‘ZOSSO’


‘Zosso’ jẹ Òrìṣà àdáyé bá, tó jẹ pé tí wọ́n bá tí bí ọmọ Àjara-Tọpá, ìyá ọmọ náà kò ní jẹ iyọ̀ títí oṣù afi yọ lókè. Tí oṣù yìí bá ti yọ, wọn á gbé ọmọ náa bọ́ sí ìta láti fi osù han ọmọ náà wí pé kí ọmọ náà wo oṣù tí ó wá sáyé. Ní ọjọ́ náà ìyá ọmọ náà yòó gbé ọmọ náà bó sí ìta láìwọ aṣo àti ọmọ náà pàápàá tí òun àti ọmọ rẹ̀ yóò sì jẹ iyọ̀ pèlú ẹja, wọn yóò sì tún fọ́ èkùrọ́ sórí ẹ̀wà láti fún ìyá ọmọ náà jẹ nígbà méje tó bájẹ́ obìnrin, ẹ̀mẹ́sàn-án to ba jẹ ọkùnrin. Léyìn tí wón bá ti se èyí tán, ìyá ọmọ yóò gbé ọmọ rẹ̀ lọ sí ìdí Òrìsà ‘Zosso’ láìwọ asọ ní ọjọ́ kejì, tí yóò sì ra otí dání láti sure fún ọmọ náà gẹ́gẹ́ bí àṣà. Wọn á sì padà sílé.

Nígbà tí ìyá ọmọ náà bá dé ilé yoò fá irun orí ọmọ rè, yóò sì lọ ra igbá àti ìkòkò tuntun. Igbá yìí ni yóò fi bo ìkòkò náà lọ sí odò ‘Zosso’. Omi odò yìí ni ìyá àti ọmọ yóò fi wẹ̀ títí omi yóò fi tàn. Òrìsà yìí máà n dáàbò bo àwọn ọmọde lọ́wọ́ aburú.