹ́ sábàbí ìpànìyàn tó jásí pàbó nígba tí apànìyàn kan tí a kò mọ̀ fẹ́ paá ní Oṣù kẹjọ Ọdún 1864. Ìṣekúpa Lincoln jẹ́ oun tí wọ́n gbèrò tí ó sì jẹ́ wípé ògbónta òṣèré orí ìtagé, John Wilkes Booth, ti gbogbo ènìyàn mọ̀ bí ẹní mọwó ni ó ṣe iṣẹ́ láabi yìí, tí ó jẹ́ ìpàdí ààpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan fún ìdí ìṣọ̀kan.

Àwọn ẹlẹgbẹ́ Booth tí wọ́n di rìkíṣí yìí ní Lewis Powell àti David Herold, tí wọ́n yàn lati pa akọ̀wé ìlú William H. Seward àti George Atzerodt tí wọ́n fún ní iṣẹ́ lati pa Igbákejì ààrẹ Andrew Johnson. Bákan náà, kí wọ́n pa àwọn olórí mẹ́ta nínú ìjọba, Booth àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ní ìrètí lati dojú ìjà kọ ìjọba Àwọn Ìpínlẹ̀ Àṣọ̀kan Àmẹ́ríkà. Wọ́n yin Lincoln nígbọn nígbà tí ó ń wo eré ìtàgé Our American Cousin pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀  Mary Todd Lincoln ní ilé ìṣeré orí ìtàgé Ford ní Washington, D.C.. Ó kú ní agogo méje lé ìṣẹ́jú méjìdínlógún àárọ̀. Ìgbìyànjú àwọn oní rìkíṣí tó kù jásí pàbó; Powell kàn ṣe Seward léṣe,  Atzerodt tí ó fẹ́ pa Johnson sì ferége.  Ètò ìsìnkú àti ìsìnkú Abraham Lincoln jẹ́ àkókò ọ̀fọ̀ fún gbogbo ìlú.

(ìtẹ̀síwájú...)