Ogun Àgbáyé Kìíní

(Àtúnjúwe láti World War I)

ÌJÀ OGUN ÀGBAYÉ KÌÍNÍ Láti ọjọ́ ti aláyé ti dáyé ni àwọn ìwọ̀ búburú bí i: jàgídíjàgan, wàhálà. Rúkèrúdò ti wà nínú ìgbésí ayé ọmọ ènìyàn. Rògbòdìyàn kò yé sẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ nì làásìgbò kò roko ìgbàgbé. Ìdàrúdàpọ̀ nínú ẹbí, Àríyànjiyàn láàárin ọ̀rẹ́. Gbọ́nmisi, omi ò to kò yé wáyé láàárín ìlú sí ilu, abúléko sí abúléko. Gbogbo àwọn nǹkan ló ń parapọ̀ tí ó sì ń di ogun.

Àwọ̀rán Àgbáyé Kìíní (WWImontage)
Ogun Àgbáyé Kìíní
Fáìlì:WW1 TitlePicture For Wikipedia Article.jpg
Clockwise from top: Trenches on the Western Front; a British Mark IV tank crossing a trench; Royal Navy battleship HMS Irresistible sinking after striking a mine at the Battle of the Dardanelles; a Vickers machine gun crew with gas masks, and German Albatros D.III biplanes
Date 28 July 1914 – 11 November 1918 (Armistice Treaty)

Treaty of Versailles signed 28 June 1919

Location Europe, Africa and the Middle East (briefly in China and the Pacific Islands)
Result Allied victory; end of the German, Russian, Ottoman, and Austro-Hungarian Empires; foundation of new countries in Europe and the Middle East; transfer of German colonies to other powers; establishment of the League of Nations.
Belligerents
Allied (Entente) Powers Central Powers
Commanders
Leaders and commanders Leaders and commanders
Casualties and losses
Military dead:
5,525,000
Military wounded:
12,831,500
Military missing:
4,121,000
Total:
22,477,500 KIA, WIA or MIA ...further details.
Military dead:
4,386,000
Military wounded:
8,388,000
Military missing:
3,629,000
Total:
16,403,000 KIA, WIA or MIA ...further details.

Tí a bá fi ojú sùnùkùn wo ogun àgbáyé kìíní, a óò rí wí pé gbogbo rògbòdìyàn, àjàkú akátá tó wáyé, kò sẹ̀yìn ìwà ìgbéraga, owú jíjẹ, èmi ni mo jùọ́ lọ, ìwọ lo jùmí lọ láàárín àwọn ọmọ adáríwurun. Àwọn àgbà sì bọ̀ wọ́n ní “àìfàgbà fẹ́nìkan ni kò jẹ́ káyé ó gún”. Nígbà tí ẹnìkan bá rò pé òun ló mọ nǹkan ṣe jú, èrò tòun ló tọ̀nà jù, kò sí ẹni tó gbọ́dọ̀ ta ko ohun tí òun bá sọ. Àwọn nǹkan wọ̀nyí tó máa ń bí ogun, nígbà tí elòmírà bá ta ko irúfẹ́ èèyàn bẹ́ẹ̀ tàbí kí ó jẹ gàba lé òun lórí. Bí ogun ṣe máa ń sẹlẹ̀ láàárin ìlú sí ìlú ló máa ń sẹlẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè.

Ara àwọn nǹkan tí ó sokùn fa ogun àgbáyé àkọ́kọ́ nìyí. Ogun àgbáyé àkọ́kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ láàárin orílẹ̀-èdè méjì kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Austria-Hungary ati Serbia. Ìlú kékeré kan ní awọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí ń jà lé lórí. Orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́ ló kọ́kọ́ gba ìlú yìí lọ́wọ́ ẹ̀kẹjì nínú ogun kan tó wáyé ní ọdún 1908. Orílẹ̀-èdè kejì wá ń dún kòkò lajà láti gba ìtú yìí padà. Sáájú àsìkò yìí, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ kan sẹ̀lẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ sí mú kí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé máa ṣe gbún-ùn gbùn-ùn gbún-ùn sí ara wọn. Sáájú ogun àgbàyé kìíní, àwọn orílẹ̀-èdè ló máa ń jẹ gàba lórí àwọ́n orílẹ̀-èdè mìíràn nígbà máà, kò pẹ́ kò jìnnà tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní mú sìn yìí bẹ̀rẹ̀ ń jà fún òmìnira.

Orílẹ̀-èdè [Belgium] gba òmìnìra ní ọdún 1830, nígbà tí ilẹ̀ [Germany] gba tiwọn ní 1871. Ìjà òmìnìra wá bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lólogbó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira. Àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kọ́kọ́ tako èyí, síbẹ̀síbẹ̀, wọn kò rí nǹkan ṣe si èyí. Gbogbo àwọn tí wọ́n tí wọ́n ti jẹ́ gàba lé lórí bẹ̀rẹ̀ sí jà fún òmìnira. Gbogbo wọn kóra pọ̀. Bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí ni ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà bẹ̀rẹ̀ sí sẹlẹ̀, àti àwọ́n ìsòro tí ó rọ̀ mọ́ ẹlẹ́yàmẹ̀yà. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló sokùnfà rògbòdìyàn ogun nígbà náà yàtọ̀ sí èyí, wíwá àwọn òyìnbó sí ilẹ̀ aláwò dúdú [Africa] wà lára àwọn nǹkan to sokùnfà ogun àgbáyé kìíní. Owó ló gbé àwọn òyìnbó dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, wọ́n wá ri pé yíò rọrùn fún àwọn láti rí nǹkan àlùmọ́ọ́nì tí wọ́n ń fẹ́ tí àwọn bá mú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú sìn. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òyìnbó wọ̀nyí dé ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ìjọ̀ bèrè sí wáyé láàárin wọn lórí orílẹ̀-èdè tí oníkálukú wọn yíò mú sìn. Nígbà tí wọ́n ń pín ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú láàárin ara wọn, bí wọn ṣe pin kò tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè amúnisìn kan lọ́rùn lórí bí wọ́n ṣe pín àwọn orílẹ̀-èdè aláwọ̀ dúdú láàárin ara wọn nígbà náà Àyọrísí gbogbo wàhálà yìí ló sokùnfà ogun àgbáyé àkọ́kọ́. Àwọn orílẹ̀-èdè alágbára wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí furá sí ara wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kó nǹkan ijà olóró jọ. Àwọn orílẹ̀-èdè kan bẹ̀rẹ̀ sí ní bá ara wọn sọ̀rẹ́ láti gbógun ti orílẹ̀-èdè mìíràn. Nígbà tí ogun yìí yóò fi bẹ̀rẹ̀, awọn orílẹ̀-èdè alágbára pín ara wọn sí ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Orílẹ̀-èdè [Germany], [Austria-Hungary] ati [Italy] wà ní ẹgbẹ́ kan, nígbà tí orílẹ̀-èdè [Britain], [France] àti [Russia] wà nínú ẹgbẹ́ kejì, Ní ọjọ́ kejìdínlógún osù kẹfà ọdún 1914 [18/6/1914] ni okùnrin kan tó ń jẹ́ Gavrilo Princip tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Serbia sekú pa ọmọ Ọba orílẹ̀-èdè Astria-Hungary tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Francis Ferdinand ẹni tó yẹ kó di ọba ní orílẹ̀-èdè náà. Èyí kò sẹ̀yìn ìgbìyànjú Serbia láti gba àwọn ẹ̀yà tí Austria-Hungary ti kó sínú ìgbèkùn nínú ogun tí wọ́n ti jà tẹ́lẹ̀. Ikú ọmọ ọba yìí ló sokùnfà ogun àgbáyé nígbà tí orílẹ̀-èdè Astria-Hungary gbaná jẹ. Wọ́n pinnu láti gbógun ti ilẹ̀ Serbia. Bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí ni ilẹ̀ Russia tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ilẹ̀ Serbia kéde pé àwọn yíò gbógun tí ilẹ̀ Austria-Hungary. Àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé gbìyànjù láti pẹ̀tù sí wàhálà yìí. Ilẹ̀

Austria-Hungary fún ilẹ̀ Serbia ní àwọn nǹkan tó le mu ogun yìí wọlè, ṣùgbọ́n ilẹ̀ Serbia kò tẹ̀lé àwọn nǹkan wọ̀nyí. Látàrí èyí, ilẹ̀ Austria-Hungary kéde ogun lé Serbia lórí ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n osù kẹjọ ọdún 1914 [28/8/1914]. Bí ilẹ̀ Austria-Hungary ṣe ṣe èyí tan ni orílẹ̀-èdè Russia náà kéde ogun lé ilẹ̀ Austria-Hungary lórí. Bí ilẹ̀ Russia ṣe ṣe èyí tán ni ilè Germany kìtọ̀ fúnwọ̀n pé tí wọ́n bá danwò, àwọn yíò gbógun tìwọ́n. Nígbà tí ilẹ̀ Austria-Hungary ríbi tí ọ̀rọ̀ yìí ń tọ, wọ́n tẹsẹ̀ dúró fún ìjíròrò pẹ̀lú ilẹ̀ Russia. Ilẹ̀ Germany pàsẹ láti tú àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ti kójọ tẹ́lẹ̀ kọ́ fún ogun yìí ká. Ilẹ Russia kọ etí ikún sí àsẹ tí ilẹ̀ Germany lórí àsẹ yìí. Èyí ló mú kí ilẹ̀ Germany kéde ogun lé ilẹ̀ Russia lórí ní ọjọ́ kìíní osù kejọ ọdún 1914 [1/8/1914]. Ní ọjọ́ kejì sí èyí ni ilẹ̀ ni ilẹ̀ France náà kéde ogun lé ilẹ̀ Germany náà lórí. Ní ọjọ́ kẹta ni ilẹ̀ Germany kéde ogun lé ilẹ̀ France lórí padà.

Sáájú kí ogun tó bẹ̀rẹ̀, ilẹ̀ Belgium tí kọ̀wé ránṣẹ́ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó kù pé tí ogun bá bẹ̀rẹ̀, àwọn kò ní lọ́wọ́ síi. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí sì fọwọ́ sí ìwé tí ilẹ̀ Belgium kọ síwọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ogun bẹ̀rẹ̀, ilẹ̀ Germany pinu láti gba ilẹ̀ Belgium kọjá láti kọ lu ilẹ̀ France. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ Belgium kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ti pínú pé àwọn kò ní dá sí ìjà. Èyí mú kí ilẹ̀ Germany bínú, wọ́n sì pínú láti gbógun tí ilẹ̀ Belgium.

Ìpin ìlẹ̀ Germany yìí mú kí ilẹ̀ Britain dá sí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n kìlọ̀ fún ilẹ̀ Germany láti ro ìpin àti gbógun ti ilẹ̀ Belgium ní ẹ̀ẹ̀mejì nítorí pé gbogbo àwọn ni àwọn fi ọwọ́ si pé ilẹ̀ Belgium kò ní lọ́wọ́ si ogun yìí nítorí náà, kí wọ́n má ṣe gbógun ti ilẹ̀ Belgium. Ilẹ̀ Germany kọ̀ jálẹ̀ láti gba ọrọ yìí yẹ̀wò, èyí sì mú kí orílẹ̀-èdè Britan kéde ogun lé ilẹ̀ Germany lóri ní ọjọ́ kẹrin osù kẹjọ ọdún 1914 [4/8/1914].

Ilẹ̀ Turkey náà dá sí ogun yìí ní osù kẹwàá ọdún 1914. Nígbà tí ilẹ̀ France náà da si ní osù kọkànlá ọdún 1914. Báyìí ni ogun yìí di ogun àgbéyé, tí ó di ìjà àjàràn. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí awọn orílẹ̀-èdè alágbára wọ̀nyí ń ṣe àkóso lé lórí tí wọ́n ń mú sìn pàápàá jùlọ ní ilẹ̀ adúláwọ̀ [Africa] àti ilẹ̀ Lárúbáwá ni gbogbo wọn náà múra láti gbè sẹ́yìn àwọn ọ̀gá wọn láti bá àwọn orílẹ̀-èdè yòókù jà tí èyí sì di isu atayán-an yàn-an káàkiri orílẹ̀-èdè àgbáyé.

Ní osù kẹrin ọdún 1917 ni ile America náà kéde ogun lé ilẹ̀ Germany lórí látàrí bí wọn ṣe kọlu àwọn ara ilẹ̀ America nínú ọkọ̀ ojú-oni ti èyí si tako ìlànà ogun jìjà. Òfin sì wà wí pé tí orílẹ̀-èdè méjì bá ń jà, àwọn ọmọ ogun ara wọn nìkan ní wọ́n dojú ìjà kọ. Orílẹ̀-èdè Germany rú òfin yìí. Èyí sì bí ilẹ̀ America nínú, ìdí nìyí tí wọ́n fi dá’ sí ogun àgbáyé ní ọdún 1917.

Ogun àgbáyé tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n osù keje ọdún 1914 [28/7/1914] parí ní ọjọ́ kọkànlá osù kọ́kànlá ọdún 1918[11/11/1918] lẹ́yìn ọdún mẹ́rin, osù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́rìnlá tí ogun ti bẹ̀rẹ̀. Owó tí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé ná sí ogun yìí tó Ọgórùn-ún méjì Bílóọ̀nù dọ́là [Two Hundred Billons Dollas] owó ilẹ̀ America láyé ìgbà náà tí owó níyì. Bí i ogójì mílíọ̀nù [Fourty Millions] ọmọ ogun orílẹ̀-èdè àgbáyé ló bá ogun yìí lọ kí á ṣẹ̀ṣẹ̀ má sọ ti àwọn ogun ojú-oun bí i mílíọ̀nù mẹ́wàá [Ten millions] tí ó ará ìlú tá kìí ṣe sọ́jà ló sòfò nínú ogun àgbéyé yìí.

Síbẹ̀síbẹ̀, wàhálà tó sokùnfà ogun àgbáyé àkọ́kọ́ tí àwọn èèyàn rò pé yíò yanju tàbí níyanjú. Wàhálà yìí ló tún sokùnfà ogun àgbáyé kejì àti àwọn ogun tó tún wáyé lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní. Ní ìparí, ogun kìí ṣe nǹkan tí ó dára. Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní "ẹni tí ogun ba pa kù ní ń ròyìn ogun". Ogun máa ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ èmí àti dúkìẹ́ sòfò. Yorùbá tún bọ̀ wọ́n ní "ẹni tí sàngó bá tojú rẹ̀ jà rí kò ní báwọn bú olúkòso". Ẹnì tí Ogun bá jà lójú rẹ̀ rí, kò ní bẹ ọlọ́run kí ogun tún wáyé ní ojú òun. Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí á ri ogun.