Zwai Bala

olórin ilẹ̀ South Africa

Zwai Bala (tí wọ́n bí ní ọjọ́ karùndínlógún oṣù kejì, ọdún 1975) jẹ́ olórín kwaito àti olórin ẹ̀mí ti orílè-èdè South Africa.

Zwai Bala
Orúkọ àbísọMzwandile Bala
Ọjọ́ìbí15 Oṣù Kejì 1975 (1975-02-15) (ọmọ ọdún 49)
Uitenhage, Eastern Cape, South Africa
Irú orinKwaito, Gospel
Occupation(s)Rapper, singer, actor
Years active1997–present

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Bala kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Drakensberg Boys' Choir School, nítòsí Winterton, KwaZulu-Natal, ó sì wọlé sí St Stithians College ní ọdún 1994. Ó tẹ̀síwájú láti gba òye ẹ̀kọ́ Master, fún ìwé-ẹ̀rí Orchestration for Film and Television ní Berklee College of Music ní ìlú Boston.[1] Ó bọ́ sí gbàgedè ní ọdún 1997, gẹ́gẹ́ bíi ọmọ-ẹgbẹ́ kwaito, ìyẹn TKZee.[2]

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ó kópa nínú ìdíje The Shell Road to Fame nígbà tí ó wà ní ọmọdún mọ́kànlá, níbi tí ó ti dé ipele aṣekágbá. Òun àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ bí i Kabelo Mabalane àti Tokollo Tshabalala ni wọ́n jìjọ ṣe ìdásílẹ̀ ẹgbé kwaito kan tí wọ́n pè ní TKZee. TKZee ṣàgbéjáde orin wọn tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Take It Eezy", holiday hit "Phalafala" àti orin wọn èyí tí ó tà jù lọ, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Shibobo",[3] níbi tí wọ́n ti ṣàfihàn agbábọ́ọ̀lù ti orílẹ̀-èdè South Africa, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Benni McCarthy. Lẹ́yìn náà, Bala bẹ̀rẹ̀ sí ni dá orin rẹ̀ kọ. Gẹ́gẹ́ bíi olùdarí àti aṣàgbéjáde orin, Bala ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ lórí orin bí i Ali Campbell ti UB40,[4] ó ṣàgbéjáde Grace láti ọwọ́ Soweto Gospel Choir tí wọ́n gba àmì-ẹ̀yẹ Grammy ní ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀,[5] tí ó sì tún farahàn nínú Classical FM–Lexus Soiree ní Sandton Intercontinental.

Ó jẹ́ olùdíje tó gbajúmọ̀ jù lọ nínú apá kìíní ti ìdíje SABC 2 tí wọ́n ń pè ní Strictly Come Dancing, ní ọdún 2006, níbi tí ó ti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú oníjó kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kego Motshabi. Wọ́n jìjọ gbé ipò kẹta.[6]

Àtòjọ àwọn orin rẹ̀

àtúnṣe

Lára àwọn orin Bala ni:

  • Ndize
  • Umlilo-Masibase
  • All I Do
  • Black 'N Proud
  • Ndiredi
  • Moody's Mood For Love
  • Nozamile
  • Vuk'uzenzele
  • Play That Music
  • Kuyasa
  • Ikhaya
  • Bash'abafana
  • Tino Tino
  • Folkfanse-My Heritage
  • Hand Prints
  • Circle of Life
  • Solo
  • Soccer
  • Gux Duo
  • Niceland-Guguletu
  • Everyone Can Drum
  • Noble Peace
  • Noyana

Orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán

àtúnṣe

Lára àwọn ìṣàfihàn rẹ̀ lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán ni:[7]

  • All You Need Is Love – Season 2 – Host
  • Clash of the Choirs South Africa – Season 1 – Choir Master
  • Clash of the Choirs South Africa – Season 3 – Guest Judge
  • Popstars – Season 2, 3 and 4 – Judge
  • Pump Up The Volume – Season 1 – Judge
  • Red Cake – Not the Cooking Show – Season 1 – Houseband leader

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

àtúnṣe

Ní ọdún 2002, ó gba South African Music Award (SAMA) fún orin àdákọ rẹ̀, ìyẹn "Lifted"[8] ní ọdún 2019 bákan náà, òun àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jì jọ wà nínú ẹgbẹ́ TKZee, ìyẹn Kabelo Mabalane àti Tokollo Tshabalala, gba àmì-ẹ̀yẹ SAMA.[9]

Àwọn ìtókasí

àtúnṣe
  1. James, Kamoche (10 April 2018). "Zwai Bala Biography". Archived from the original on 4 December 2021. Retrieved 22 October 2024. 
  2. "Zwai Bala | TVSA". www.tvsa.co.za. 
  3. "SAMusic". 
  4. "Ali Campbell – The Legendary Voice Of UB40 Reunited with Astro & Mickey release new album "Silhouette" ahead of Australian tour in December.". Cooking Vinyl. Archived from the original on 10 September 2016. Retrieved 25 September 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "Grace – The Soweto Gospel Choir | Songs, Reviews, Credits". AllMusic. 
  6. "Strictly Come Dancing South Africa – Episode 1". Timely Passion. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  7. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named auto2
  8. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named auto12
  9. "TKZee's journey to being awarded the Lifetime Achievement Award". KAYA FM. 4 June 2019.