Zina Saro-Wiwa (tí a bí ní ọdún 1976, Port Harcourt, Nigeria ) jẹ́ olórin fídíò àti onífíìmù tí ó gbé ní Brooklyn. Ó ṣe àwọn fídíò, àwọn ìwé àkọọ́lẹ̀, àwọn fídíò orin àti àwọn fíìmù àdánwò.

Zina Saro-Wiwa
Ọjọ́ìbí1976 (ọmọ ọdún 47–48)
Port Harcourt, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian, British
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Bristol
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́2008 - present
Àwọn olùbátan

Saro-Wiwa ni olùdásílẹ fíìmù ti ẹgbẹ́ alt- Nollywood . Ìgbìyànjú tí ó ńlò ìtan-àkọọ́lẹ̀, àṣà àti àwọn àpéjọ wíwò ti ilé-iṣẹ́ fíìmù Nollywood ṣùgbọ́n fun awọn ajàfẹ́tọ-ènìyàn nípa ètò òṣèlú.

Ó jẹ́ akọ̀ròyìn BBC tẹ́lẹ̀ rí, a bí iṣé ọnà rẹ̀ jáde láti inú ìfẹ́ rẹ̀ láti mú ìyípadà bá ojú tí gbogbo àgbáyé fi ń wo Áfíríkà nípa lílo fíìmù, àwòrán, àti oúnjẹ. Iṣé rẹ̀ pẹ̀lú ni New West African Kitchen, iṣẹ́ àkànṣe kan níbi tí Saro-Wiwa ti ṣe àtúnrò nípa onjewiwa Iwọ-oorun Afirika . Ayẹyẹ kọ̀ọ̀kan tún ṣe àfihàn àwọn iflarahàn àwòrán fídíò Áfíríkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ kékeré kan.

Ní ọjọ́ kejìlólógún Oṣù Kẹta Ọdún 2011, Saro-Wiwa gba àmì ìdánimọ̀ gẹgẹ bí ọ̀kan nínú àwọn adarí mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ó ga jùlọ ti Renaissance Afirika nínú ìwé ìròyìn Times .[citation needed]

Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀ àti ẹ̀kọ́

àtúnṣe

Zina Saro-Wiwa jẹ́ ọmọ Ken ati Maria Saro-Wiwa tí a bí ní Port Harcourt, orílẹ̀-èdè Nàíjírìa. Bàbá rẹ̀, òǹkọ̀wé àti akéwì Ken Saro-Wiwa tó ti di olóògbé, di olokiki ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọ-ènìyan ní orílẹ̀-èdè Naijiria. Odun 1995 ni ijọba ologun dájọ́ ikú fún bàbá rè nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndílógún. Ó dàgbà ní Surrey àti Sussex ní UK níbití Màríà, ìyàwó Saro-Wiwa àti àwọn ọmọ márùn-ún ń gbé. Ó lọ sí ilé-ìwé àwọn ọmọbìrin aládàáni, Roedean, ní Sussex, àti Yunifasiti ti Bristol níbi tí ó ti kawe ní ìmọ̀ lóri ọrọ aje ati ìtàn awujọ.

Arábìnrin ìbejì rẹ̀ jẹ́ oǹkọ̀wé arìrìn-àjò Noo Saro-Wiwa, oǹkọ̀wé ti Looking For Transwonderland (ti Granta ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀). Arákùnrin rẹ̀ àgbà Ken Wiwa, ni oǹkọ̀wé ìwé-ìrántí In The Shadow of a Saint (tí Random House/Vintage).

Iṣẹ́ rẹ̀ ní tẹlifíṣọ̀nù àti rédíò

àtúnṣe