Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Èkó

yunifasiti gbangba ni Ojo, Nigeria

Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Èkó tí a tún mọ̀ sí LASU, wà ní Ojo, ìlú kan ní Ìpínlẹ̀ Eko, Nàìjíríà. A dá ilé ẹ̀kọ́ gíga náà sílẹ̀ ní ọdún ọdun 1983 ní ìlànà pẹ̀lú òfin tí o fun lálẹ̀ ni Ìpínlẹ̀ Èkó,[5] [6] fún ìlọsíwájú ti ẹ̀kọ́; ọ̀rọ̀ àkọmọnà wọn Fun Otitọ ati Iṣẹ.[7]

Lagos State University
Nibi ni aami
Motto"For Truth and Service" (Èdè Gẹ̀ẹ́sì)
Established1983
TypeAwujọ ẹda
ChancellorGbolahan Elias,SAN[1]
Vice-ChancellorIbiyemi Olatunji-Bello[2][3][4]
Students35,000
LocationOjo, Eko, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Websitewww.lasu.edu.ng
Ọ̀nà àbáwọlé Yunifásitì ìpínlè Eko

Ilé-ẹ̀kọ́ gíga yìí dáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ilé-ẹ̀kọ́ àgbègbè pẹ̀lú èrò láti jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ tí kò ní ilé-ìgbé.

Ilé ìtàgé tó lè gbà èèyàn ọ̀ọ́dúnrún (300) wà ní ìkọ́lẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó wà ní Ọ́jọ́ nípasẹ̀ Àjọ Àwórí Ìlera Àwọn Ará Nàìjíríà (AWAN). Àyè iṣẹ́ ìkọ́lẹ̀ náà wà ní òpópónà ilé tí a npè ní Babátúndé Rájí Fáṣọlá Senate House. Ó ṣàbẹ̀ ilé ìkàwé tuntun tí wọ́n ń kọ́, àti ilé àwọn ẹ̀ka ọmọ ile-ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀ títí di báyìí. Nígbà tí wọ́n bá parí iṣẹ́ náà, ilé náà yóò jẹ́ ibi ìkọ́ nípa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀fiisi àti àwọn iṣẹ́ ẹ̀kọ́.

Ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀ka mẹ́ta: Ìṣòwò àti Ìdarí Ìṣòwò, Òfin, àti Ìṣègùn. Ẹ̀ka Ìṣòwò àti Ìdarí Ìṣòwò ni wọ́n yí padà sí Ẹ̀ka Ìṣòwò àti Ìmọ̀ Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìjìnlẹ̀ ní ìpàdé àkọ́kọ́ tí ìgbìmọ̀ náà ṣe. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣàfikún àwọn ẹ̀ka: Èdè, Ẹ̀kọ́, Ẹ̀kọ́ Ẹ̀rọ, Àwọn Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ìjọba àti Ìṣòwò, Ẹ̀ka Ìsọfúnni àti Ẹ̀kọ́ Àgbáyé, Ìmọ̀ Ìròyìn àti Ẹ̀kọ́ Àkànṣe Gbigbé, àti Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Òfurufú.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Premium Times (30 July 2020). "LASU, LASPOLY, other Lagos-owned tertiary institutions get new governing councils – FULL LIST". Premiumtimesng.com. Premium Times. Retrieved 2021-12-06. 
  2. Premium Times (20 September 2021). "New LASU VC, Olatunji-Bello takes charge". Premiumtimesng.com. Retrieved 2021-12-06. 
  3. "Nigerians hail Sanwo-Olu's appointment of new LASU VC". Businessday NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-09-21. Retrieved 2022-03-17. 
  4. "How 9th LASU VC emerged". The Sun Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-10-05. Retrieved 2022-03-17. 
  5. https://lasu.edu.ng/home/pages/?id=about
  6. https://www.pulse.ng/communities/student/know-your-university-lasu-11-things-you-did-not-know-about-lagos-state-university/rwg08rw
  7. https://lasu.edu.ng/home/pages/?id=about