Wikipedia:Ẹ kú àbọ̀

Ìkíni jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àṣà ìbílẹ̀ẹ Yorùbá. Ìwà ọmọlúwàbí ni kíkí' ni àti ìbọ̀wọ̀ f'ágbà. Ẹ̀wẹ̀wẹ̀, ọmọdé ní ń kọ́kọ́ kí àgbà nílẹ̀ yìí, àfojúdi ni fún ọmọdé tí ó rí àgbà tí kò k'ágbà.

Tótó ṣe bí òwe, àwọn àgbàlagbà ló ní wípé, "bí a bá ṣe ko 'ni; là á kí'ni, bí a bá ṣe kí' ni là á jẹ́'ni", èyí ń tọ́ka sí iha tí àwọn baba-ńláa wá kọ sí àṣà ìkíni ní ilẹ̀ẹ káàárọ̀-o-ò-jí-ire.

Báwo wá ni a ṣe ń kí'ni nílẹ̀ẹ Yoòbá?

"Kú" jẹ́ gbólóhùn tí ó pọn dandan bí a bá ń kí ènìyàn. Àmọ́, sàwáwù ẹni ni ẹni lè lo "kú" fún, "ẹ kú" ni ti àgbàlagbà tó ju'ni lọ. Bí a bá fẹ́ kí ìyá, bàbá tàbí ẹni tó ju' ni lọ, "ẹ kú..." ni a óò fi bẹ̀rẹ̀ ìkíni náà. Fún àpẹẹrẹ, "ẹ kú àbọ̀ bàbá", "ẹ kú iṣẹ́ ìyá ", ẹ káàbọ̀ ẹ̀gbọ́n". Bó ṣe ẹlẹgbẹ́ ẹni tàbí ẹni tí a jù lọ, "kú" ni atọ́ka, "kú àbọ̀ ", "kú àbọ̀ àbúrò" àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Alẹ́ = kú alẹ́ (káalẹ́). Oorun = kú oorun. --ỌMỌ YOÒBÁ (ọ̀rọ̀) 10:48, 29 Oṣù Kẹ̀sán 2018 (UTC)