Aarun ẹdọ A (tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ sí àkóràn ààrùn ẹ̀dọ̀) jẹ́ líle ààrùn àkóràn ti ẹ̀dọ̀ tí kòkòrò àkóràn ààrùn ẹ̀dọ̀ A fà (HAV).[1] Ọ̀pọ̀ iṣẹlẹ̀ ni kòní àwọn ààmì pàápàá ní ara ọmọdé.[2] Àkókò láàrín àkóràn àti àwọn ààmì, lára àwọn tí o ní, jẹ́ láàrín ọ̀sẹ̀ méjì sí mẹ́fà.[3] Bí àwọn ààmì báwà wọn maa ń wà fún ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ wọ́n sì lè pẹ̀lú: ìṣu, èébì, ṣíṣunú, ẹran ara pípọ́n, ibà, àti inú dídùn.[2] Láàrin 10-15% àwọn ènìyàn ní ìrirí wíwáyé àwọn ààmì lákókò oṣù mẹ́fà lẹ́hìn àkóràn àkọkọ́.[2] Ààrùn ẹ̀dọ̀ líle kò sábà ń wáyé ní èyí tí ó wọ́pọ̀ láàrín àwọn àgbàlagbà.[2]

Ààrùn ẹ̀dọ̀ A
Ààrùn ẹ̀dọ̀ AÌṣẹlẹ̀ ní èyí tí ààrùn ẹ̀dọ̀ A ńfa ìbà pọ́njú-pọ́njú
Ààrùn ẹ̀dọ̀ AÌṣẹlẹ̀ ní èyí tí ààrùn ẹ̀dọ̀ A ńfa ìbà pọ́njú-pọ́njú
Ìṣẹlẹ̀ ní èyí tí ààrùn ẹ̀dọ̀ A ńfa ìbà pọ́njú-pọ́njú
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B15. B15.
ICD/CIM-9070.0, 070.1 070.0, 070.1
DiseasesDB5757
MedlinePlus000278

Ó sábà maa ń ràn nípa jíjẹ tàbí mímu oúnjẹ tàbí omi ẹlẹ́gbin tí ó ní ìgbẹ́ àkóràn.[2] Ẹja eléèpo tí a kò sè dáadaa jẹ́ orísun tí ó wọ́pọ̀.[4] Ó tún lè ràn nípa ìfarakàn ẹni tí ó ní àkóràn.[2] Bí àwọn ọmọdé ò ti ní àwọn ààmì àkóràn bẹ́ẹ̀ wọ́n ṣì le Koran ẹlòmíràn.[2] Lẹ́hìn àkóràn àkọkọ́ ènìyàn kòle ní àkóràn mọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.[5] Ìmọ̀ àisàn nílò àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ bíi àwọn ààmì rẹ̀ ṣe farajọ àwọn ti ààrùn míìrán.[2] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn máàrún tí a mọ̀ ààrùn ẹ̀dọ̀ àwọn àkóràn: A, B, C, D, àti E.

òògùn ààrùn ẹ̀dọ̀ A dára fún ìdẹ́kun.[2][6] Àwọn orílẹ̀ èdè kan fọwọ́si níwọ̀nba fún àwọn ọmọdé àti fún àwọn tí ó wà léwu gidi tí akòití fún ní oogùn rẹ.[2][7] Ó hàn pé ó dára fún ẹ̀mí.[2] Àwọn ìwọ̀n ìdẹ́kun míìrán ni ọwọ́ fífọ̀ àti síse oúnjẹ dáradára.[2] Kòsí ìtọjú kan pàtó, pẹ̀lú ìsinmi àti àwọn oogùn fún ìṣu tàbí ṣíṣunú ni a fọwọsí bí o ti yẹ lóòrekoorè.[2] Àwọn àkóràn sábà maa ńlọ pátápátá láìsi àrùn ẹ̀dọ̀ rárá.[2] Ìtọjú fún àrùn ẹ̀dọ̀ líle, bí ó bá wáyé, ni pẹ̀lú Ìrọ́pò ẹ̀dọ̀.[2]

