Zulu
Zulu Àwọn ènìyàn Zulu ni ẹ̀yà tó pọ̀jù ni orílè-èdè Gúúsù Áfríkà. A mọ̀ wọ́n mọ́ ìlẹ̀kẹ̀ alárànbàrà àti agbọ̀n pẹ̀lú àwọn ñǹkan gbígbẹ́. Wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn jẹ́ ìran tó sẹ̀ lára olóyè kan láti agbègbè Cóńgò, ni ñǹkan ẹgbẹ̀rún ọdùn mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn ni wọn tẹ̀síwájú sí Gúsú. Àwọn ènìyàn Zulu gbàgbọ́ nínú òrìṣà tó ń jẹ́ Nkulunkulu gẹ̀gẹ́ bí asẹ̀dá wọn òrishà yìí ko ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìfẹ́ sí ìgbé ayé kọ̀ọ̀kan. Awọn ènìyàn Zulu pin sí méjì! àwọn ìlàjì ni inú ìlù nígbà tí àwọn ìlàjì yókù sì wà ní ìgberíko tí wọ́n ń ṣisẹ́ àgbẹ̀. Mílíònù mẹ́sàn-án ènìyàn ló ń sọ èdè Zulu. Èdè yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè ìjọba mọ́kànlá ilẹ̀ South Africa. Àkọtọ Rómàniù ni wọ́n fi ń kọ èdè náà.
Àpapọ̀ iye oníbùgbé | ||||||||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|
10,659,309 (2001 census)[1] | ||||||||||||
Regions with significant populations | ||||||||||||
Gúúsù Áfríkà | ||||||||||||
| ||||||||||||
Èdè | ||||||||||||
Zulu | ||||||||||||
Ẹ̀sìn | ||||||||||||
Ẹ̀yà abínibí bíbátan | ||||||||||||
Bantu · Nguni · Basotho · Xhosa · Swazi · Matabele · Khoisan |
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 South Africa grows to 44.8 million, on the site southafrica.info published for the International Marketing Council of South Africa, dated 9 July 2003, retrieved 4 March 2005.