Àlọ́ Ìjàpá àti Àlákàn

Apààlọ́ :Ààlọ́ o!

Ègbè Ààlọ́ :Ààlọ̀!

Apààlọ́: Ààlọ́ mí dá gbà-á, ó dá gbò-ó, ó dá fìrìgbagbóò, o dá lérí Ìjàpá àti Alákàn

Nígbà kan, Ìjàpá àti Àlákàn ń ṣe ọ̀rẹ́, Àlákàn ń gbé etí omi, ó ń ṣiṣẹ́ pẹjapẹja. Ìjàpá ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, ó ń gbé ibi tó jìnà s'omi. Èyi má ń jẹ́ kí Ìjàpá tọrọ omi lọ́wọ́ Àlákàn nígbà èérún tàbí tí òjò kò bá rọ̀[1].

Àlákàn bí ọmọ méje ṣùgbọ́n Ìjàpá ko bi ọmọ rárá. Ìjàpá a máa jowú Àlákàn, inú a máa bíi, o sì ń wọ́nà a ti pa Àlákàn l'ọ́mọ.

Nígbà kan, ìyàn mú ní ìlú Ìjàpá, kò sí òjò gbogbo odò kékèké ti gbe. Iṣu tí Ìjàpá gbìn kò ta. Ìjàpá lọ ba Àlákàn ṣe àdéhùn ko fún òun ni omi, òun yóò ma fún ni iṣu párọ̀. Àlákàn fún Ìjàpá l'ómi gẹ́gẹ́ bí àdéhùn wọn. Ìjàpá ni kí alákàn rán Ọmọ rẹ tẹ̀lé òun lọ gba isu, alákàn ran abigbeyin rẹ tẹle Ìjàpá, nigbati ọmọ alákàn tẹle Ìjàpá délé, ó bẹ̀rẹ̀ si níí kọrin bù bayii

ORIN ÀÀLỌ́

àtúnṣe

Bó délé ó kankan

Alugbinrin

Ó p'ó sapá kángun kangun

Alugbinrin

Ó p'ó ṣe ẹsẹ kángun kàngun

Alugbinrin

Ó pé ẹyín ẹyin lọ fi ń rìn ho

Alugbinrin

Ìjàpá pá ọmọ alákàn, ó sì ṣeé jẹ

Nígbà tí alákàn retí ọmọ rẹ̀ títí tí kò rí, ó tún rán Ẹ̀gbọ́n rẹ lọ, bí Ìjàpá tún ṣe rí eléyìí orin lọ mú sì ẹnu tó sì fọ ponpo mọ lórí, tó sì pá.

Alákàn ni àwọn ọmọ òun bàjé púpò, ó rán ìkẹta ikẹrin , ekàrún, ẹkẹfà àti èkeje, nigbati èkeje de bẹ ó dọbálẹ̀ fún Ìjàpá, ó béèrè àwọn àbúrò rẹ,Alabahun ni òun kò rí wọn ò ní bàbà òun ni kí òun gba isu wa, Ìjàpá bá tún mú orín èébú sì ẹnu, lo bá fọ igi mo lórí. Ní alákàn bá gbéra ó dílé Alabahun, ìgbà tó dé ibè, Ìjàpá ni ile ni ohun wá lataaro, òun kò rí ọmọ kankan, orí alákàn gbóná, ó fura pé Ìjàpá tí pá àwọn ọmọ òun, ó pá mọ́ra, ó fi ẹ̀jẹ̀ sínú tú ìtó funfun jáde, àwọn méjèèjì jọ nwa ọmọ kiri, ibè ni alákàn tí rí ìgba ẹyin àwọn ọmọ rẹ, o sọ fún Ìjàpá pé ilẹ̀ tí sú kí olúkúlùkù padà sílè, ó gba ìṣù lọ́wọ́ Ìjàpá kò má bàa fura pé òun ti mọ̀.

Ní ọjọ́ kejì Ìjàpá lọ sí ilé alákàn láti gba omi, alákàn gba garawa lọ́wọ́ Ìjàpá, ó wọ inú ihò rẹ lọ, ó ga ọwọ́ emuga rẹ silẹ, ó ní kí Ìjàpá na ọwọ kò fà garawa omi rẹ síta, Ìjàpá na ọwọ rẹ kò tó omi, alákàn ni kò nawọ dáadáa kò gbó rí wọlé, bí alákàn ṣe fi ẹmuga mú lọ́run mọ́lẹ̀ ni yìí tó sì pá Ìjàpá.

Ẹ̀kọ́ Ààlọ́

àtúnṣe

Ààlọ́ yìí kọ wá wípé owú jíjẹ kò dára, ìtẹ́lọ́rùn lọ dára, bí ènìyàn bá ń jowú ọ̀nà àti ba nkan jẹ́ ní yóò máa san.

ÀWỌN ÌTỌ́KASÍ

àtúnṣe
  1. https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales