Wunmi Mosaku
Wunmi Mosaku (bíi ni ọdún 1986) jẹ́ òṣèré àti olórin ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [2]Ó gbajúmọ̀ fún ipa Joy tí ó kó nínú eré Moses Jones (2009) àti Holly Lawson nínú eré Vera(2011). Ó gba àmì ẹ̀yẹ Best Supporting Actress láti ọ̀dọ̀ BAFTA TV Award fún ipa Gloria Taylor tí ó kó nínú eré Damilola, Our Loved Boy ni ọdún 2016. Ní ọdún 2019, ó kópa nínú ipá karùn-ún tí fíìmù Luther.[3]
Wunmi Mosaku | |
---|---|
Mosaku at The Old Vic, 2010 | |
Ọjọ́ìbí | Oluwunmi Mosaku 1986 (ọmọ ọdún 37–38)[1] Nigeria |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Royal Academy of Dramatic Art (2007) |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 2006–present |
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Mosaku sì orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àmọ́ wọ́n gbe lọ sí ìlú Manchester ni orílẹ̀ èdè England. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Trinity Church of England High school àti Xaverian Sixth Form College.
Iṣẹ́
àtúnṣeMosaku gboyè jáde láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Royal Academy of Dramatic Art ní ọdún 2007. Ó kọ́kọ́ farahàn lórí eré orí ìtàgé nínú eré The Great Theatre of the World èyí tí Pedro Calderón gbé kalẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ti kópa nínú eré Rough Crossing èyí èyí tí Rupert Goold ṣe adarí fún. Ní ọdún 2009, ó kópa nínú eré Isindigo Katrina. Ó farahàn nínú ìwé ìròyìn ní ojú ìwé àkọ́kọ́ tí Screen International ni oṣù kẹfà ọdún 2009 gẹ́gẹ́ bí ìkan lára àwọn gbajúmọ̀ ni orílẹ̀ èdè UK. Ní ọdún 2010, ó kó ipa Malia nínú eré I am Slave[4], èyí ló sì jẹ́ kí ó gba àmì ẹ̀yẹ òṣèré bìnrin to dára jù lọ láti ọ̀dọ̀ Birmingham Black Film Festival, Culture Diversity Awards àti Screen Nation Awards. Ní ọdún 2015, ó kó ipa Quentina nínú eré Capital èyí tí BBC gbé kalẹ̀.[5]
Àṣàyàn àwọn eré tí ó tí ṣe
àtúnṣeYear | Film | Role | Director |
---|---|---|---|
2006 | The Women of Troy | Helen of Troy | Phil Hawkins |
2010 | Honeymooner | Seema | Col Spector |
Womb | Erica | Benedek Fliegauf | |
I Am Slave | Malia | Gabriel Range | |
2011 | Stolen | Sonia Carney | Justin Chadwick |
Citadel | Marie | Ciaran Foy | |
2013 | Philomena | Young nun | Stephen Frears |
2016 | Batman v Superman: Dawn of Justice | Kahina Ziri | Zack Snyder |
Fantastic Beasts and Where to Find Them | Beryl | David Yates | |
2018 | Leading Lady Parts | Herself | Jessica Swale |
2019 | Sweetness in the Belly | Amina | Zeresenay Berhane Mehari |
2020 | His House | Rial | Remi Weekes |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Wunmi Mosaku. (1986-), Stage and screen actress". National Portrait Gallery. Retrieved 6 January 2019.
- ↑ "TEN MINUTES WITH... WUNMI MOSAKU". Arise Live. Archived from the original on 23 September 2015. Retrieved 23 November 2014.
- ↑ Wise, Louis (23 December 2018). "Wunmi Mosaku interview: Idris Elba's new Luther sidekick on how she got into acting by watching Annie" (in en). The Times. https://www.thetimes.co.uk/edition/culture/wunmi-mosaku-interview-idris-elba-new-luther-sidekick-xxhm7snpd. Retrieved 6 January 2019.
- ↑ Peter J. Thompson. "I AM SLAVE’S WUNMI MOSAKU ON BEING MENDE NAZER". Nigeria Films. Retrieved 24 November 2014.
- ↑ "BBC One: Capital". BBC Online. Retrieved 24 November 2015.