Wikipedia:Ìbẹ̀rẹ̀

Lórí Wikipedia, ẹ lè ṣe àtúnṣe sí ojúewé kíákíá, bọ́tilẹ̀ jẹ́pé ẹ kò bá tíì forúkọsílẹ̀, nípa lílo ìpele "àtúnṣe" tó wà lórí ojúewé kọ̀ọ̀kan.

Kíni Wikipedia jẹ́?

Ẹ tẹ ìpele Àtúnṣe láti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣàtúnṣe sí ojúewé kan

Wikipedia jẹ́ ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́ tó wà nítorí akitiyan awọn oníse rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n kópa nínú iṣẹ́-ọwọ́ yìí lè dá àyọkà tuntun tàbí ṣàtúnṣe àwọn àyọkà tó wà. Àfikún kọ̀ọ̀kan únjẹ́ kíkọ sílẹ̀ sínú ìtàn àwọn ojúewé bẹ́ẹ̀sìni wọ́n únhàn nínú àwọn àtúnṣe tuntun. Àwọn ohun tí wọn kò bá ní ìbámu pọ̀ mọ́ ìwé ìmọ̀ Wikipedia yíò jẹ́ píparẹ́.

Báwo lẹ ṣe le kópa?

Ẹ mọ́ fòyà láti ṣàtúnṣe àwọn ojúewé. Ẹnikẹ́ni yìówù ni ó le ṣe àtúnṣe, tó bá sáà jẹ́ pé onítòhún kò fa ìbàjẹ́ sí àkóónú àwọn àyọkà. Tí ẹ bá rí àsìṣe tàbí àfojúfò kankan, ẹ lè ṣe àtúnṣe rẹ̀.

Kò sí irú àtúnṣe kankan tó le fa ìbàjẹ́ sí Wikipedia nítorípé àsìṣe tàbí ìbàjẹ́ yìówù tó bá ṣẹlẹ̀ le jẹ́ yíyípadà.

Láti dán àtúnṣe ojúewé wò:

  1. Ẹ lọ sí inú àpótí àdánwò
  2. Ẹ tẹ ìpele Àtúnṣe orí ojúewé náà láti mú ààyè àtúnṣe jáde. Ẹ kọ ọ̀rọ̀ tí ẹ bá fẹ́ síbẹ̀.
  3. Tí ẹ bá ṣetán ẹ tẹ bọ́tìnì Ìmúpamọ́ ojúewé láti fí àtúnṣe yín pamọ́
    ...tàbí ẹ lè tẹ bọ́tìnì "Àyẹ̀wò" láti wo bí ojúewé náà yíò ṣe rí kí ẹ tó múupamọ́


Tóúnbọ̀: Síṣe àtúnṣe >>