Lágbayé láàrín 1.5 mílíónù àwọn ìṣẹlẹ̀ ààmì maa ń wáyé lọdọọdún[2] èyí tí o ṣèéṣe àwọn àkóràn mílíónù ọ̀nà mẹ́wà ní gbogbo.[8] Ó wọ́pọ̀ l’áwọn apa ẹkùn kan lágbayé tí wọn kìí tíṣe ìmọtótó dáradára àti tí kòsí omi tó.[7] Ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ṣẹ̀ẹ̀ṣẹ̀ ń gbèrú ìdá 90% àwọn ọmọdé ni o tiní àkóràn ní ọmọ ọdún 10 wọn kòsì le ni mọ́ ní àgbà.[7] O máa ń ṣẹlẹ̀ níwọ̀nba ní àwọn orílẹ̀ èdè tí o ti gbèrú níbi tí àwọn ọmọdé kòní àkóràn ní kékeré tí kòsí sí ìwọ́pọ̀ ìfún lóògùn.[7] Ní 2010, àrùn ẹ̀dọ̀ líle A fa ikú 102,000.[9] Àyajọ́ ọdún ààrùn ẹ̀dọ̀ àgbayé ó maa ń wáyé lọ́dọọdún ní July 28 láti mú kí àwọn ènìyàn mọ́ọ̀ ààrùn ẹ̀dọ̀ líle.[7]

Àwọn ìtọ́kasi

àtúnṣe
  1. Ryan KJ, Ray CG (editors) (2004). Sherris Medical Microbiology (4th ed.). McGraw Hill. pp. 541–4. ISBN 0-8385-8529-9. 
  2. 2.00 2.01 2.02 2.03 2.04 2.05 2.06 2.07 2.08 2.09 2.10 2.11 2.12 2.13 2.14 2.15 Matheny, SC; Kingery, JE (1 December 2012). "Hepatitis A.". Am Fam Physician 86 (11): 1027–34; quiz 1010–2. PMID 23198670. http://www.aafp.org/afp/2012/1201/p1027.html. 
  3. Connor BA (2005). "Hepatitis A vaccine in the last-minute traveler". Am. J. Med. 118 (Suppl 10A): 58S–62S. doi:10.1016/j.amjmed.2005.07.018. PMID 16271543. 
  4. Bellou, M.; Kokkinos, P.; Vantarakis, A. (March 2013). "Shellfish-borne viral outbreaks: a systematic review.". Food Environ Virol 5 (1): 13–23. doi:10.1007/s12560-012-9097-6. PMID 23412719. 
  5. The Encyclopedia of Hepatitis and Other Liver Diseases. Infobase. 2006. p. 105. ISBN 9780816069903. http://books.google.ca/books?id=HfPU99jIfboC&pg=PA105. 
  6. Irving, GJ.; Holden, J.; Yang, R.; Pope, D. (2012). "Hepatitis A immunisation in persons not previously exposed to hepatitis A.". Cochrane Database Syst Rev 7: CD009051. doi:10.1002/14651858.CD009051.pub2. PMID 22786522. 
  7. 7.0 7.1 7.2 7.3 7.4 "Hepatitis A Fact sheet N°328". World Health Organization. July 2013. Retrieved 20 February 2014. 
  8. Wasley, A; Fiore, A; Bell, BP (2006). "Hepatitis A in the era of vaccination.". Epidemiol Rev 28: 101–11. doi:10.1093/epirev/mxj012. PMID 16775039. http://epirev.oxfordjournals.org/content/28/1/101.long. 
  9. Lozano, R (Dec 15, 2012). "Global and regional mortality from 235 causes of death for 20 age groups in 1990 and 2010: a systematic analysis for the Global Burden of Disease Study 2010". Lancet 380 (9859): 2095–128. doi:10.1016/S0140-6736(12)61728-0. PMID 23245604.