Wikipedia:Òpó márún
Ojúlówó ètò àgbékalẹ̀ Wikipedia ní ṣókí ní "òpó marún":
Wikipedia jẹ́ ìwé-ìmọ ọfẹ : Ó ṣe àkójọpọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà ìwé-ìmọ ọfẹ, ìwé ọlọ́dọọdún àtí ìwé ìtumọ̀ nípa ìletò àti agbèègbè tí gbogboògbò àti àwọn tó ṣe pàtàkì. Wikipedia kìí ṣe fún ìpolongo òṣèlú, kìí ṣe ibi ìpolówó , ibi ìgberòyin jáde, ibi ìṣàyẹ̀wò ìjọba àìlólórí tabí tiwantiwa, tàbí ojú òpó ìwé àkọpọ̀. Kìí ṣe ìwé ìtumọ̀, ìwé ìròyìn, tabí àkójọpọ̀ àwọn ìwé àkọsílẹ̀, bí ótilẹ̀jẹ́pé àwọn iṣẹ́ àkànṣe Wikimedia míràn jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Wón máa ń kọ Wikipedia láìfìkan bòkan: A máa ń gbìyànjú fún àwọn àyọkà tí ó ṣe àlàyé nípa kókó ọ̀rọ̀ láìfí igbá kan bọ̀kan nínú. A máa ń yàgó fún àgbàwí. À máa ń ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ láìsí ìtàkùsọ́rọ̀. Níbòmíràn ó lè jẹ́ wípé èrò kan péré ní ó wà. Ní àwọn ibòmíràn, a máa ń ṣàpèjúwe ọ́̀pọlọpọ̀ èrò, a sí ma ń ṣàgbékalẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́, ó lè má jẹ́ "òótọ́" tàbí "èrò tódára jùlọ".
Wikipedia jẹ́ ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́ tí ẹnikẹ́ni lè lò, ṣàtúnṣe sí, tí ó sì lè pín kiri: Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ ípé àwọn olóòtu Wikipedia kìí gba owó lati kọ àyọkà, kòsí ẹni tí ó ni àyọkà, wọ́n lè ṣe àtunṣe sí ohunkóhun tí o bá kọ, tí wọ́n sì lè pín. Bọ̀wọ̀ fún àwọn òfin tí kò fàyè gba ìda iṣẹ́ oníṣẹ́ kọ, má sì da ìwé oníwé kọ.
Àwọn olóòtú gbọ́dọ̀ fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bára wọn lò. Bọ̀wò fún àwọn olóòtu olóòtú Wikipedeia ẹlẹgbẹ́ rẹ, tí o kò ba ́ tilẹ̀ gbà fún wọn. Lo ofín Wikipedia, àti pé o kò gbọdọ dojú ìjà kọ ẹnikẹ́ni. Jẹ́ kí àwọn àwọn olóòtù tókù dási ọ̀rọ̀ yín, lọ́ra fún ogun lorí àtúnṣe sí àyọkà, má ṣe ba Wikipedia jẹ́ kí o lè ṣpèjúwe ọrọ. Má ṣe bínú sí ohunkóhun, jẹ́ki inú rẹ mọ́ kí o sì fa àwọn olóòtú tuntun mọ́ra. Tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀, jomitoro pẹ̀lu ́ wọn pẹ̀lú ohun tútù ní ojú ewé ọ̀rọ̀ oníṣẹ́, kí o sì tẹ́lé ìlànà tí wọ́n fi ń pàrí ìjà, kí o sì fi sọ́kàn wípé àyọkà 5,185,472 ló ń fẹ́ àtúnṣe àti ìjomitoro.
Wikipedia has no firm rules: Wikipedia kò ní òfin tó le: Wikipedia ní àwọ ètò iṣẹ́ àti ìlànà, ṣùgbọ́n wọn kò le koko bí òkúta;